Psalms 15 (BOYCB)
undefined Saamu ti Dafidi. 1 OLÚWA, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ? 2 Ẹni tí ń rìn déédétí ó sì ń sọ òtítọ́,láti inú ọkàn rẹ̀; 3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀, 4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígànṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLÚWA,ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀àní tí kò sì yípadà, 5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlétí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyíni a kì yóò mì láéláé.