Psalms 54 (BOYCB)
undefined Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí àwọn ará Sifi lọ sọ fún Saulu pé, “Dafidi sá pamọ́ sọ́dọ̀ wa?” 1 Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ:dá mi láre nípa agbára rẹ. 2 Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. 3 Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí.Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa,àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn. 4 Kíyèsi i Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi;Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ. 5 Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ. 6 Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ,èmi yóò yin orúkọ rẹ, OLÚWA,nítorí tí ó dára. 7 Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogboojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.