Zechariah 1 (BOYCB)

1 Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé: 2 “OLÚWA ti bínú sí àwọn baba ńlá yín. 3 Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn. Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ mi,’ báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 4 Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé, báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni OLÚWA wí. 5 Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọ́n ha wà títí ayé? 6 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín?“Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ” 7 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo wá, pé. 8 Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà. 9 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?”Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.” 10 Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí OLÚWA ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.” 11 Wọ́n si dá angẹli OLÚWA tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.” 12 Nígbà náà ni angẹli OLÚWA náà dáhùn ó sì wí pé, “OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?” 13 OLÚWA sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn. 14 Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. 15 Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’ 16 “Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’ 17 “Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; OLÚWA yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ” 18 Mo si gbé ojú sókè, mo sì rí, sì kíyèsi i, ìwo mẹ́rin. 19 Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?”Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Juda, Israẹli, àti Jerusalẹmu ká.” 20 OLÚWA sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí. 21 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?”O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Juda ká, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sókè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orílẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sórí ilẹ̀ Juda láti tú ènìyàn rẹ̀ ká.”

In Other Versions

Zechariah 1 in the ANGEFD

Zechariah 1 in the ANTPNG2D

Zechariah 1 in the AS21

Zechariah 1 in the BAGH

Zechariah 1 in the BBPNG

Zechariah 1 in the BBT1E

Zechariah 1 in the BDS

Zechariah 1 in the BEV

Zechariah 1 in the BHAD

Zechariah 1 in the BIB

Zechariah 1 in the BLPT

Zechariah 1 in the BNT

Zechariah 1 in the BNTABOOT

Zechariah 1 in the BNTLV

Zechariah 1 in the BOATCB

Zechariah 1 in the BOATCB2

Zechariah 1 in the BOBCV

Zechariah 1 in the BOCNT

Zechariah 1 in the BOECS

Zechariah 1 in the BOGWICC

Zechariah 1 in the BOHCB

Zechariah 1 in the BOHCV

Zechariah 1 in the BOHLNT

Zechariah 1 in the BOHNTLTAL

Zechariah 1 in the BOICB

Zechariah 1 in the BOILNTAP

Zechariah 1 in the BOITCV

Zechariah 1 in the BOKCV

Zechariah 1 in the BOKCV2

Zechariah 1 in the BOKHWOG

Zechariah 1 in the BOKSSV

Zechariah 1 in the BOLCB

Zechariah 1 in the BOLCB2

Zechariah 1 in the BOMCV

Zechariah 1 in the BONAV

Zechariah 1 in the BONCB

Zechariah 1 in the BONLT

Zechariah 1 in the BONUT2

Zechariah 1 in the BOPLNT

Zechariah 1 in the BOSCB

Zechariah 1 in the BOSNC

Zechariah 1 in the BOTLNT

Zechariah 1 in the BOVCB

Zechariah 1 in the BPBB

Zechariah 1 in the BPH

Zechariah 1 in the BSB

Zechariah 1 in the CCB

Zechariah 1 in the CUV

Zechariah 1 in the CUVS

Zechariah 1 in the DBT

Zechariah 1 in the DGDNT

Zechariah 1 in the DHNT

Zechariah 1 in the DNT

Zechariah 1 in the ELBE

Zechariah 1 in the EMTV

Zechariah 1 in the ESV

Zechariah 1 in the FBV

Zechariah 1 in the FEB

Zechariah 1 in the GGMNT

Zechariah 1 in the GNT

Zechariah 1 in the HARY

Zechariah 1 in the HNT

Zechariah 1 in the IRVA

Zechariah 1 in the IRVB

Zechariah 1 in the IRVG

Zechariah 1 in the IRVH

Zechariah 1 in the IRVK

Zechariah 1 in the IRVM

Zechariah 1 in the IRVM2

Zechariah 1 in the IRVO

Zechariah 1 in the IRVP

Zechariah 1 in the IRVT

Zechariah 1 in the IRVT2

Zechariah 1 in the IRVU

Zechariah 1 in the ISVN

Zechariah 1 in the JSNT

Zechariah 1 in the KAPI

Zechariah 1 in the KBT1ETNIK

Zechariah 1 in the KBV

Zechariah 1 in the KJV

Zechariah 1 in the KNFD

Zechariah 1 in the LBA

Zechariah 1 in the LBLA

Zechariah 1 in the LNT

Zechariah 1 in the LSV

Zechariah 1 in the MAAL

Zechariah 1 in the MBV

Zechariah 1 in the MBV2

Zechariah 1 in the MHNT

Zechariah 1 in the MKNFD

Zechariah 1 in the MNG

Zechariah 1 in the MNT

Zechariah 1 in the MNT2

Zechariah 1 in the MRS1T

Zechariah 1 in the NAA

Zechariah 1 in the NASB

Zechariah 1 in the NBLA

Zechariah 1 in the NBS

Zechariah 1 in the NBVTP

Zechariah 1 in the NET2

Zechariah 1 in the NIV11

Zechariah 1 in the NNT

Zechariah 1 in the NNT2

Zechariah 1 in the NNT3

Zechariah 1 in the PDDPT

Zechariah 1 in the PFNT

Zechariah 1 in the RMNT

Zechariah 1 in the SBIAS

Zechariah 1 in the SBIBS

Zechariah 1 in the SBIBS2

Zechariah 1 in the SBICS

Zechariah 1 in the SBIDS

Zechariah 1 in the SBIGS

Zechariah 1 in the SBIHS

Zechariah 1 in the SBIIS

Zechariah 1 in the SBIIS2

Zechariah 1 in the SBIIS3

Zechariah 1 in the SBIKS

Zechariah 1 in the SBIKS2

Zechariah 1 in the SBIMS

Zechariah 1 in the SBIOS

Zechariah 1 in the SBIPS

Zechariah 1 in the SBISS

Zechariah 1 in the SBITS

Zechariah 1 in the SBITS2

Zechariah 1 in the SBITS3

Zechariah 1 in the SBITS4

Zechariah 1 in the SBIUS

Zechariah 1 in the SBIVS

Zechariah 1 in the SBT

Zechariah 1 in the SBT1E

Zechariah 1 in the SCHL

Zechariah 1 in the SNT

Zechariah 1 in the SUSU

Zechariah 1 in the SUSU2

Zechariah 1 in the SYNO

Zechariah 1 in the TBIAOTANT

Zechariah 1 in the TBT1E

Zechariah 1 in the TBT1E2

Zechariah 1 in the TFTIP

Zechariah 1 in the TFTU

Zechariah 1 in the TGNTATF3T

Zechariah 1 in the THAI

Zechariah 1 in the TNFD

Zechariah 1 in the TNT

Zechariah 1 in the TNTIK

Zechariah 1 in the TNTIL

Zechariah 1 in the TNTIN

Zechariah 1 in the TNTIP

Zechariah 1 in the TNTIZ

Zechariah 1 in the TOMA

Zechariah 1 in the TTENT

Zechariah 1 in the UBG

Zechariah 1 in the UGV

Zechariah 1 in the UGV2

Zechariah 1 in the UGV3

Zechariah 1 in the VBL

Zechariah 1 in the VDCC

Zechariah 1 in the YALU

Zechariah 1 in the YAPE

Zechariah 1 in the YBVTP

Zechariah 1 in the ZBP