1 Chronicles 22 (BOYCB)
1 Nígbà náà Dafidi wí pé, “Ilé OLÚWA Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ẹbọ sísun fún Israẹli.” 2 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi pàṣẹ láti kó àwọn àjèjì tí ń gbé ní Israẹli jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbẹ́-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run. 3 Dafidi sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣó fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n. 4 Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kedari tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Sidoni àti àwọn ará Tire mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari wá fún Dafidi. 5 Dafidi wí pé, “Ọmọ mi Solomoni ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìrírí, ilé tí a ó kọ́ fún OLÚWA gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un”. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú. 6 Nígbà náà ó pe Solomoni ọmọ rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún un OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli. 7 Dafidi sì wí fún Solomoni pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ OLÚWA Ọlọ́run mi. 8 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé, ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi. 9 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Solomoni, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún Israẹli lásìkò ìjọba rẹ̀. 10 Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Israẹli láéláé.’ 11 “Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí OLÚWA wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé OLÚWA Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. 12 Kí OLÚWA kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin OLÚWA Ọlọ́run mọ́. 13 Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti OLÚWA ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́. 14 “Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé OLÚWA ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn. 15 Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́. 16 Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin oníṣọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí OLÚWA wà pẹ̀lú rẹ.” 17 Nígbà náà Dafidi pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli láti ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. 18 Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìṣẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú OLÚWA àti níwájú àwọn ènìyàn. 19 Nísinsin yìí, ẹ ṣí ọkàn yin páyà àti àyà yín sí àti wá OLÚWA Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún OLÚWA Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú OLÚWA àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé OLÚWA tí a o kọ́ fún orúkọ OLÚWA.”
In Other Versions
1 Chronicles 22 in the ANGEFD
1 Chronicles 22 in the ANTPNG2D
1 Chronicles 22 in the AS21
1 Chronicles 22 in the BAGH
1 Chronicles 22 in the BBPNG
1 Chronicles 22 in the BBT1E
1 Chronicles 22 in the BDS
1 Chronicles 22 in the BEV
1 Chronicles 22 in the BHAD
1 Chronicles 22 in the BIB
1 Chronicles 22 in the BLPT
1 Chronicles 22 in the BNT
1 Chronicles 22 in the BNTABOOT
1 Chronicles 22 in the BNTLV
1 Chronicles 22 in the BOATCB
1 Chronicles 22 in the BOATCB2
1 Chronicles 22 in the BOBCV
1 Chronicles 22 in the BOCNT
1 Chronicles 22 in the BOECS
1 Chronicles 22 in the BOGWICC
1 Chronicles 22 in the BOHCB
1 Chronicles 22 in the BOHCV
1 Chronicles 22 in the BOHLNT
1 Chronicles 22 in the BOHNTLTAL
1 Chronicles 22 in the BOICB
1 Chronicles 22 in the BOILNTAP
1 Chronicles 22 in the BOITCV
1 Chronicles 22 in the BOKCV
1 Chronicles 22 in the BOKCV2
1 Chronicles 22 in the BOKHWOG
1 Chronicles 22 in the BOKSSV
1 Chronicles 22 in the BOLCB
1 Chronicles 22 in the BOLCB2
1 Chronicles 22 in the BOMCV
1 Chronicles 22 in the BONAV
1 Chronicles 22 in the BONCB
1 Chronicles 22 in the BONLT
1 Chronicles 22 in the BONUT2
1 Chronicles 22 in the BOPLNT
1 Chronicles 22 in the BOSCB
1 Chronicles 22 in the BOSNC
1 Chronicles 22 in the BOTLNT
1 Chronicles 22 in the BOVCB
1 Chronicles 22 in the BPBB
1 Chronicles 22 in the BPH
1 Chronicles 22 in the BSB
1 Chronicles 22 in the CCB
1 Chronicles 22 in the CUV
1 Chronicles 22 in the CUVS
1 Chronicles 22 in the DBT
1 Chronicles 22 in the DGDNT
1 Chronicles 22 in the DHNT
1 Chronicles 22 in the DNT
1 Chronicles 22 in the ELBE
1 Chronicles 22 in the EMTV
1 Chronicles 22 in the ESV
1 Chronicles 22 in the FBV
1 Chronicles 22 in the FEB
1 Chronicles 22 in the GGMNT
1 Chronicles 22 in the GNT
1 Chronicles 22 in the HARY
1 Chronicles 22 in the HNT
1 Chronicles 22 in the IRVA
1 Chronicles 22 in the IRVB
1 Chronicles 22 in the IRVG
1 Chronicles 22 in the IRVH
1 Chronicles 22 in the IRVK
1 Chronicles 22 in the IRVM
1 Chronicles 22 in the IRVM2
1 Chronicles 22 in the IRVO
1 Chronicles 22 in the IRVP
1 Chronicles 22 in the IRVT
1 Chronicles 22 in the IRVT2
1 Chronicles 22 in the IRVU
1 Chronicles 22 in the ISVN
1 Chronicles 22 in the JSNT
1 Chronicles 22 in the KAPI
1 Chronicles 22 in the KBT1ETNIK
1 Chronicles 22 in the KBV
1 Chronicles 22 in the KJV
1 Chronicles 22 in the KNFD
1 Chronicles 22 in the LBA
1 Chronicles 22 in the LBLA
1 Chronicles 22 in the LNT
1 Chronicles 22 in the LSV
1 Chronicles 22 in the MAAL
1 Chronicles 22 in the MBV
1 Chronicles 22 in the MBV2
1 Chronicles 22 in the MHNT
1 Chronicles 22 in the MKNFD
1 Chronicles 22 in the MNG
1 Chronicles 22 in the MNT
1 Chronicles 22 in the MNT2
1 Chronicles 22 in the MRS1T
1 Chronicles 22 in the NAA
1 Chronicles 22 in the NASB
1 Chronicles 22 in the NBLA
1 Chronicles 22 in the NBS
1 Chronicles 22 in the NBVTP
1 Chronicles 22 in the NET2
1 Chronicles 22 in the NIV11
1 Chronicles 22 in the NNT
1 Chronicles 22 in the NNT2
1 Chronicles 22 in the NNT3
1 Chronicles 22 in the PDDPT
1 Chronicles 22 in the PFNT
1 Chronicles 22 in the RMNT
1 Chronicles 22 in the SBIAS
1 Chronicles 22 in the SBIBS
1 Chronicles 22 in the SBIBS2
1 Chronicles 22 in the SBICS
1 Chronicles 22 in the SBIDS
1 Chronicles 22 in the SBIGS
1 Chronicles 22 in the SBIHS
1 Chronicles 22 in the SBIIS
1 Chronicles 22 in the SBIIS2
1 Chronicles 22 in the SBIIS3
1 Chronicles 22 in the SBIKS
1 Chronicles 22 in the SBIKS2
1 Chronicles 22 in the SBIMS
1 Chronicles 22 in the SBIOS
1 Chronicles 22 in the SBIPS
1 Chronicles 22 in the SBISS
1 Chronicles 22 in the SBITS
1 Chronicles 22 in the SBITS2
1 Chronicles 22 in the SBITS3
1 Chronicles 22 in the SBITS4
1 Chronicles 22 in the SBIUS
1 Chronicles 22 in the SBIVS
1 Chronicles 22 in the SBT
1 Chronicles 22 in the SBT1E
1 Chronicles 22 in the SCHL
1 Chronicles 22 in the SNT
1 Chronicles 22 in the SUSU
1 Chronicles 22 in the SUSU2
1 Chronicles 22 in the SYNO
1 Chronicles 22 in the TBIAOTANT
1 Chronicles 22 in the TBT1E
1 Chronicles 22 in the TBT1E2
1 Chronicles 22 in the TFTIP
1 Chronicles 22 in the TFTU
1 Chronicles 22 in the TGNTATF3T
1 Chronicles 22 in the THAI
1 Chronicles 22 in the TNFD
1 Chronicles 22 in the TNT
1 Chronicles 22 in the TNTIK
1 Chronicles 22 in the TNTIL
1 Chronicles 22 in the TNTIN
1 Chronicles 22 in the TNTIP
1 Chronicles 22 in the TNTIZ
1 Chronicles 22 in the TOMA
1 Chronicles 22 in the TTENT
1 Chronicles 22 in the UBG
1 Chronicles 22 in the UGV
1 Chronicles 22 in the UGV2
1 Chronicles 22 in the UGV3
1 Chronicles 22 in the VBL
1 Chronicles 22 in the VDCC
1 Chronicles 22 in the YALU
1 Chronicles 22 in the YAPE
1 Chronicles 22 in the YBVTP
1 Chronicles 22 in the ZBP