1 Chronicles 5 (BOYCB)

1 Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí Israẹli. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ibùsùn baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí. 2 Nítorí Juda borí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni aláṣẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Josẹfu), 3 àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni: Hanoku àti Pallu, Hesroni àti Karmi. 4 Àwọn ọmọ Joẹli:Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀,Ṣimei ọmọ rẹ̀. 5 Mika ọmọ rẹ̀,Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀. 6 Beera ọmọ rẹ̀, tí Tiglat-Pileseri ọba Asiria kó ní ìgbèkùn lọ. Ìjòyè àwọn ọmọ Reubeni ni Beera jẹ́. 7 Àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:Jeieli àti Sekariah ni olórí, 8 àti Bela ọmọ Asasi ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli. Wọ́n tí ń gbé Aroeri àní títí dé Nebo àti Baali-Meoni. 9 Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi. 10 Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi. 11 Àti àwọn ọmọ Gadi ń gbé lékè wọn, ní ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka: 12 Joẹli jẹ́ olórí, Ṣafamu ìran ọmọ Janai, àti Ṣafati ni Baṣani. 13 Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní:Mikaeli, Meṣullamu Ṣeba, Jorai, Jaka, Sia àti Eberi méje. 14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jeroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi. 15 Ahi, ọmọ Adbeeli, ọmọ Guni, olórí ilé àwọn baba wọn. 16 Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn. 17 Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn ìdílé, ní ọjọ́ Jotamu ọba Juda, àti ní ọjọ́ Jeroboamu ọba Israẹli. 18 Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì (47,760) ènìyàn, tí ó jáde lọ sí ogún náà. 19 Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hagari jagun, pẹ̀lú Jeturi, àti Nafiṣi àti Nadabu. 20 Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 21 Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000) àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún (250,000), àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì (2,000), àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000). 22 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn. 23 Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Baṣani títí dé Baali-Hermoni, àti Seniri àti títí dé òkè Hermoni. 24 Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Eferi, Iṣi, Elieli, Asrieli, Jeremiah, Hodafiah àti Jahdieli àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn. 25 Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì ṣe àgbèrè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn. 26 Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (èyí ni Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.

In Other Versions

1 Chronicles 5 in the ANGEFD

1 Chronicles 5 in the ANTPNG2D

1 Chronicles 5 in the AS21

1 Chronicles 5 in the BAGH

1 Chronicles 5 in the BBPNG

1 Chronicles 5 in the BBT1E

1 Chronicles 5 in the BDS

1 Chronicles 5 in the BEV

1 Chronicles 5 in the BHAD

1 Chronicles 5 in the BIB

1 Chronicles 5 in the BLPT

1 Chronicles 5 in the BNT

1 Chronicles 5 in the BNTABOOT

1 Chronicles 5 in the BNTLV

1 Chronicles 5 in the BOATCB

1 Chronicles 5 in the BOATCB2

1 Chronicles 5 in the BOBCV

1 Chronicles 5 in the BOCNT

1 Chronicles 5 in the BOECS

1 Chronicles 5 in the BOGWICC

1 Chronicles 5 in the BOHCB

1 Chronicles 5 in the BOHCV

1 Chronicles 5 in the BOHLNT

1 Chronicles 5 in the BOHNTLTAL

1 Chronicles 5 in the BOICB

1 Chronicles 5 in the BOILNTAP

1 Chronicles 5 in the BOITCV

1 Chronicles 5 in the BOKCV

1 Chronicles 5 in the BOKCV2

1 Chronicles 5 in the BOKHWOG

1 Chronicles 5 in the BOKSSV

1 Chronicles 5 in the BOLCB

1 Chronicles 5 in the BOLCB2

1 Chronicles 5 in the BOMCV

1 Chronicles 5 in the BONAV

1 Chronicles 5 in the BONCB

1 Chronicles 5 in the BONLT

1 Chronicles 5 in the BONUT2

1 Chronicles 5 in the BOPLNT

1 Chronicles 5 in the BOSCB

1 Chronicles 5 in the BOSNC

1 Chronicles 5 in the BOTLNT

1 Chronicles 5 in the BOVCB

1 Chronicles 5 in the BPBB

1 Chronicles 5 in the BPH

1 Chronicles 5 in the BSB

1 Chronicles 5 in the CCB

1 Chronicles 5 in the CUV

1 Chronicles 5 in the CUVS

1 Chronicles 5 in the DBT

1 Chronicles 5 in the DGDNT

1 Chronicles 5 in the DHNT

1 Chronicles 5 in the DNT

1 Chronicles 5 in the ELBE

1 Chronicles 5 in the EMTV

1 Chronicles 5 in the ESV

1 Chronicles 5 in the FBV

1 Chronicles 5 in the FEB

1 Chronicles 5 in the GGMNT

1 Chronicles 5 in the GNT

1 Chronicles 5 in the HARY

1 Chronicles 5 in the HNT

1 Chronicles 5 in the IRVA

1 Chronicles 5 in the IRVB

1 Chronicles 5 in the IRVG

1 Chronicles 5 in the IRVH

1 Chronicles 5 in the IRVK

1 Chronicles 5 in the IRVM

1 Chronicles 5 in the IRVM2

1 Chronicles 5 in the IRVO

1 Chronicles 5 in the IRVP

1 Chronicles 5 in the IRVT

1 Chronicles 5 in the IRVT2

1 Chronicles 5 in the IRVU

1 Chronicles 5 in the ISVN

1 Chronicles 5 in the JSNT

1 Chronicles 5 in the KAPI

1 Chronicles 5 in the KBT1ETNIK

1 Chronicles 5 in the KBV

1 Chronicles 5 in the KJV

1 Chronicles 5 in the KNFD

1 Chronicles 5 in the LBA

1 Chronicles 5 in the LBLA

1 Chronicles 5 in the LNT

1 Chronicles 5 in the LSV

1 Chronicles 5 in the MAAL

1 Chronicles 5 in the MBV

1 Chronicles 5 in the MBV2

1 Chronicles 5 in the MHNT

1 Chronicles 5 in the MKNFD

1 Chronicles 5 in the MNG

1 Chronicles 5 in the MNT

1 Chronicles 5 in the MNT2

1 Chronicles 5 in the MRS1T

1 Chronicles 5 in the NAA

1 Chronicles 5 in the NASB

1 Chronicles 5 in the NBLA

1 Chronicles 5 in the NBS

1 Chronicles 5 in the NBVTP

1 Chronicles 5 in the NET2

1 Chronicles 5 in the NIV11

1 Chronicles 5 in the NNT

1 Chronicles 5 in the NNT2

1 Chronicles 5 in the NNT3

1 Chronicles 5 in the PDDPT

1 Chronicles 5 in the PFNT

1 Chronicles 5 in the RMNT

1 Chronicles 5 in the SBIAS

1 Chronicles 5 in the SBIBS

1 Chronicles 5 in the SBIBS2

1 Chronicles 5 in the SBICS

1 Chronicles 5 in the SBIDS

1 Chronicles 5 in the SBIGS

1 Chronicles 5 in the SBIHS

1 Chronicles 5 in the SBIIS

1 Chronicles 5 in the SBIIS2

1 Chronicles 5 in the SBIIS3

1 Chronicles 5 in the SBIKS

1 Chronicles 5 in the SBIKS2

1 Chronicles 5 in the SBIMS

1 Chronicles 5 in the SBIOS

1 Chronicles 5 in the SBIPS

1 Chronicles 5 in the SBISS

1 Chronicles 5 in the SBITS

1 Chronicles 5 in the SBITS2

1 Chronicles 5 in the SBITS3

1 Chronicles 5 in the SBITS4

1 Chronicles 5 in the SBIUS

1 Chronicles 5 in the SBIVS

1 Chronicles 5 in the SBT

1 Chronicles 5 in the SBT1E

1 Chronicles 5 in the SCHL

1 Chronicles 5 in the SNT

1 Chronicles 5 in the SUSU

1 Chronicles 5 in the SUSU2

1 Chronicles 5 in the SYNO

1 Chronicles 5 in the TBIAOTANT

1 Chronicles 5 in the TBT1E

1 Chronicles 5 in the TBT1E2

1 Chronicles 5 in the TFTIP

1 Chronicles 5 in the TFTU

1 Chronicles 5 in the TGNTATF3T

1 Chronicles 5 in the THAI

1 Chronicles 5 in the TNFD

1 Chronicles 5 in the TNT

1 Chronicles 5 in the TNTIK

1 Chronicles 5 in the TNTIL

1 Chronicles 5 in the TNTIN

1 Chronicles 5 in the TNTIP

1 Chronicles 5 in the TNTIZ

1 Chronicles 5 in the TOMA

1 Chronicles 5 in the TTENT

1 Chronicles 5 in the UBG

1 Chronicles 5 in the UGV

1 Chronicles 5 in the UGV2

1 Chronicles 5 in the UGV3

1 Chronicles 5 in the VBL

1 Chronicles 5 in the VDCC

1 Chronicles 5 in the YALU

1 Chronicles 5 in the YAPE

1 Chronicles 5 in the YBVTP

1 Chronicles 5 in the ZBP