1 Kings 5 (BOYCB)
1 Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo. 2 Solomoni sì ránṣẹ́ yìí padà sí Hiramu pé, 3 “Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí OLÚWA fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. 4 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí OLÚWA Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe. 5 Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ OLÚWA Ọlọ́run mi, bí OLÚWA ti sọ fún Dafidi baba mi, nígbà tí ó wí pé, ‘Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’ 6 “Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi kedari Lebanoni fún mi wá. Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ. Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Sidoni.” 7 Nígbà tí Hiramu sì gbọ́ iṣẹ́ Solomoni, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún OLÚWA lónìí, nítorí tí ó ti fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ láti ṣàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.” 8 Hiramu sì ránṣẹ́ sí Solomoni pé,“Èmi ti gbọ́ iṣẹ́ tí ìwọ rán sí mi, èmi yóò sì ṣe gbogbo èyí tí o fẹ́ ní pípèsè igi kedari àti ní ti igi firi. 9 Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lebanoni wá sí Òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi Òkun Ńlá títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.” 10 Báyìí ni Hiramu sì pèsè igi kedari àti igi firi tí Solomoni ń fẹ́ fún un, 11 Solomoni sì fún Hiramu ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) òsùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún òsùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún. 12 OLÚWA sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn. 13 Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ènìyàn. 14 Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà. 15 Solomoni sì ní ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè, 16 àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Solomoni jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà. 17 Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀. 18 Àwọn oníṣọ̀nà Solomoni àti Hiramu àti àwọn òṣìṣẹ́ láti Gebali sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.
In Other Versions
1 Kings 5 in the ANGEFD
1 Kings 5 in the ANTPNG2D
1 Kings 5 in the AS21
1 Kings 5 in the BAGH
1 Kings 5 in the BBPNG
1 Kings 5 in the BBT1E
1 Kings 5 in the BDS
1 Kings 5 in the BEV
1 Kings 5 in the BHAD
1 Kings 5 in the BIB
1 Kings 5 in the BLPT
1 Kings 5 in the BNT
1 Kings 5 in the BNTABOOT
1 Kings 5 in the BNTLV
1 Kings 5 in the BOATCB
1 Kings 5 in the BOATCB2
1 Kings 5 in the BOBCV
1 Kings 5 in the BOCNT
1 Kings 5 in the BOECS
1 Kings 5 in the BOGWICC
1 Kings 5 in the BOHCB
1 Kings 5 in the BOHCV
1 Kings 5 in the BOHLNT
1 Kings 5 in the BOHNTLTAL
1 Kings 5 in the BOICB
1 Kings 5 in the BOILNTAP
1 Kings 5 in the BOITCV
1 Kings 5 in the BOKCV
1 Kings 5 in the BOKCV2
1 Kings 5 in the BOKHWOG
1 Kings 5 in the BOKSSV
1 Kings 5 in the BOLCB
1 Kings 5 in the BOLCB2
1 Kings 5 in the BOMCV
1 Kings 5 in the BONAV
1 Kings 5 in the BONCB
1 Kings 5 in the BONLT
1 Kings 5 in the BONUT2
1 Kings 5 in the BOPLNT
1 Kings 5 in the BOSCB
1 Kings 5 in the BOSNC
1 Kings 5 in the BOTLNT
1 Kings 5 in the BOVCB
1 Kings 5 in the BPBB
1 Kings 5 in the BPH
1 Kings 5 in the BSB
1 Kings 5 in the CCB
1 Kings 5 in the CUV
1 Kings 5 in the CUVS
1 Kings 5 in the DBT
1 Kings 5 in the DGDNT
1 Kings 5 in the DHNT
1 Kings 5 in the DNT
1 Kings 5 in the ELBE
1 Kings 5 in the EMTV
1 Kings 5 in the ESV
1 Kings 5 in the FBV
1 Kings 5 in the FEB
1 Kings 5 in the GGMNT
1 Kings 5 in the GNT
1 Kings 5 in the HARY
1 Kings 5 in the HNT
1 Kings 5 in the IRVA
1 Kings 5 in the IRVB
1 Kings 5 in the IRVG
1 Kings 5 in the IRVH
1 Kings 5 in the IRVK
1 Kings 5 in the IRVM
1 Kings 5 in the IRVM2
1 Kings 5 in the IRVO
1 Kings 5 in the IRVP
1 Kings 5 in the IRVT
1 Kings 5 in the IRVT2
1 Kings 5 in the IRVU
1 Kings 5 in the ISVN
1 Kings 5 in the JSNT
1 Kings 5 in the KAPI
1 Kings 5 in the KBT1ETNIK
1 Kings 5 in the KBV
1 Kings 5 in the KJV
1 Kings 5 in the KNFD
1 Kings 5 in the LBA
1 Kings 5 in the LBLA
1 Kings 5 in the LNT
1 Kings 5 in the LSV
1 Kings 5 in the MAAL
1 Kings 5 in the MBV
1 Kings 5 in the MBV2
1 Kings 5 in the MHNT
1 Kings 5 in the MKNFD
1 Kings 5 in the MNG
1 Kings 5 in the MNT
1 Kings 5 in the MNT2
1 Kings 5 in the MRS1T
1 Kings 5 in the NAA
1 Kings 5 in the NASB
1 Kings 5 in the NBLA
1 Kings 5 in the NBS
1 Kings 5 in the NBVTP
1 Kings 5 in the NET2
1 Kings 5 in the NIV11
1 Kings 5 in the NNT
1 Kings 5 in the NNT2
1 Kings 5 in the NNT3
1 Kings 5 in the PDDPT
1 Kings 5 in the PFNT
1 Kings 5 in the RMNT
1 Kings 5 in the SBIAS
1 Kings 5 in the SBIBS
1 Kings 5 in the SBIBS2
1 Kings 5 in the SBICS
1 Kings 5 in the SBIDS
1 Kings 5 in the SBIGS
1 Kings 5 in the SBIHS
1 Kings 5 in the SBIIS
1 Kings 5 in the SBIIS2
1 Kings 5 in the SBIIS3
1 Kings 5 in the SBIKS
1 Kings 5 in the SBIKS2
1 Kings 5 in the SBIMS
1 Kings 5 in the SBIOS
1 Kings 5 in the SBIPS
1 Kings 5 in the SBISS
1 Kings 5 in the SBITS
1 Kings 5 in the SBITS2
1 Kings 5 in the SBITS3
1 Kings 5 in the SBITS4
1 Kings 5 in the SBIUS
1 Kings 5 in the SBIVS
1 Kings 5 in the SBT
1 Kings 5 in the SBT1E
1 Kings 5 in the SCHL
1 Kings 5 in the SNT
1 Kings 5 in the SUSU
1 Kings 5 in the SUSU2
1 Kings 5 in the SYNO
1 Kings 5 in the TBIAOTANT
1 Kings 5 in the TBT1E
1 Kings 5 in the TBT1E2
1 Kings 5 in the TFTIP
1 Kings 5 in the TFTU
1 Kings 5 in the TGNTATF3T
1 Kings 5 in the THAI
1 Kings 5 in the TNFD
1 Kings 5 in the TNT
1 Kings 5 in the TNTIK
1 Kings 5 in the TNTIL
1 Kings 5 in the TNTIN
1 Kings 5 in the TNTIP
1 Kings 5 in the TNTIZ
1 Kings 5 in the TOMA
1 Kings 5 in the TTENT
1 Kings 5 in the UBG
1 Kings 5 in the UGV
1 Kings 5 in the UGV2
1 Kings 5 in the UGV3
1 Kings 5 in the VBL
1 Kings 5 in the VDCC
1 Kings 5 in the YALU
1 Kings 5 in the YAPE
1 Kings 5 in the YBVTP
1 Kings 5 in the ZBP