1 Samuel 26 (BOYCB)

1 Nígbà náà ni àwọn ará Sifi tọ Saulu wá sí Gibeah, wọn wí pé, “Dafidi kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hakila, èyí tí ó wà níwájú Jeṣimoni?” 2 Saulu sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sifi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àṣàyàn ènìyàn ni Israẹli sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dafidi ni ijù Sifi. 3 Saulu sì pàgọ́ rẹ̀ ní ibi òkè Hakila tí o wà níwájú Jeṣimoni lójú ọ̀nà, Dafidi sì jókòó ni ibi ijù náà, ó sì rí pé Saulu ń tẹ̀lé òun ni ijù náà. 4 Dafidi sì rán ayọ́lẹ̀wò jáde, ó sì mọ nítòótọ́ pé Saulu ń bọ̀. 5 Dafidi sì dìde, ó sì wá sí ibi ti Saulu pàgọ́ sí: Dafidi rí ibi tí Saulu gbé dùbúlẹ̀ sí, àti Abneri ọmọ Neri, olórí ogun rẹ̀: Saulu sì dùbúlẹ̀ láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, àwọn ènìyàn náà sì pàgọ́ wọn yí i ká. 6 Dafidi sì dáhùn, ó sì wí fún Ahimeleki, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hiti, àti fún Abiṣai ọmọ Seruiah ẹ̀gbọ́n Joabu, pé, “Ta ni yóò ba mi sọ̀kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Saulu ni ibùdó?”Abiṣai sì wí pé, “Èmi yóò ba ọ sọ̀kalẹ̀ lọ.” 7 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti Abiṣai sì tọ àwọn ènìyàn náà wá lóru: sì wò ó, Saulu dùbúlẹ̀ ó sì ń sùn láàrín kẹ̀kẹ́, a sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ni ibi tìmùtìmù rẹ̀: Abneri àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká. 8 Abiṣai sì wí fún Dafidi pé, “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí: ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, sá à jẹ́ kí èmi o fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, èmi kì yóò gun un lẹ́ẹ̀méjì.” 9 Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Má ṣe pa á nítorí pé ta ni lè na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró OLÚWA kí ó sì wà láìjẹ̀bi?” 10 Dafidi sì wí pé, “Bí OLÚWA tí ń bẹ OLÚWA yóò pa á, tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò sì pé tí yóò kú, tàbí òun ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ìjà yóò sì ṣègbé níbẹ̀. 11 OLÚWA má jẹ́ kí èmi na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró OLÚWA. Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, mú ọ̀kọ̀ náà tí ń bẹ níbi tìmùtìmù rẹ̀, àti ìgò omi kí a sì máa lọ.” 12 Dafidi sì mú ọ̀kọ̀ náà àti ìgò omi náà kúrò níbi tìmùtìmù Saulu: wọ́n sì bá tiwọn lọ, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí i, tàbí tí ó mọ̀: kò sì sí ẹnìkan tí ó jí; gbogbo wọn sì sùn; nítorí pé oorun èjìká láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá ti ṣubú lù wọ́n. 13 Dafidi sì rékọjá sí ìhà kejì, ó sì dúró lórí òkè kan tí ó jìnnà réré; àlàfo kan sì wà láàrín méjì wọn. 14 Dafidi sì kọ sí àwọn ènìyàn náà àti sí Abneri ọmọ Neri wí pé, “Ìwọ kò dáhùn, Abneri?”Nígbà náà ni Abneri sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ta ni ń pe ọba?” 15 Dafidi sì wí fún Abneri pé, “Alágbára ọkùnrin kọ́ ni ìwọ bí? Ta ni ó sì dàbí ìwọ ni Israẹli? Ǹjẹ́ èéṣe tí ìwọ kò tọ́jú ọba Olúwa rẹ? Nítorí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn náà ti wọlé wá láti pa ọba olúwa rẹ. 16 Nǹkan tí ìwọ ṣe yìí kò dára. Bí OLÚWA ti ń bẹ, o tọ́ kí ẹ̀yin ó kú, nítorí pé ẹ̀yin kò pa olúwa yín mọ́, ẹni àmì òróró OLÚWA. Ǹjẹ́ sì wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba gbé wà, àti ìgò omi tí ó ti wà níbi tìmùtìmù rẹ̀.” 17 Saulu sì mọ ohùn Dafidi, ó sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí Dafidi ọmọ mi?”Dafidi sì wí pé, “Ohùn mi ni, olúwa mi, ọba.” 18 Òun sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ṣe ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀? Kín ni èmi ṣe? Tàbí ìwà búburú wo ni ó wà lọ́wọ́ mi. 19 Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, olúwa mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Bí ó bá ṣe OLÚWA bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ; ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú OLÚWA; nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má ba à ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní OLÚWA, wí pé, ‘Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn.’ 20 Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú OLÚWA; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.” 21 Saulu sì wí pé, “Èmi ti dẹ́ṣẹ̀: yípadà, Dafidi ọmọ mi: nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe iyebíye lójú rẹ lónìí: wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ.” 22 Dafidi sì dáhùn, ó sì wí pé, “Wò ó, ọ̀kọ̀ ọba! Kí ó sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rékọjá wá gbà á. 23 Kí OLÚWA o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀: nítorí pé OLÚWA tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni àmì òróró OLÚWA. 24 Sì wò ó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí rẹ ti tóbi lónìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni ki ẹ̀mí mi ó tóbi lójú OLÚWA, kí ó sì gbà mí lọ́wọ́ ibi gbogbo.” 25 Saulu sì wí fún Dafidi pé, “Alábùkún fún ni ìwọ, Dafidi ọmọ mi: nítòótọ́ ìwọ yóò sì ṣe nǹkan ńlá, nítòótọ́ ìwọ yóò sì borí.”Dafidi sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, Saulu sì yípadà sí ibùgbé rẹ̀.

In Other Versions

1 Samuel 26 in the ANGEFD

1 Samuel 26 in the ANTPNG2D

1 Samuel 26 in the AS21

1 Samuel 26 in the BAGH

1 Samuel 26 in the BBPNG

1 Samuel 26 in the BBT1E

1 Samuel 26 in the BDS

1 Samuel 26 in the BEV

1 Samuel 26 in the BHAD

1 Samuel 26 in the BIB

1 Samuel 26 in the BLPT

1 Samuel 26 in the BNT

1 Samuel 26 in the BNTABOOT

1 Samuel 26 in the BNTLV

1 Samuel 26 in the BOATCB

1 Samuel 26 in the BOATCB2

1 Samuel 26 in the BOBCV

1 Samuel 26 in the BOCNT

1 Samuel 26 in the BOECS

1 Samuel 26 in the BOGWICC

1 Samuel 26 in the BOHCB

1 Samuel 26 in the BOHCV

1 Samuel 26 in the BOHLNT

1 Samuel 26 in the BOHNTLTAL

1 Samuel 26 in the BOICB

1 Samuel 26 in the BOILNTAP

1 Samuel 26 in the BOITCV

1 Samuel 26 in the BOKCV

1 Samuel 26 in the BOKCV2

1 Samuel 26 in the BOKHWOG

1 Samuel 26 in the BOKSSV

1 Samuel 26 in the BOLCB

1 Samuel 26 in the BOLCB2

1 Samuel 26 in the BOMCV

1 Samuel 26 in the BONAV

1 Samuel 26 in the BONCB

1 Samuel 26 in the BONLT

1 Samuel 26 in the BONUT2

1 Samuel 26 in the BOPLNT

1 Samuel 26 in the BOSCB

1 Samuel 26 in the BOSNC

1 Samuel 26 in the BOTLNT

1 Samuel 26 in the BOVCB

1 Samuel 26 in the BPBB

1 Samuel 26 in the BPH

1 Samuel 26 in the BSB

1 Samuel 26 in the CCB

1 Samuel 26 in the CUV

1 Samuel 26 in the CUVS

1 Samuel 26 in the DBT

1 Samuel 26 in the DGDNT

1 Samuel 26 in the DHNT

1 Samuel 26 in the DNT

1 Samuel 26 in the ELBE

1 Samuel 26 in the EMTV

1 Samuel 26 in the ESV

1 Samuel 26 in the FBV

1 Samuel 26 in the FEB

1 Samuel 26 in the GGMNT

1 Samuel 26 in the GNT

1 Samuel 26 in the HARY

1 Samuel 26 in the HNT

1 Samuel 26 in the IRVA

1 Samuel 26 in the IRVB

1 Samuel 26 in the IRVG

1 Samuel 26 in the IRVH

1 Samuel 26 in the IRVK

1 Samuel 26 in the IRVM

1 Samuel 26 in the IRVM2

1 Samuel 26 in the IRVO

1 Samuel 26 in the IRVP

1 Samuel 26 in the IRVT

1 Samuel 26 in the IRVT2

1 Samuel 26 in the IRVU

1 Samuel 26 in the ISVN

1 Samuel 26 in the JSNT

1 Samuel 26 in the KAPI

1 Samuel 26 in the KBT1ETNIK

1 Samuel 26 in the KBV

1 Samuel 26 in the KJV

1 Samuel 26 in the KNFD

1 Samuel 26 in the LBA

1 Samuel 26 in the LBLA

1 Samuel 26 in the LNT

1 Samuel 26 in the LSV

1 Samuel 26 in the MAAL

1 Samuel 26 in the MBV

1 Samuel 26 in the MBV2

1 Samuel 26 in the MHNT

1 Samuel 26 in the MKNFD

1 Samuel 26 in the MNG

1 Samuel 26 in the MNT

1 Samuel 26 in the MNT2

1 Samuel 26 in the MRS1T

1 Samuel 26 in the NAA

1 Samuel 26 in the NASB

1 Samuel 26 in the NBLA

1 Samuel 26 in the NBS

1 Samuel 26 in the NBVTP

1 Samuel 26 in the NET2

1 Samuel 26 in the NIV11

1 Samuel 26 in the NNT

1 Samuel 26 in the NNT2

1 Samuel 26 in the NNT3

1 Samuel 26 in the PDDPT

1 Samuel 26 in the PFNT

1 Samuel 26 in the RMNT

1 Samuel 26 in the SBIAS

1 Samuel 26 in the SBIBS

1 Samuel 26 in the SBIBS2

1 Samuel 26 in the SBICS

1 Samuel 26 in the SBIDS

1 Samuel 26 in the SBIGS

1 Samuel 26 in the SBIHS

1 Samuel 26 in the SBIIS

1 Samuel 26 in the SBIIS2

1 Samuel 26 in the SBIIS3

1 Samuel 26 in the SBIKS

1 Samuel 26 in the SBIKS2

1 Samuel 26 in the SBIMS

1 Samuel 26 in the SBIOS

1 Samuel 26 in the SBIPS

1 Samuel 26 in the SBISS

1 Samuel 26 in the SBITS

1 Samuel 26 in the SBITS2

1 Samuel 26 in the SBITS3

1 Samuel 26 in the SBITS4

1 Samuel 26 in the SBIUS

1 Samuel 26 in the SBIVS

1 Samuel 26 in the SBT

1 Samuel 26 in the SBT1E

1 Samuel 26 in the SCHL

1 Samuel 26 in the SNT

1 Samuel 26 in the SUSU

1 Samuel 26 in the SUSU2

1 Samuel 26 in the SYNO

1 Samuel 26 in the TBIAOTANT

1 Samuel 26 in the TBT1E

1 Samuel 26 in the TBT1E2

1 Samuel 26 in the TFTIP

1 Samuel 26 in the TFTU

1 Samuel 26 in the TGNTATF3T

1 Samuel 26 in the THAI

1 Samuel 26 in the TNFD

1 Samuel 26 in the TNT

1 Samuel 26 in the TNTIK

1 Samuel 26 in the TNTIL

1 Samuel 26 in the TNTIN

1 Samuel 26 in the TNTIP

1 Samuel 26 in the TNTIZ

1 Samuel 26 in the TOMA

1 Samuel 26 in the TTENT

1 Samuel 26 in the UBG

1 Samuel 26 in the UGV

1 Samuel 26 in the UGV2

1 Samuel 26 in the UGV3

1 Samuel 26 in the VBL

1 Samuel 26 in the VDCC

1 Samuel 26 in the YALU

1 Samuel 26 in the YAPE

1 Samuel 26 in the YBVTP

1 Samuel 26 in the ZBP