2 Corinthians 8 (BOYCB)
1 Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia. 2 Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. 3 Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. 4 Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. 5 Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnra wọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. 6 Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú. 7 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìyìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú. 8 Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìyìnrere ẹlòmíràn. 9 Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di tálákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀. 10 Àti nínú èyí ni mo fi ìmọ̀ràn mi fún yín, nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú. 11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó ba à lè ṣe pé, bí ìpinnu fún ṣíṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín. 12 Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní. 13 Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba. 14 Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín, kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. 15 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.” 16 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Titu fún yín. 17 Nítorí kì í ṣe pé òun gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa nìkan ni; ṣùgbọ́n bí òun ti ní ìtara púpọ̀, òun tìkára rẹ̀ tọ̀ yín wá, fúnra rẹ̀. 18 Àwa ti rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ìyìn ẹni tí ó wà nínú ìyìnrere yíká gbogbo ìjọ. 19 Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra ìtara wa. 20 Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má ba à rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín. 21 Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú. 22 Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí ni ìtara rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntán ńlá tí ó ní sí yín. 23 Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Titu jẹ́, ẹlẹgbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń béèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kristi. 24 Nítorí náà ẹ fi ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín.
In Other Versions
2 Corinthians 8 in the ANGEFD
2 Corinthians 8 in the ANTPNG2D
2 Corinthians 8 in the AS21
2 Corinthians 8 in the BAGH
2 Corinthians 8 in the BBPNG
2 Corinthians 8 in the BBT1E
2 Corinthians 8 in the BDS
2 Corinthians 8 in the BEV
2 Corinthians 8 in the BHAD
2 Corinthians 8 in the BIB
2 Corinthians 8 in the BLPT
2 Corinthians 8 in the BNT
2 Corinthians 8 in the BNTABOOT
2 Corinthians 8 in the BNTLV
2 Corinthians 8 in the BOATCB
2 Corinthians 8 in the BOATCB2
2 Corinthians 8 in the BOBCV
2 Corinthians 8 in the BOCNT
2 Corinthians 8 in the BOECS
2 Corinthians 8 in the BOGWICC
2 Corinthians 8 in the BOHCB
2 Corinthians 8 in the BOHCV
2 Corinthians 8 in the BOHLNT
2 Corinthians 8 in the BOHNTLTAL
2 Corinthians 8 in the BOICB
2 Corinthians 8 in the BOILNTAP
2 Corinthians 8 in the BOITCV
2 Corinthians 8 in the BOKCV
2 Corinthians 8 in the BOKCV2
2 Corinthians 8 in the BOKHWOG
2 Corinthians 8 in the BOKSSV
2 Corinthians 8 in the BOLCB
2 Corinthians 8 in the BOLCB2
2 Corinthians 8 in the BOMCV
2 Corinthians 8 in the BONAV
2 Corinthians 8 in the BONCB
2 Corinthians 8 in the BONLT
2 Corinthians 8 in the BONUT2
2 Corinthians 8 in the BOPLNT
2 Corinthians 8 in the BOSCB
2 Corinthians 8 in the BOSNC
2 Corinthians 8 in the BOTLNT
2 Corinthians 8 in the BOVCB
2 Corinthians 8 in the BPBB
2 Corinthians 8 in the BPH
2 Corinthians 8 in the BSB
2 Corinthians 8 in the CCB
2 Corinthians 8 in the CUV
2 Corinthians 8 in the CUVS
2 Corinthians 8 in the DBT
2 Corinthians 8 in the DGDNT
2 Corinthians 8 in the DHNT
2 Corinthians 8 in the DNT
2 Corinthians 8 in the ELBE
2 Corinthians 8 in the EMTV
2 Corinthians 8 in the ESV
2 Corinthians 8 in the FBV
2 Corinthians 8 in the FEB
2 Corinthians 8 in the GGMNT
2 Corinthians 8 in the GNT
2 Corinthians 8 in the HARY
2 Corinthians 8 in the HNT
2 Corinthians 8 in the IRVA
2 Corinthians 8 in the IRVB
2 Corinthians 8 in the IRVG
2 Corinthians 8 in the IRVH
2 Corinthians 8 in the IRVK
2 Corinthians 8 in the IRVM
2 Corinthians 8 in the IRVM2
2 Corinthians 8 in the IRVO
2 Corinthians 8 in the IRVP
2 Corinthians 8 in the IRVT
2 Corinthians 8 in the IRVT2
2 Corinthians 8 in the IRVU
2 Corinthians 8 in the ISVN
2 Corinthians 8 in the JSNT
2 Corinthians 8 in the KAPI
2 Corinthians 8 in the KBT1ETNIK
2 Corinthians 8 in the KBV
2 Corinthians 8 in the KJV
2 Corinthians 8 in the KNFD
2 Corinthians 8 in the LBA
2 Corinthians 8 in the LBLA
2 Corinthians 8 in the LNT
2 Corinthians 8 in the LSV
2 Corinthians 8 in the MAAL
2 Corinthians 8 in the MBV
2 Corinthians 8 in the MBV2
2 Corinthians 8 in the MHNT
2 Corinthians 8 in the MKNFD
2 Corinthians 8 in the MNG
2 Corinthians 8 in the MNT
2 Corinthians 8 in the MNT2
2 Corinthians 8 in the MRS1T
2 Corinthians 8 in the NAA
2 Corinthians 8 in the NASB
2 Corinthians 8 in the NBLA
2 Corinthians 8 in the NBS
2 Corinthians 8 in the NBVTP
2 Corinthians 8 in the NET2
2 Corinthians 8 in the NIV11
2 Corinthians 8 in the NNT
2 Corinthians 8 in the NNT2
2 Corinthians 8 in the NNT3
2 Corinthians 8 in the PDDPT
2 Corinthians 8 in the PFNT
2 Corinthians 8 in the RMNT
2 Corinthians 8 in the SBIAS
2 Corinthians 8 in the SBIBS
2 Corinthians 8 in the SBIBS2
2 Corinthians 8 in the SBICS
2 Corinthians 8 in the SBIDS
2 Corinthians 8 in the SBIGS
2 Corinthians 8 in the SBIHS
2 Corinthians 8 in the SBIIS
2 Corinthians 8 in the SBIIS2
2 Corinthians 8 in the SBIIS3
2 Corinthians 8 in the SBIKS
2 Corinthians 8 in the SBIKS2
2 Corinthians 8 in the SBIMS
2 Corinthians 8 in the SBIOS
2 Corinthians 8 in the SBIPS
2 Corinthians 8 in the SBISS
2 Corinthians 8 in the SBITS
2 Corinthians 8 in the SBITS2
2 Corinthians 8 in the SBITS3
2 Corinthians 8 in the SBITS4
2 Corinthians 8 in the SBIUS
2 Corinthians 8 in the SBIVS
2 Corinthians 8 in the SBT
2 Corinthians 8 in the SBT1E
2 Corinthians 8 in the SCHL
2 Corinthians 8 in the SNT
2 Corinthians 8 in the SUSU
2 Corinthians 8 in the SUSU2
2 Corinthians 8 in the SYNO
2 Corinthians 8 in the TBIAOTANT
2 Corinthians 8 in the TBT1E
2 Corinthians 8 in the TBT1E2
2 Corinthians 8 in the TFTIP
2 Corinthians 8 in the TFTU
2 Corinthians 8 in the TGNTATF3T
2 Corinthians 8 in the THAI
2 Corinthians 8 in the TNFD
2 Corinthians 8 in the TNT
2 Corinthians 8 in the TNTIK
2 Corinthians 8 in the TNTIL
2 Corinthians 8 in the TNTIN
2 Corinthians 8 in the TNTIP
2 Corinthians 8 in the TNTIZ
2 Corinthians 8 in the TOMA
2 Corinthians 8 in the TTENT
2 Corinthians 8 in the UBG
2 Corinthians 8 in the UGV
2 Corinthians 8 in the UGV2
2 Corinthians 8 in the UGV3
2 Corinthians 8 in the VBL
2 Corinthians 8 in the VDCC
2 Corinthians 8 in the YALU
2 Corinthians 8 in the YAPE
2 Corinthians 8 in the YBVTP
2 Corinthians 8 in the ZBP