2 Kings 22 (BOYCB)

1 Josiah jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jedida ọmọbìnrin Adaiah; ó wá láti Boskati. 2 Ó sì ṣe èyí tí ó dára lójú OLÚWA, ó sì rìn ní ọ̀nà Dafidi baba a rẹ̀, kò sì yípadà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì. 3 Ní ọdún kejìdínlógún tí ó fi jẹ ọba. Ọba Josiah rán akọ̀wé, Ṣafani ọmọ Asalia, ọmọ Meṣullamu, sí ilé OLÚWA. Ó wí pé, 4 “Gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, kí o sì jẹ́ kí ó ṣírò iye owó tí a mú wá sí ilé OLÚWA, tí àwọn olùṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn. 5 Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé OLÚWA. Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé OLÚWA ṣe. 6 Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé. Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹmpili ṣe. 7 Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.” 8 Hilkiah olórí àlùfáà sọ fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi rí ìwé òfin nílé OLÚWA.” Ó fi fún Ṣafani, ẹni tí ó kà á. 9 Nígbà náà, Ṣafani akọ̀wé lọ sí ọ̀dọ̀ ọba. Ó sì sọ fún un pé, “Àwọn ìjòyè rẹ ti san owó náà tí ó wà nínú ilé OLÚWA. Èmi sì ti fi lé ọwọ́ àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà àti àwọn alábojútó nílé OLÚWA.” 10 Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sọ fún ọba pé, “Hilkiah àlùfáà ti fún un ní ìwé kan.” Ṣafani kà lára rẹ̀ níwájú ọba. 11 Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya. 12 Ó pa àṣẹ yìí fún Ahikamu àlùfáà, Hilkiah ọmọ Ṣafani, Akbori ọmọ Mikaiah, àti Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba. 13 “Lọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ OLÚWA fún mi àti fún àwọn ènìyàn àti fún gbogbo Juda nípa ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú OLÚWA tí ó ń jó sí wa nítorí àwọn baba wa kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí; wọn kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ níbẹ̀ nípa wa.” 14 Hilkiah àlùfáà, Ahikamu àti Akbori Ṣafani pẹ̀lú Asaiah, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Hulda láti lọ bá a sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tikfa ọmọ Harhasi alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jerusalẹmu ní ìdàkejì. 15 Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Israẹli wí, Sọ fún ọkùnrin tí ó rán an yín sí mi, 16 ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Juda ti kà. 17 Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì tún sun tùràrí fún ọlọ́run mìíràn. Wọ́n sì mú mi bínú nípa gbogbo àwọn òrìṣà tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn dá. Ìbínú mi yóò ru sí ibí yìí, kì yóò sì rọlẹ̀.’ 18 Sọ fún ọba Juda tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ OLÚWA, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Israẹli wí nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí ìwọ ti gbọ́. 19 Nítorí tí ọkàn rẹ rọ̀, tí ìwọ sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú OLÚWA, nígbà tí ìwọ gbọ́ èyí tí mo sọ sí ibí yìí àti sí àwọn ènìyàn rẹ pé wọn yóò di ahoro àti ẹni ègún tí ìwọ sì fa aṣọ ọ̀ rẹ ya pẹ̀lú níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ, ni OLÚWA wí. 20 Nítorí náà èmi yóò kó ọ jọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baba à rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kì yóò rí gbogbo àwọn ibi tí èmi yóò mú wá bá ibí yìí.’ ”Bẹ́ẹ̀ wọ́n mú èsì rẹ̀ padà tọ ọba wá.

In Other Versions

2 Kings 22 in the ANGEFD

2 Kings 22 in the ANTPNG2D

2 Kings 22 in the AS21

2 Kings 22 in the BAGH

2 Kings 22 in the BBPNG

2 Kings 22 in the BBT1E

2 Kings 22 in the BDS

2 Kings 22 in the BEV

2 Kings 22 in the BHAD

2 Kings 22 in the BIB

2 Kings 22 in the BLPT

2 Kings 22 in the BNT

2 Kings 22 in the BNTABOOT

2 Kings 22 in the BNTLV

2 Kings 22 in the BOATCB

2 Kings 22 in the BOATCB2

2 Kings 22 in the BOBCV

2 Kings 22 in the BOCNT

2 Kings 22 in the BOECS

2 Kings 22 in the BOGWICC

2 Kings 22 in the BOHCB

2 Kings 22 in the BOHCV

2 Kings 22 in the BOHLNT

2 Kings 22 in the BOHNTLTAL

2 Kings 22 in the BOICB

2 Kings 22 in the BOILNTAP

2 Kings 22 in the BOITCV

2 Kings 22 in the BOKCV

2 Kings 22 in the BOKCV2

2 Kings 22 in the BOKHWOG

2 Kings 22 in the BOKSSV

2 Kings 22 in the BOLCB

2 Kings 22 in the BOLCB2

2 Kings 22 in the BOMCV

2 Kings 22 in the BONAV

2 Kings 22 in the BONCB

2 Kings 22 in the BONLT

2 Kings 22 in the BONUT2

2 Kings 22 in the BOPLNT

2 Kings 22 in the BOSCB

2 Kings 22 in the BOSNC

2 Kings 22 in the BOTLNT

2 Kings 22 in the BOVCB

2 Kings 22 in the BPBB

2 Kings 22 in the BPH

2 Kings 22 in the BSB

2 Kings 22 in the CCB

2 Kings 22 in the CUV

2 Kings 22 in the CUVS

2 Kings 22 in the DBT

2 Kings 22 in the DGDNT

2 Kings 22 in the DHNT

2 Kings 22 in the DNT

2 Kings 22 in the ELBE

2 Kings 22 in the EMTV

2 Kings 22 in the ESV

2 Kings 22 in the FBV

2 Kings 22 in the FEB

2 Kings 22 in the GGMNT

2 Kings 22 in the GNT

2 Kings 22 in the HARY

2 Kings 22 in the HNT

2 Kings 22 in the IRVA

2 Kings 22 in the IRVB

2 Kings 22 in the IRVG

2 Kings 22 in the IRVH

2 Kings 22 in the IRVK

2 Kings 22 in the IRVM

2 Kings 22 in the IRVM2

2 Kings 22 in the IRVO

2 Kings 22 in the IRVP

2 Kings 22 in the IRVT

2 Kings 22 in the IRVT2

2 Kings 22 in the IRVU

2 Kings 22 in the ISVN

2 Kings 22 in the JSNT

2 Kings 22 in the KAPI

2 Kings 22 in the KBT1ETNIK

2 Kings 22 in the KBV

2 Kings 22 in the KJV

2 Kings 22 in the KNFD

2 Kings 22 in the LBA

2 Kings 22 in the LBLA

2 Kings 22 in the LNT

2 Kings 22 in the LSV

2 Kings 22 in the MAAL

2 Kings 22 in the MBV

2 Kings 22 in the MBV2

2 Kings 22 in the MHNT

2 Kings 22 in the MKNFD

2 Kings 22 in the MNG

2 Kings 22 in the MNT

2 Kings 22 in the MNT2

2 Kings 22 in the MRS1T

2 Kings 22 in the NAA

2 Kings 22 in the NASB

2 Kings 22 in the NBLA

2 Kings 22 in the NBS

2 Kings 22 in the NBVTP

2 Kings 22 in the NET2

2 Kings 22 in the NIV11

2 Kings 22 in the NNT

2 Kings 22 in the NNT2

2 Kings 22 in the NNT3

2 Kings 22 in the PDDPT

2 Kings 22 in the PFNT

2 Kings 22 in the RMNT

2 Kings 22 in the SBIAS

2 Kings 22 in the SBIBS

2 Kings 22 in the SBIBS2

2 Kings 22 in the SBICS

2 Kings 22 in the SBIDS

2 Kings 22 in the SBIGS

2 Kings 22 in the SBIHS

2 Kings 22 in the SBIIS

2 Kings 22 in the SBIIS2

2 Kings 22 in the SBIIS3

2 Kings 22 in the SBIKS

2 Kings 22 in the SBIKS2

2 Kings 22 in the SBIMS

2 Kings 22 in the SBIOS

2 Kings 22 in the SBIPS

2 Kings 22 in the SBISS

2 Kings 22 in the SBITS

2 Kings 22 in the SBITS2

2 Kings 22 in the SBITS3

2 Kings 22 in the SBITS4

2 Kings 22 in the SBIUS

2 Kings 22 in the SBIVS

2 Kings 22 in the SBT

2 Kings 22 in the SBT1E

2 Kings 22 in the SCHL

2 Kings 22 in the SNT

2 Kings 22 in the SUSU

2 Kings 22 in the SUSU2

2 Kings 22 in the SYNO

2 Kings 22 in the TBIAOTANT

2 Kings 22 in the TBT1E

2 Kings 22 in the TBT1E2

2 Kings 22 in the TFTIP

2 Kings 22 in the TFTU

2 Kings 22 in the TGNTATF3T

2 Kings 22 in the THAI

2 Kings 22 in the TNFD

2 Kings 22 in the TNT

2 Kings 22 in the TNTIK

2 Kings 22 in the TNTIL

2 Kings 22 in the TNTIN

2 Kings 22 in the TNTIP

2 Kings 22 in the TNTIZ

2 Kings 22 in the TOMA

2 Kings 22 in the TTENT

2 Kings 22 in the UBG

2 Kings 22 in the UGV

2 Kings 22 in the UGV2

2 Kings 22 in the UGV3

2 Kings 22 in the VBL

2 Kings 22 in the VDCC

2 Kings 22 in the YALU

2 Kings 22 in the YAPE

2 Kings 22 in the YBVTP

2 Kings 22 in the ZBP