2 Peter 2 (BOYCB)

1 Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn. 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. 3 Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé. 4 Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn angẹli si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀run àpáàdì tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́. 5 Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. 6 Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́; 8 (nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́). 9 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 10 Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè.Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo. 11 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn angẹli bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó o nì, wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa. 12 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí, bí ẹranko igbó tí kò ní èrò, ẹranko sá á tí a dá láti máa mú pa, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn, a ó pa wọn run pátápátá nínú ìbàjẹ́ ara wọn. 13 Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jayé nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àsè pẹ̀lú yín. 14 Ojú wọn kún fún panṣágà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ń tan àwọn tí ọkàn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ; àwọn tí wọ́n ní ọkàn tí ó ti yege nínú wọ̀bìà, ọmọ ègún ni wọ́n. 15 Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìṣòdodo. 16 Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí ìrékọjá rẹ̀, odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì fi òpin sí ìṣiwèrè wòlíì náà. 17 Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. 18 Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà. 19 Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀. 20 Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ. 21 Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọn má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọn yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn. 22 Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára, “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”

In Other Versions

2 Peter 2 in the ANGEFD

2 Peter 2 in the ANTPNG2D

2 Peter 2 in the AS21

2 Peter 2 in the BAGH

2 Peter 2 in the BBPNG

2 Peter 2 in the BBT1E

2 Peter 2 in the BDS

2 Peter 2 in the BEV

2 Peter 2 in the BHAD

2 Peter 2 in the BIB

2 Peter 2 in the BLPT

2 Peter 2 in the BNT

2 Peter 2 in the BNTABOOT

2 Peter 2 in the BNTLV

2 Peter 2 in the BOATCB

2 Peter 2 in the BOATCB2

2 Peter 2 in the BOBCV

2 Peter 2 in the BOCNT

2 Peter 2 in the BOECS

2 Peter 2 in the BOGWICC

2 Peter 2 in the BOHCB

2 Peter 2 in the BOHCV

2 Peter 2 in the BOHLNT

2 Peter 2 in the BOHNTLTAL

2 Peter 2 in the BOICB

2 Peter 2 in the BOILNTAP

2 Peter 2 in the BOITCV

2 Peter 2 in the BOKCV

2 Peter 2 in the BOKCV2

2 Peter 2 in the BOKHWOG

2 Peter 2 in the BOKSSV

2 Peter 2 in the BOLCB

2 Peter 2 in the BOLCB2

2 Peter 2 in the BOMCV

2 Peter 2 in the BONAV

2 Peter 2 in the BONCB

2 Peter 2 in the BONLT

2 Peter 2 in the BONUT2

2 Peter 2 in the BOPLNT

2 Peter 2 in the BOSCB

2 Peter 2 in the BOSNC

2 Peter 2 in the BOTLNT

2 Peter 2 in the BOVCB

2 Peter 2 in the BPBB

2 Peter 2 in the BPH

2 Peter 2 in the BSB

2 Peter 2 in the CCB

2 Peter 2 in the CUV

2 Peter 2 in the CUVS

2 Peter 2 in the DBT

2 Peter 2 in the DGDNT

2 Peter 2 in the DHNT

2 Peter 2 in the DNT

2 Peter 2 in the ELBE

2 Peter 2 in the EMTV

2 Peter 2 in the ESV

2 Peter 2 in the FBV

2 Peter 2 in the FEB

2 Peter 2 in the GGMNT

2 Peter 2 in the GNT

2 Peter 2 in the HARY

2 Peter 2 in the HNT

2 Peter 2 in the IRVA

2 Peter 2 in the IRVB

2 Peter 2 in the IRVG

2 Peter 2 in the IRVH

2 Peter 2 in the IRVK

2 Peter 2 in the IRVM

2 Peter 2 in the IRVM2

2 Peter 2 in the IRVO

2 Peter 2 in the IRVP

2 Peter 2 in the IRVT

2 Peter 2 in the IRVT2

2 Peter 2 in the IRVU

2 Peter 2 in the ISVN

2 Peter 2 in the JSNT

2 Peter 2 in the KAPI

2 Peter 2 in the KBT1ETNIK

2 Peter 2 in the KBV

2 Peter 2 in the KJV

2 Peter 2 in the KNFD

2 Peter 2 in the LBA

2 Peter 2 in the LBLA

2 Peter 2 in the LNT

2 Peter 2 in the LSV

2 Peter 2 in the MAAL

2 Peter 2 in the MBV

2 Peter 2 in the MBV2

2 Peter 2 in the MHNT

2 Peter 2 in the MKNFD

2 Peter 2 in the MNG

2 Peter 2 in the MNT

2 Peter 2 in the MNT2

2 Peter 2 in the MRS1T

2 Peter 2 in the NAA

2 Peter 2 in the NASB

2 Peter 2 in the NBLA

2 Peter 2 in the NBS

2 Peter 2 in the NBVTP

2 Peter 2 in the NET2

2 Peter 2 in the NIV11

2 Peter 2 in the NNT

2 Peter 2 in the NNT2

2 Peter 2 in the NNT3

2 Peter 2 in the PDDPT

2 Peter 2 in the PFNT

2 Peter 2 in the RMNT

2 Peter 2 in the SBIAS

2 Peter 2 in the SBIBS

2 Peter 2 in the SBIBS2

2 Peter 2 in the SBICS

2 Peter 2 in the SBIDS

2 Peter 2 in the SBIGS

2 Peter 2 in the SBIHS

2 Peter 2 in the SBIIS

2 Peter 2 in the SBIIS2

2 Peter 2 in the SBIIS3

2 Peter 2 in the SBIKS

2 Peter 2 in the SBIKS2

2 Peter 2 in the SBIMS

2 Peter 2 in the SBIOS

2 Peter 2 in the SBIPS

2 Peter 2 in the SBISS

2 Peter 2 in the SBITS

2 Peter 2 in the SBITS2

2 Peter 2 in the SBITS3

2 Peter 2 in the SBITS4

2 Peter 2 in the SBIUS

2 Peter 2 in the SBIVS

2 Peter 2 in the SBT

2 Peter 2 in the SBT1E

2 Peter 2 in the SCHL

2 Peter 2 in the SNT

2 Peter 2 in the SUSU

2 Peter 2 in the SUSU2

2 Peter 2 in the SYNO

2 Peter 2 in the TBIAOTANT

2 Peter 2 in the TBT1E

2 Peter 2 in the TBT1E2

2 Peter 2 in the TFTIP

2 Peter 2 in the TFTU

2 Peter 2 in the TGNTATF3T

2 Peter 2 in the THAI

2 Peter 2 in the TNFD

2 Peter 2 in the TNT

2 Peter 2 in the TNTIK

2 Peter 2 in the TNTIL

2 Peter 2 in the TNTIN

2 Peter 2 in the TNTIP

2 Peter 2 in the TNTIZ

2 Peter 2 in the TOMA

2 Peter 2 in the TTENT

2 Peter 2 in the UBG

2 Peter 2 in the UGV

2 Peter 2 in the UGV2

2 Peter 2 in the UGV3

2 Peter 2 in the VBL

2 Peter 2 in the VDCC

2 Peter 2 in the YALU

2 Peter 2 in the YAPE

2 Peter 2 in the YBVTP

2 Peter 2 in the ZBP