2 Samuel 10 (BOYCB)
1 Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ará Ammoni sì kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 2 Dafidi sì wí pé, “Èmi yóò ṣe oore fún Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dafidi sì ránṣẹ́ láti tù Hanuni nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀.Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ammoni. 3 Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.” 4 Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ. 5 Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.” 6 Àwọn ará Ammoni sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dafidi, àwọn ọmọ Ammoni sì ránṣẹ́, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Siria ti Beti-Rehobu; àti Siria-Soba, ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ti ọba Maaka, ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin àti ti Tobu ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ọkùnrin lọ́wẹ̀. 7 Dafidi sì gbọ́, ó sì rán Joabu, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára. 8 Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi; ará Siria-Soba, àti ti Rehobu, àti Tobu, àti Maaka, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn. 9 Nígbà tí Joabu sì rí i pé ogun náà dojúkọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Israẹli, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Siria. 10 Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Abiṣai àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ammoni. 11 Ó sì wí pé, “Bí agbára àwọn ará Siria bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́, ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ammoni bá sì pọ̀jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́. 12 Mú ọkàn lè, jẹ́ kí a ṣe onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa, àti nítorí àwọn ìlú Ọlọ́run wa; OLÚWA yóò sì ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.” 13 Joabu àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Siria pàdé ìjà, wọ́n sì sá níwájú rẹ̀. 14 Nígbà tí àwọn ọmọ Ammoni sì rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Abiṣai, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Joabu sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ammoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu. 15 Nígbà tí àwọn ará Siria sì rí i pé àwọn ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì kó ara wọn jọ 16 Hadadeseri sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Siria tí ó wà ní òkè odò Eufurate jáde wá, wọ́n sì wá sí Helami; Sobaki olórí ogun Hadadeseri sì ṣe olórí wọn. 17 Nígbà tí a sọ fún Dafidi, ó sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì wá sí Helami, àwọn ará Siria sì tẹ́ ogun kọjú sí Dafidi, wọ́n sì bá a jà. 18 Àwọn ará Siria sì sá níwájú Israẹli, Dafidi sì pa nínú àwọn ará Siria ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sobaki olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ̀. 19 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadeseri sì rí i pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n.Àwọn ará Siria sì bẹ̀rù láti máa ran àwọn ọmọ Ammoni lọ́wọ́ mọ́.
In Other Versions
2 Samuel 10 in the ANGEFD
2 Samuel 10 in the ANTPNG2D
2 Samuel 10 in the AS21
2 Samuel 10 in the BAGH
2 Samuel 10 in the BBPNG
2 Samuel 10 in the BBT1E
2 Samuel 10 in the BDS
2 Samuel 10 in the BEV
2 Samuel 10 in the BHAD
2 Samuel 10 in the BIB
2 Samuel 10 in the BLPT
2 Samuel 10 in the BNT
2 Samuel 10 in the BNTABOOT
2 Samuel 10 in the BNTLV
2 Samuel 10 in the BOATCB
2 Samuel 10 in the BOATCB2
2 Samuel 10 in the BOBCV
2 Samuel 10 in the BOCNT
2 Samuel 10 in the BOECS
2 Samuel 10 in the BOGWICC
2 Samuel 10 in the BOHCB
2 Samuel 10 in the BOHCV
2 Samuel 10 in the BOHLNT
2 Samuel 10 in the BOHNTLTAL
2 Samuel 10 in the BOICB
2 Samuel 10 in the BOILNTAP
2 Samuel 10 in the BOITCV
2 Samuel 10 in the BOKCV
2 Samuel 10 in the BOKCV2
2 Samuel 10 in the BOKHWOG
2 Samuel 10 in the BOKSSV
2 Samuel 10 in the BOLCB
2 Samuel 10 in the BOLCB2
2 Samuel 10 in the BOMCV
2 Samuel 10 in the BONAV
2 Samuel 10 in the BONCB
2 Samuel 10 in the BONLT
2 Samuel 10 in the BONUT2
2 Samuel 10 in the BOPLNT
2 Samuel 10 in the BOSCB
2 Samuel 10 in the BOSNC
2 Samuel 10 in the BOTLNT
2 Samuel 10 in the BOVCB
2 Samuel 10 in the BPBB
2 Samuel 10 in the BPH
2 Samuel 10 in the BSB
2 Samuel 10 in the CCB
2 Samuel 10 in the CUV
2 Samuel 10 in the CUVS
2 Samuel 10 in the DBT
2 Samuel 10 in the DGDNT
2 Samuel 10 in the DHNT
2 Samuel 10 in the DNT
2 Samuel 10 in the ELBE
2 Samuel 10 in the EMTV
2 Samuel 10 in the ESV
2 Samuel 10 in the FBV
2 Samuel 10 in the FEB
2 Samuel 10 in the GGMNT
2 Samuel 10 in the GNT
2 Samuel 10 in the HARY
2 Samuel 10 in the HNT
2 Samuel 10 in the IRVA
2 Samuel 10 in the IRVB
2 Samuel 10 in the IRVG
2 Samuel 10 in the IRVH
2 Samuel 10 in the IRVK
2 Samuel 10 in the IRVM
2 Samuel 10 in the IRVM2
2 Samuel 10 in the IRVO
2 Samuel 10 in the IRVP
2 Samuel 10 in the IRVT
2 Samuel 10 in the IRVT2
2 Samuel 10 in the IRVU
2 Samuel 10 in the ISVN
2 Samuel 10 in the JSNT
2 Samuel 10 in the KAPI
2 Samuel 10 in the KBT1ETNIK
2 Samuel 10 in the KBV
2 Samuel 10 in the KJV
2 Samuel 10 in the KNFD
2 Samuel 10 in the LBA
2 Samuel 10 in the LBLA
2 Samuel 10 in the LNT
2 Samuel 10 in the LSV
2 Samuel 10 in the MAAL
2 Samuel 10 in the MBV
2 Samuel 10 in the MBV2
2 Samuel 10 in the MHNT
2 Samuel 10 in the MKNFD
2 Samuel 10 in the MNG
2 Samuel 10 in the MNT
2 Samuel 10 in the MNT2
2 Samuel 10 in the MRS1T
2 Samuel 10 in the NAA
2 Samuel 10 in the NASB
2 Samuel 10 in the NBLA
2 Samuel 10 in the NBS
2 Samuel 10 in the NBVTP
2 Samuel 10 in the NET2
2 Samuel 10 in the NIV11
2 Samuel 10 in the NNT
2 Samuel 10 in the NNT2
2 Samuel 10 in the NNT3
2 Samuel 10 in the PDDPT
2 Samuel 10 in the PFNT
2 Samuel 10 in the RMNT
2 Samuel 10 in the SBIAS
2 Samuel 10 in the SBIBS
2 Samuel 10 in the SBIBS2
2 Samuel 10 in the SBICS
2 Samuel 10 in the SBIDS
2 Samuel 10 in the SBIGS
2 Samuel 10 in the SBIHS
2 Samuel 10 in the SBIIS
2 Samuel 10 in the SBIIS2
2 Samuel 10 in the SBIIS3
2 Samuel 10 in the SBIKS
2 Samuel 10 in the SBIKS2
2 Samuel 10 in the SBIMS
2 Samuel 10 in the SBIOS
2 Samuel 10 in the SBIPS
2 Samuel 10 in the SBISS
2 Samuel 10 in the SBITS
2 Samuel 10 in the SBITS2
2 Samuel 10 in the SBITS3
2 Samuel 10 in the SBITS4
2 Samuel 10 in the SBIUS
2 Samuel 10 in the SBIVS
2 Samuel 10 in the SBT
2 Samuel 10 in the SBT1E
2 Samuel 10 in the SCHL
2 Samuel 10 in the SNT
2 Samuel 10 in the SUSU
2 Samuel 10 in the SUSU2
2 Samuel 10 in the SYNO
2 Samuel 10 in the TBIAOTANT
2 Samuel 10 in the TBT1E
2 Samuel 10 in the TBT1E2
2 Samuel 10 in the TFTIP
2 Samuel 10 in the TFTU
2 Samuel 10 in the TGNTATF3T
2 Samuel 10 in the THAI
2 Samuel 10 in the TNFD
2 Samuel 10 in the TNT
2 Samuel 10 in the TNTIK
2 Samuel 10 in the TNTIL
2 Samuel 10 in the TNTIN
2 Samuel 10 in the TNTIP
2 Samuel 10 in the TNTIZ
2 Samuel 10 in the TOMA
2 Samuel 10 in the TTENT
2 Samuel 10 in the UBG
2 Samuel 10 in the UGV
2 Samuel 10 in the UGV2
2 Samuel 10 in the UGV3
2 Samuel 10 in the VBL
2 Samuel 10 in the VDCC
2 Samuel 10 in the YALU
2 Samuel 10 in the YAPE
2 Samuel 10 in the YBVTP
2 Samuel 10 in the ZBP