2 Samuel 22 (BOYCB)

1 Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí OLÚWA ní ọjọ́ tí OLÚWA gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu. 2 Ó sì wí pé,“OLÚWA ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi; 3 Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi.Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi;ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá. 4 “Èmi ké pe OLÚWA, tí ó yẹ láti máa yìn,ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. 5 Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. 6 Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri;ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. 7 “Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé OLÚWA,èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi.Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀igbe mí wọ etí rẹ̀. 8 Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì;ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì,ó sì mì, nítorí tí ó bínú. 9 Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá,iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀. 10 Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀;òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. 11 Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò,a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́. 12 Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi,àní ìṣúdudu ìkùùkuu àwọ̀ sánmọ̀. 13 Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ẹ̀yín iná ràn. 14 OLÚWA sán àrá láti ọ̀run wá,Ọ̀gá-ògo jùlọ sì fọhùn rẹ̀. 15 Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn. 16 Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn,ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,nípa ìbáwí OLÚWA,nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀. 17 “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá. 18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. 19 Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi,ṣùgbọ́n OLÚWA ni aláfẹ̀yìntì mi. 20 Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá,ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi. 21 “OLÚWA sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi. 22 Nítorí pé èmi pa ọ̀nà OLÚWA mọ́,èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. 23 Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn. 24 Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í,èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. 25 OLÚWA sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀. 26 “Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú,àti fún ẹni ìdúró ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró ṣinṣin ní òdodo. 27 Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun;àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́. 28 Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà;ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. 29 Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, OLÚWA; OLÚWA yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. 30 Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá;nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan. 31 “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;ọ̀rọ̀ OLÚWA ni a ti dánwò.Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e. 32 Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe OLÚWA?Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa. 33 Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára,ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́. 34 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;ó sì mú mi dúró ní ibi gíga mi. 35 Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà;tó bẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ. 36 Ìwọ sì ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ̀;ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá. 37 Ìwọ sì sọ ìtẹ̀lẹ̀ di ńlá ní abẹ́ mi;tó bẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀. 38 “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n,èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n. 39 Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn,wọn kò sì le dìde mọ́, wọ́n ṣubú lábẹ́ mi. 40 Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà;àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi. 41 Ìwọ sì mú àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà fún mi,èmi ó sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. 42 Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n;wọ́n wo OLÚWA, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn. 43 Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ. 44 “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi,ìwọ pa mi mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè.Àwọn ènìyàn tí èmi kò tí mọ̀ yóò máa sìn mí. 45 Àwọn àjèjì wá láti tẹríba fún mi;bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọ́n á sì gbọ́ tèmi. 46 Àyà yóò pá àwọn àlejò,wọ́n ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn. 47 “OLÚWA ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi!Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi. 48 Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi,àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi. 49 Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó kórìíra mi lọ;ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá. 50 Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, OLÚWA,láàrín àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè, èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ. 51 “Òun ni ilé ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀;ó sì fi àánú hàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀,fún Dafidi, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”

In Other Versions

2 Samuel 22 in the ANGEFD

2 Samuel 22 in the ANTPNG2D

2 Samuel 22 in the AS21

2 Samuel 22 in the BAGH

2 Samuel 22 in the BBPNG

2 Samuel 22 in the BBT1E

2 Samuel 22 in the BDS

2 Samuel 22 in the BEV

2 Samuel 22 in the BHAD

2 Samuel 22 in the BIB

2 Samuel 22 in the BLPT

2 Samuel 22 in the BNT

2 Samuel 22 in the BNTABOOT

2 Samuel 22 in the BNTLV

2 Samuel 22 in the BOATCB

2 Samuel 22 in the BOATCB2

2 Samuel 22 in the BOBCV

2 Samuel 22 in the BOCNT

2 Samuel 22 in the BOECS

2 Samuel 22 in the BOGWICC

2 Samuel 22 in the BOHCB

2 Samuel 22 in the BOHCV

2 Samuel 22 in the BOHLNT

2 Samuel 22 in the BOHNTLTAL

2 Samuel 22 in the BOICB

2 Samuel 22 in the BOILNTAP

2 Samuel 22 in the BOITCV

2 Samuel 22 in the BOKCV

2 Samuel 22 in the BOKCV2

2 Samuel 22 in the BOKHWOG

2 Samuel 22 in the BOKSSV

2 Samuel 22 in the BOLCB

2 Samuel 22 in the BOLCB2

2 Samuel 22 in the BOMCV

2 Samuel 22 in the BONAV

2 Samuel 22 in the BONCB

2 Samuel 22 in the BONLT

2 Samuel 22 in the BONUT2

2 Samuel 22 in the BOPLNT

2 Samuel 22 in the BOSCB

2 Samuel 22 in the BOSNC

2 Samuel 22 in the BOTLNT

2 Samuel 22 in the BOVCB

2 Samuel 22 in the BPBB

2 Samuel 22 in the BPH

2 Samuel 22 in the BSB

2 Samuel 22 in the CCB

2 Samuel 22 in the CUV

2 Samuel 22 in the CUVS

2 Samuel 22 in the DBT

2 Samuel 22 in the DGDNT

2 Samuel 22 in the DHNT

2 Samuel 22 in the DNT

2 Samuel 22 in the ELBE

2 Samuel 22 in the EMTV

2 Samuel 22 in the ESV

2 Samuel 22 in the FBV

2 Samuel 22 in the FEB

2 Samuel 22 in the GGMNT

2 Samuel 22 in the GNT

2 Samuel 22 in the HARY

2 Samuel 22 in the HNT

2 Samuel 22 in the IRVA

2 Samuel 22 in the IRVB

2 Samuel 22 in the IRVG

2 Samuel 22 in the IRVH

2 Samuel 22 in the IRVK

2 Samuel 22 in the IRVM

2 Samuel 22 in the IRVM2

2 Samuel 22 in the IRVO

2 Samuel 22 in the IRVP

2 Samuel 22 in the IRVT

2 Samuel 22 in the IRVT2

2 Samuel 22 in the IRVU

2 Samuel 22 in the ISVN

2 Samuel 22 in the JSNT

2 Samuel 22 in the KAPI

2 Samuel 22 in the KBT1ETNIK

2 Samuel 22 in the KBV

2 Samuel 22 in the KJV

2 Samuel 22 in the KNFD

2 Samuel 22 in the LBA

2 Samuel 22 in the LBLA

2 Samuel 22 in the LNT

2 Samuel 22 in the LSV

2 Samuel 22 in the MAAL

2 Samuel 22 in the MBV

2 Samuel 22 in the MBV2

2 Samuel 22 in the MHNT

2 Samuel 22 in the MKNFD

2 Samuel 22 in the MNG

2 Samuel 22 in the MNT

2 Samuel 22 in the MNT2

2 Samuel 22 in the MRS1T

2 Samuel 22 in the NAA

2 Samuel 22 in the NASB

2 Samuel 22 in the NBLA

2 Samuel 22 in the NBS

2 Samuel 22 in the NBVTP

2 Samuel 22 in the NET2

2 Samuel 22 in the NIV11

2 Samuel 22 in the NNT

2 Samuel 22 in the NNT2

2 Samuel 22 in the NNT3

2 Samuel 22 in the PDDPT

2 Samuel 22 in the PFNT

2 Samuel 22 in the RMNT

2 Samuel 22 in the SBIAS

2 Samuel 22 in the SBIBS

2 Samuel 22 in the SBIBS2

2 Samuel 22 in the SBICS

2 Samuel 22 in the SBIDS

2 Samuel 22 in the SBIGS

2 Samuel 22 in the SBIHS

2 Samuel 22 in the SBIIS

2 Samuel 22 in the SBIIS2

2 Samuel 22 in the SBIIS3

2 Samuel 22 in the SBIKS

2 Samuel 22 in the SBIKS2

2 Samuel 22 in the SBIMS

2 Samuel 22 in the SBIOS

2 Samuel 22 in the SBIPS

2 Samuel 22 in the SBISS

2 Samuel 22 in the SBITS

2 Samuel 22 in the SBITS2

2 Samuel 22 in the SBITS3

2 Samuel 22 in the SBITS4

2 Samuel 22 in the SBIUS

2 Samuel 22 in the SBIVS

2 Samuel 22 in the SBT

2 Samuel 22 in the SBT1E

2 Samuel 22 in the SCHL

2 Samuel 22 in the SNT

2 Samuel 22 in the SUSU

2 Samuel 22 in the SUSU2

2 Samuel 22 in the SYNO

2 Samuel 22 in the TBIAOTANT

2 Samuel 22 in the TBT1E

2 Samuel 22 in the TBT1E2

2 Samuel 22 in the TFTIP

2 Samuel 22 in the TFTU

2 Samuel 22 in the TGNTATF3T

2 Samuel 22 in the THAI

2 Samuel 22 in the TNFD

2 Samuel 22 in the TNT

2 Samuel 22 in the TNTIK

2 Samuel 22 in the TNTIL

2 Samuel 22 in the TNTIN

2 Samuel 22 in the TNTIP

2 Samuel 22 in the TNTIZ

2 Samuel 22 in the TOMA

2 Samuel 22 in the TTENT

2 Samuel 22 in the UBG

2 Samuel 22 in the UGV

2 Samuel 22 in the UGV2

2 Samuel 22 in the UGV3

2 Samuel 22 in the VBL

2 Samuel 22 in the VDCC

2 Samuel 22 in the YALU

2 Samuel 22 in the YAPE

2 Samuel 22 in the YBVTP

2 Samuel 22 in the ZBP