2 Samuel 6 (BOYCB)
1 Dafidi sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Israẹli jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000). 2 Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù. 3 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu wá, èyí tí ó wà ní Gibeah: Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà. 4 Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà. 5 Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú OLÚWA lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali. 6 Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Nakoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dìímú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀. 7 Ìbínú OLÚWA sì ru sí Ussa; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣísẹ̀ rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. 8 Inú Dafidi sì bàjẹ́ nítorí tí OLÚWA gé Ussa kúrò, ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresi-Usa títí ó fi di òní yìí. 9 Dafidi sì bẹ̀rù OLÚWA ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí ẹ̀rí OLÚWA yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?” 10 Dafidi kò sì fẹ́ mú àpótí ẹ̀rí OLÚWA sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dafidi; ṣùgbọ́n Dafidi sì mú un yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. 11 Àpótí ẹ̀rí OLÚWA sì gbé ní ilé Obedi-Edomu ará Gitti ní oṣù mẹ́ta; OLÚWA sì bùkún fún Obedi-Edomu, àti gbogbo ilé rẹ̀. 12 A sì rò fún Dafidi ọba pé, “OLÚWA ti bùkún fún ilé Obedi-Edomu, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dafidi sì lọ, ó sì mú àpótí ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedi-Edomu wá sí ìlú Dafidi pẹ̀lú ayọ̀. 13 Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí OLÚWA bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ. 14 Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú OLÚWA; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀. 15 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè. 16 Bí àpótí ẹ̀rí OLÚWA sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú OLÚWA; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀. 17 Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí OLÚWA náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú OLÚWA. 18 Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. 19 Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀. 20 Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.” 21 Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú OLÚWA ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn OLÚWA, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú OLÚWA. 22 Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.” 23 Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.
In Other Versions
2 Samuel 6 in the ANGEFD
2 Samuel 6 in the ANTPNG2D
2 Samuel 6 in the AS21
2 Samuel 6 in the BAGH
2 Samuel 6 in the BBPNG
2 Samuel 6 in the BBT1E
2 Samuel 6 in the BDS
2 Samuel 6 in the BEV
2 Samuel 6 in the BHAD
2 Samuel 6 in the BIB
2 Samuel 6 in the BLPT
2 Samuel 6 in the BNT
2 Samuel 6 in the BNTABOOT
2 Samuel 6 in the BNTLV
2 Samuel 6 in the BOATCB
2 Samuel 6 in the BOATCB2
2 Samuel 6 in the BOBCV
2 Samuel 6 in the BOCNT
2 Samuel 6 in the BOECS
2 Samuel 6 in the BOGWICC
2 Samuel 6 in the BOHCB
2 Samuel 6 in the BOHCV
2 Samuel 6 in the BOHLNT
2 Samuel 6 in the BOHNTLTAL
2 Samuel 6 in the BOICB
2 Samuel 6 in the BOILNTAP
2 Samuel 6 in the BOITCV
2 Samuel 6 in the BOKCV
2 Samuel 6 in the BOKCV2
2 Samuel 6 in the BOKHWOG
2 Samuel 6 in the BOKSSV
2 Samuel 6 in the BOLCB
2 Samuel 6 in the BOLCB2
2 Samuel 6 in the BOMCV
2 Samuel 6 in the BONAV
2 Samuel 6 in the BONCB
2 Samuel 6 in the BONLT
2 Samuel 6 in the BONUT2
2 Samuel 6 in the BOPLNT
2 Samuel 6 in the BOSCB
2 Samuel 6 in the BOSNC
2 Samuel 6 in the BOTLNT
2 Samuel 6 in the BOVCB
2 Samuel 6 in the BPBB
2 Samuel 6 in the BPH
2 Samuel 6 in the BSB
2 Samuel 6 in the CCB
2 Samuel 6 in the CUV
2 Samuel 6 in the CUVS
2 Samuel 6 in the DBT
2 Samuel 6 in the DGDNT
2 Samuel 6 in the DHNT
2 Samuel 6 in the DNT
2 Samuel 6 in the ELBE
2 Samuel 6 in the EMTV
2 Samuel 6 in the ESV
2 Samuel 6 in the FBV
2 Samuel 6 in the FEB
2 Samuel 6 in the GGMNT
2 Samuel 6 in the GNT
2 Samuel 6 in the HARY
2 Samuel 6 in the HNT
2 Samuel 6 in the IRVA
2 Samuel 6 in the IRVB
2 Samuel 6 in the IRVG
2 Samuel 6 in the IRVH
2 Samuel 6 in the IRVK
2 Samuel 6 in the IRVM
2 Samuel 6 in the IRVM2
2 Samuel 6 in the IRVO
2 Samuel 6 in the IRVP
2 Samuel 6 in the IRVT
2 Samuel 6 in the IRVT2
2 Samuel 6 in the IRVU
2 Samuel 6 in the ISVN
2 Samuel 6 in the JSNT
2 Samuel 6 in the KAPI
2 Samuel 6 in the KBT1ETNIK
2 Samuel 6 in the KBV
2 Samuel 6 in the KJV
2 Samuel 6 in the KNFD
2 Samuel 6 in the LBA
2 Samuel 6 in the LBLA
2 Samuel 6 in the LNT
2 Samuel 6 in the LSV
2 Samuel 6 in the MAAL
2 Samuel 6 in the MBV
2 Samuel 6 in the MBV2
2 Samuel 6 in the MHNT
2 Samuel 6 in the MKNFD
2 Samuel 6 in the MNG
2 Samuel 6 in the MNT
2 Samuel 6 in the MNT2
2 Samuel 6 in the MRS1T
2 Samuel 6 in the NAA
2 Samuel 6 in the NASB
2 Samuel 6 in the NBLA
2 Samuel 6 in the NBS
2 Samuel 6 in the NBVTP
2 Samuel 6 in the NET2
2 Samuel 6 in the NIV11
2 Samuel 6 in the NNT
2 Samuel 6 in the NNT2
2 Samuel 6 in the NNT3
2 Samuel 6 in the PDDPT
2 Samuel 6 in the PFNT
2 Samuel 6 in the RMNT
2 Samuel 6 in the SBIAS
2 Samuel 6 in the SBIBS
2 Samuel 6 in the SBIBS2
2 Samuel 6 in the SBICS
2 Samuel 6 in the SBIDS
2 Samuel 6 in the SBIGS
2 Samuel 6 in the SBIHS
2 Samuel 6 in the SBIIS
2 Samuel 6 in the SBIIS2
2 Samuel 6 in the SBIIS3
2 Samuel 6 in the SBIKS
2 Samuel 6 in the SBIKS2
2 Samuel 6 in the SBIMS
2 Samuel 6 in the SBIOS
2 Samuel 6 in the SBIPS
2 Samuel 6 in the SBISS
2 Samuel 6 in the SBITS
2 Samuel 6 in the SBITS2
2 Samuel 6 in the SBITS3
2 Samuel 6 in the SBITS4
2 Samuel 6 in the SBIUS
2 Samuel 6 in the SBIVS
2 Samuel 6 in the SBT
2 Samuel 6 in the SBT1E
2 Samuel 6 in the SCHL
2 Samuel 6 in the SNT
2 Samuel 6 in the SUSU
2 Samuel 6 in the SUSU2
2 Samuel 6 in the SYNO
2 Samuel 6 in the TBIAOTANT
2 Samuel 6 in the TBT1E
2 Samuel 6 in the TBT1E2
2 Samuel 6 in the TFTIP
2 Samuel 6 in the TFTU
2 Samuel 6 in the TGNTATF3T
2 Samuel 6 in the THAI
2 Samuel 6 in the TNFD
2 Samuel 6 in the TNT
2 Samuel 6 in the TNTIK
2 Samuel 6 in the TNTIL
2 Samuel 6 in the TNTIN
2 Samuel 6 in the TNTIP
2 Samuel 6 in the TNTIZ
2 Samuel 6 in the TOMA
2 Samuel 6 in the TTENT
2 Samuel 6 in the UBG
2 Samuel 6 in the UGV
2 Samuel 6 in the UGV2
2 Samuel 6 in the UGV3
2 Samuel 6 in the VBL
2 Samuel 6 in the VDCC
2 Samuel 6 in the YALU
2 Samuel 6 in the YAPE
2 Samuel 6 in the YBVTP
2 Samuel 6 in the ZBP