2 Timothy 3 (BOYCB)

1 Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀ pé, ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. 2 Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. 3 Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, 4 oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. 5 Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. 6 Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri. 7 Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. 8 Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. 9 Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si. 10 Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. 11 Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. 12 Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. 14 Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. 15 Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 16 Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo. 17 Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.

In Other Versions

2 Timothy 3 in the ANGEFD

2 Timothy 3 in the ANTPNG2D

2 Timothy 3 in the AS21

2 Timothy 3 in the BAGH

2 Timothy 3 in the BBPNG

2 Timothy 3 in the BBT1E

2 Timothy 3 in the BDS

2 Timothy 3 in the BEV

2 Timothy 3 in the BHAD

2 Timothy 3 in the BIB

2 Timothy 3 in the BLPT

2 Timothy 3 in the BNT

2 Timothy 3 in the BNTABOOT

2 Timothy 3 in the BNTLV

2 Timothy 3 in the BOATCB

2 Timothy 3 in the BOATCB2

2 Timothy 3 in the BOBCV

2 Timothy 3 in the BOCNT

2 Timothy 3 in the BOECS

2 Timothy 3 in the BOGWICC

2 Timothy 3 in the BOHCB

2 Timothy 3 in the BOHCV

2 Timothy 3 in the BOHLNT

2 Timothy 3 in the BOHNTLTAL

2 Timothy 3 in the BOICB

2 Timothy 3 in the BOILNTAP

2 Timothy 3 in the BOITCV

2 Timothy 3 in the BOKCV

2 Timothy 3 in the BOKCV2

2 Timothy 3 in the BOKHWOG

2 Timothy 3 in the BOKSSV

2 Timothy 3 in the BOLCB

2 Timothy 3 in the BOLCB2

2 Timothy 3 in the BOMCV

2 Timothy 3 in the BONAV

2 Timothy 3 in the BONCB

2 Timothy 3 in the BONLT

2 Timothy 3 in the BONUT2

2 Timothy 3 in the BOPLNT

2 Timothy 3 in the BOSCB

2 Timothy 3 in the BOSNC

2 Timothy 3 in the BOTLNT

2 Timothy 3 in the BOVCB

2 Timothy 3 in the BPBB

2 Timothy 3 in the BPH

2 Timothy 3 in the BSB

2 Timothy 3 in the CCB

2 Timothy 3 in the CUV

2 Timothy 3 in the CUVS

2 Timothy 3 in the DBT

2 Timothy 3 in the DGDNT

2 Timothy 3 in the DHNT

2 Timothy 3 in the DNT

2 Timothy 3 in the ELBE

2 Timothy 3 in the EMTV

2 Timothy 3 in the ESV

2 Timothy 3 in the FBV

2 Timothy 3 in the FEB

2 Timothy 3 in the GGMNT

2 Timothy 3 in the GNT

2 Timothy 3 in the HARY

2 Timothy 3 in the HNT

2 Timothy 3 in the IRVA

2 Timothy 3 in the IRVB

2 Timothy 3 in the IRVG

2 Timothy 3 in the IRVH

2 Timothy 3 in the IRVK

2 Timothy 3 in the IRVM

2 Timothy 3 in the IRVM2

2 Timothy 3 in the IRVO

2 Timothy 3 in the IRVP

2 Timothy 3 in the IRVT

2 Timothy 3 in the IRVT2

2 Timothy 3 in the IRVU

2 Timothy 3 in the ISVN

2 Timothy 3 in the JSNT

2 Timothy 3 in the KAPI

2 Timothy 3 in the KBT1ETNIK

2 Timothy 3 in the KBV

2 Timothy 3 in the KJV

2 Timothy 3 in the KNFD

2 Timothy 3 in the LBA

2 Timothy 3 in the LBLA

2 Timothy 3 in the LNT

2 Timothy 3 in the LSV

2 Timothy 3 in the MAAL

2 Timothy 3 in the MBV

2 Timothy 3 in the MBV2

2 Timothy 3 in the MHNT

2 Timothy 3 in the MKNFD

2 Timothy 3 in the MNG

2 Timothy 3 in the MNT

2 Timothy 3 in the MNT2

2 Timothy 3 in the MRS1T

2 Timothy 3 in the NAA

2 Timothy 3 in the NASB

2 Timothy 3 in the NBLA

2 Timothy 3 in the NBS

2 Timothy 3 in the NBVTP

2 Timothy 3 in the NET2

2 Timothy 3 in the NIV11

2 Timothy 3 in the NNT

2 Timothy 3 in the NNT2

2 Timothy 3 in the NNT3

2 Timothy 3 in the PDDPT

2 Timothy 3 in the PFNT

2 Timothy 3 in the RMNT

2 Timothy 3 in the SBIAS

2 Timothy 3 in the SBIBS

2 Timothy 3 in the SBIBS2

2 Timothy 3 in the SBICS

2 Timothy 3 in the SBIDS

2 Timothy 3 in the SBIGS

2 Timothy 3 in the SBIHS

2 Timothy 3 in the SBIIS

2 Timothy 3 in the SBIIS2

2 Timothy 3 in the SBIIS3

2 Timothy 3 in the SBIKS

2 Timothy 3 in the SBIKS2

2 Timothy 3 in the SBIMS

2 Timothy 3 in the SBIOS

2 Timothy 3 in the SBIPS

2 Timothy 3 in the SBISS

2 Timothy 3 in the SBITS

2 Timothy 3 in the SBITS2

2 Timothy 3 in the SBITS3

2 Timothy 3 in the SBITS4

2 Timothy 3 in the SBIUS

2 Timothy 3 in the SBIVS

2 Timothy 3 in the SBT

2 Timothy 3 in the SBT1E

2 Timothy 3 in the SCHL

2 Timothy 3 in the SNT

2 Timothy 3 in the SUSU

2 Timothy 3 in the SUSU2

2 Timothy 3 in the SYNO

2 Timothy 3 in the TBIAOTANT

2 Timothy 3 in the TBT1E

2 Timothy 3 in the TBT1E2

2 Timothy 3 in the TFTIP

2 Timothy 3 in the TFTU

2 Timothy 3 in the TGNTATF3T

2 Timothy 3 in the THAI

2 Timothy 3 in the TNFD

2 Timothy 3 in the TNT

2 Timothy 3 in the TNTIK

2 Timothy 3 in the TNTIL

2 Timothy 3 in the TNTIN

2 Timothy 3 in the TNTIP

2 Timothy 3 in the TNTIZ

2 Timothy 3 in the TOMA

2 Timothy 3 in the TTENT

2 Timothy 3 in the UBG

2 Timothy 3 in the UGV

2 Timothy 3 in the UGV2

2 Timothy 3 in the UGV3

2 Timothy 3 in the VBL

2 Timothy 3 in the VDCC

2 Timothy 3 in the YALU

2 Timothy 3 in the YAPE

2 Timothy 3 in the YBVTP

2 Timothy 3 in the ZBP