Deuteronomy 10 (BOYCB)

1 Nígbà náà ni OLÚWA wí fún mi pé, “Gbé wàláà òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún fi igi kan àpótí kan. 2 Èmi yóò sì kọ ọ̀rọ̀ tí ó wà lára wàláà àkọ́kọ́ tí ìwọ fọ́, sára wàláà wọ̀nyí. Ìwọ yóò sì fi wọ́n sínú àpótí náà.” 3 Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kasia, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì lọ́wọ́ mí. 4 OLÚWA tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí wàláà wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. OLÚWA sì fi wọ́n fún mi. 5 Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn wàláà òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí OLÚWA ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí. 6 (Àwọn ará Israẹli sì gbéra láti kànga àwọn ará Jaakani dé Mosera. Níbí ni Aaroni kú sí, tí a sì sin ín, Eleasari ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà. 7 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gudgoda, títí dé Jotbata, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn. 8 Ní ìgbà yìí ni OLÚWA yan àwọn ẹ̀yà Lefi láti máa ru àpótí ẹ̀rí OLÚWA, láti máa dúró níwájú OLÚWA láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ OLÚWA súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí. 9 Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrín àwọn arákùnrin wọn. OLÚWA ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run ti sọ fún un yín.) 10 Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, OLÚWA sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín. 11 OLÚWA sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn bá à lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.” 12 Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin OLÚWA Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, 13 àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà OLÚWA tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ. 14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé OLÚWA Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. 15 Síbẹ̀ OLÚWA sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní. 16 Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ. 17 Torí pé OLÚWA Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18 Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn. 19 Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwọn àjèjì, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì rí ní Ejibiti. 20 Ẹ bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀. 21 Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí. 22 Àádọ́rin péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ṣùgbọ́n OLÚWA Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ sí i ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

In Other Versions

Deuteronomy 10 in the ANGEFD

Deuteronomy 10 in the ANTPNG2D

Deuteronomy 10 in the AS21

Deuteronomy 10 in the BAGH

Deuteronomy 10 in the BBPNG

Deuteronomy 10 in the BBT1E

Deuteronomy 10 in the BDS

Deuteronomy 10 in the BEV

Deuteronomy 10 in the BHAD

Deuteronomy 10 in the BIB

Deuteronomy 10 in the BLPT

Deuteronomy 10 in the BNT

Deuteronomy 10 in the BNTABOOT

Deuteronomy 10 in the BNTLV

Deuteronomy 10 in the BOATCB

Deuteronomy 10 in the BOATCB2

Deuteronomy 10 in the BOBCV

Deuteronomy 10 in the BOCNT

Deuteronomy 10 in the BOECS

Deuteronomy 10 in the BOGWICC

Deuteronomy 10 in the BOHCB

Deuteronomy 10 in the BOHCV

Deuteronomy 10 in the BOHLNT

Deuteronomy 10 in the BOHNTLTAL

Deuteronomy 10 in the BOICB

Deuteronomy 10 in the BOILNTAP

Deuteronomy 10 in the BOITCV

Deuteronomy 10 in the BOKCV

Deuteronomy 10 in the BOKCV2

Deuteronomy 10 in the BOKHWOG

Deuteronomy 10 in the BOKSSV

Deuteronomy 10 in the BOLCB

Deuteronomy 10 in the BOLCB2

Deuteronomy 10 in the BOMCV

Deuteronomy 10 in the BONAV

Deuteronomy 10 in the BONCB

Deuteronomy 10 in the BONLT

Deuteronomy 10 in the BONUT2

Deuteronomy 10 in the BOPLNT

Deuteronomy 10 in the BOSCB

Deuteronomy 10 in the BOSNC

Deuteronomy 10 in the BOTLNT

Deuteronomy 10 in the BOVCB

Deuteronomy 10 in the BPBB

Deuteronomy 10 in the BPH

Deuteronomy 10 in the BSB

Deuteronomy 10 in the CCB

Deuteronomy 10 in the CUV

Deuteronomy 10 in the CUVS

Deuteronomy 10 in the DBT

Deuteronomy 10 in the DGDNT

Deuteronomy 10 in the DHNT

Deuteronomy 10 in the DNT

Deuteronomy 10 in the ELBE

Deuteronomy 10 in the EMTV

Deuteronomy 10 in the ESV

Deuteronomy 10 in the FBV

Deuteronomy 10 in the FEB

Deuteronomy 10 in the GGMNT

Deuteronomy 10 in the GNT

Deuteronomy 10 in the HARY

Deuteronomy 10 in the HNT

Deuteronomy 10 in the IRVA

Deuteronomy 10 in the IRVB

Deuteronomy 10 in the IRVG

Deuteronomy 10 in the IRVH

Deuteronomy 10 in the IRVK

Deuteronomy 10 in the IRVM

Deuteronomy 10 in the IRVM2

Deuteronomy 10 in the IRVO

Deuteronomy 10 in the IRVP

Deuteronomy 10 in the IRVT

Deuteronomy 10 in the IRVT2

Deuteronomy 10 in the IRVU

Deuteronomy 10 in the ISVN

Deuteronomy 10 in the JSNT

Deuteronomy 10 in the KAPI

Deuteronomy 10 in the KBT1ETNIK

Deuteronomy 10 in the KBV

Deuteronomy 10 in the KJV

Deuteronomy 10 in the KNFD

Deuteronomy 10 in the LBA

Deuteronomy 10 in the LBLA

Deuteronomy 10 in the LNT

Deuteronomy 10 in the LSV

Deuteronomy 10 in the MAAL

Deuteronomy 10 in the MBV

Deuteronomy 10 in the MBV2

Deuteronomy 10 in the MHNT

Deuteronomy 10 in the MKNFD

Deuteronomy 10 in the MNG

Deuteronomy 10 in the MNT

Deuteronomy 10 in the MNT2

Deuteronomy 10 in the MRS1T

Deuteronomy 10 in the NAA

Deuteronomy 10 in the NASB

Deuteronomy 10 in the NBLA

Deuteronomy 10 in the NBS

Deuteronomy 10 in the NBVTP

Deuteronomy 10 in the NET2

Deuteronomy 10 in the NIV11

Deuteronomy 10 in the NNT

Deuteronomy 10 in the NNT2

Deuteronomy 10 in the NNT3

Deuteronomy 10 in the PDDPT

Deuteronomy 10 in the PFNT

Deuteronomy 10 in the RMNT

Deuteronomy 10 in the SBIAS

Deuteronomy 10 in the SBIBS

Deuteronomy 10 in the SBIBS2

Deuteronomy 10 in the SBICS

Deuteronomy 10 in the SBIDS

Deuteronomy 10 in the SBIGS

Deuteronomy 10 in the SBIHS

Deuteronomy 10 in the SBIIS

Deuteronomy 10 in the SBIIS2

Deuteronomy 10 in the SBIIS3

Deuteronomy 10 in the SBIKS

Deuteronomy 10 in the SBIKS2

Deuteronomy 10 in the SBIMS

Deuteronomy 10 in the SBIOS

Deuteronomy 10 in the SBIPS

Deuteronomy 10 in the SBISS

Deuteronomy 10 in the SBITS

Deuteronomy 10 in the SBITS2

Deuteronomy 10 in the SBITS3

Deuteronomy 10 in the SBITS4

Deuteronomy 10 in the SBIUS

Deuteronomy 10 in the SBIVS

Deuteronomy 10 in the SBT

Deuteronomy 10 in the SBT1E

Deuteronomy 10 in the SCHL

Deuteronomy 10 in the SNT

Deuteronomy 10 in the SUSU

Deuteronomy 10 in the SUSU2

Deuteronomy 10 in the SYNO

Deuteronomy 10 in the TBIAOTANT

Deuteronomy 10 in the TBT1E

Deuteronomy 10 in the TBT1E2

Deuteronomy 10 in the TFTIP

Deuteronomy 10 in the TFTU

Deuteronomy 10 in the TGNTATF3T

Deuteronomy 10 in the THAI

Deuteronomy 10 in the TNFD

Deuteronomy 10 in the TNT

Deuteronomy 10 in the TNTIK

Deuteronomy 10 in the TNTIL

Deuteronomy 10 in the TNTIN

Deuteronomy 10 in the TNTIP

Deuteronomy 10 in the TNTIZ

Deuteronomy 10 in the TOMA

Deuteronomy 10 in the TTENT

Deuteronomy 10 in the UBG

Deuteronomy 10 in the UGV

Deuteronomy 10 in the UGV2

Deuteronomy 10 in the UGV3

Deuteronomy 10 in the VBL

Deuteronomy 10 in the VDCC

Deuteronomy 10 in the YALU

Deuteronomy 10 in the YAPE

Deuteronomy 10 in the YBVTP

Deuteronomy 10 in the ZBP