Deuteronomy 26 (BOYCB)
1 Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀, 2 mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé. 3 Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé, “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí OLÚWA búra fún àwọn baba wa.” 4 Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ OLÚWA Ọlọ́run rẹ. 5 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. 6 Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe. 7 Nígbà náà ni a kégbe pe OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba wa, OLÚWA sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa. 8 Nígbà náà ni OLÚWA mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu. 9 Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; 10 àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ OLÚWA ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀. 11 Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí OLÚWA ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ. 12 Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó. 13 Nígbà náà ní kí o wí fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pàṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn. 14 Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí OLÚWA Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pàṣẹ fún mi. 15 Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Israẹli, àti fún ilẹ̀ náà tí ìwọ ti fi fún wa, bí ìwọ ti búra fún àwọn baba ńlá wa, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin.” 16 OLÚWA Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin, kí o sì máa ṣe wọ́n pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo àyà rẹ. 17 Ìwọ jẹ́wọ́ OLÚWA ní òní pé OLÚWA ni Ọlọ́run rẹ, àti pé ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, àti pé ìwọ yóò máa pa ìlànà rẹ̀, àṣẹ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti pé ìwọ yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i. 18 Ní òní ni OLÚWA jẹ́wọ́ rẹ pé ìwọ ni ènìyàn òun, ilé ìṣúra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí, àti pé ìwọ yóò máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́. 19 Òun sì jẹ́wọ́ pé, òun yóò gbé ọ sókè ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí òun ti dá lọ, ní ìyìn, ní òkìkí àti ní ọlá; kí ìwọ kí ó le jẹ́ ènìyàn mímọ́ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí.
In Other Versions
Deuteronomy 26 in the ANGEFD
Deuteronomy 26 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 26 in the AS21
Deuteronomy 26 in the BAGH
Deuteronomy 26 in the BBPNG
Deuteronomy 26 in the BBT1E
Deuteronomy 26 in the BDS
Deuteronomy 26 in the BEV
Deuteronomy 26 in the BHAD
Deuteronomy 26 in the BIB
Deuteronomy 26 in the BLPT
Deuteronomy 26 in the BNT
Deuteronomy 26 in the BNTABOOT
Deuteronomy 26 in the BNTLV
Deuteronomy 26 in the BOATCB
Deuteronomy 26 in the BOATCB2
Deuteronomy 26 in the BOBCV
Deuteronomy 26 in the BOCNT
Deuteronomy 26 in the BOECS
Deuteronomy 26 in the BOGWICC
Deuteronomy 26 in the BOHCB
Deuteronomy 26 in the BOHCV
Deuteronomy 26 in the BOHLNT
Deuteronomy 26 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 26 in the BOICB
Deuteronomy 26 in the BOILNTAP
Deuteronomy 26 in the BOITCV
Deuteronomy 26 in the BOKCV
Deuteronomy 26 in the BOKCV2
Deuteronomy 26 in the BOKHWOG
Deuteronomy 26 in the BOKSSV
Deuteronomy 26 in the BOLCB
Deuteronomy 26 in the BOLCB2
Deuteronomy 26 in the BOMCV
Deuteronomy 26 in the BONAV
Deuteronomy 26 in the BONCB
Deuteronomy 26 in the BONLT
Deuteronomy 26 in the BONUT2
Deuteronomy 26 in the BOPLNT
Deuteronomy 26 in the BOSCB
Deuteronomy 26 in the BOSNC
Deuteronomy 26 in the BOTLNT
Deuteronomy 26 in the BOVCB
Deuteronomy 26 in the BPBB
Deuteronomy 26 in the BPH
Deuteronomy 26 in the BSB
Deuteronomy 26 in the CCB
Deuteronomy 26 in the CUV
Deuteronomy 26 in the CUVS
Deuteronomy 26 in the DBT
Deuteronomy 26 in the DGDNT
Deuteronomy 26 in the DHNT
Deuteronomy 26 in the DNT
Deuteronomy 26 in the ELBE
Deuteronomy 26 in the EMTV
Deuteronomy 26 in the ESV
Deuteronomy 26 in the FBV
Deuteronomy 26 in the FEB
Deuteronomy 26 in the GGMNT
Deuteronomy 26 in the GNT
Deuteronomy 26 in the HARY
Deuteronomy 26 in the HNT
Deuteronomy 26 in the IRVA
Deuteronomy 26 in the IRVB
Deuteronomy 26 in the IRVG
Deuteronomy 26 in the IRVH
Deuteronomy 26 in the IRVK
Deuteronomy 26 in the IRVM
Deuteronomy 26 in the IRVM2
Deuteronomy 26 in the IRVO
Deuteronomy 26 in the IRVP
Deuteronomy 26 in the IRVT
Deuteronomy 26 in the IRVT2
Deuteronomy 26 in the IRVU
Deuteronomy 26 in the ISVN
Deuteronomy 26 in the JSNT
Deuteronomy 26 in the KAPI
Deuteronomy 26 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 26 in the KBV
Deuteronomy 26 in the KJV
Deuteronomy 26 in the KNFD
Deuteronomy 26 in the LBA
Deuteronomy 26 in the LBLA
Deuteronomy 26 in the LNT
Deuteronomy 26 in the LSV
Deuteronomy 26 in the MAAL
Deuteronomy 26 in the MBV
Deuteronomy 26 in the MBV2
Deuteronomy 26 in the MHNT
Deuteronomy 26 in the MKNFD
Deuteronomy 26 in the MNG
Deuteronomy 26 in the MNT
Deuteronomy 26 in the MNT2
Deuteronomy 26 in the MRS1T
Deuteronomy 26 in the NAA
Deuteronomy 26 in the NASB
Deuteronomy 26 in the NBLA
Deuteronomy 26 in the NBS
Deuteronomy 26 in the NBVTP
Deuteronomy 26 in the NET2
Deuteronomy 26 in the NIV11
Deuteronomy 26 in the NNT
Deuteronomy 26 in the NNT2
Deuteronomy 26 in the NNT3
Deuteronomy 26 in the PDDPT
Deuteronomy 26 in the PFNT
Deuteronomy 26 in the RMNT
Deuteronomy 26 in the SBIAS
Deuteronomy 26 in the SBIBS
Deuteronomy 26 in the SBIBS2
Deuteronomy 26 in the SBICS
Deuteronomy 26 in the SBIDS
Deuteronomy 26 in the SBIGS
Deuteronomy 26 in the SBIHS
Deuteronomy 26 in the SBIIS
Deuteronomy 26 in the SBIIS2
Deuteronomy 26 in the SBIIS3
Deuteronomy 26 in the SBIKS
Deuteronomy 26 in the SBIKS2
Deuteronomy 26 in the SBIMS
Deuteronomy 26 in the SBIOS
Deuteronomy 26 in the SBIPS
Deuteronomy 26 in the SBISS
Deuteronomy 26 in the SBITS
Deuteronomy 26 in the SBITS2
Deuteronomy 26 in the SBITS3
Deuteronomy 26 in the SBITS4
Deuteronomy 26 in the SBIUS
Deuteronomy 26 in the SBIVS
Deuteronomy 26 in the SBT
Deuteronomy 26 in the SBT1E
Deuteronomy 26 in the SCHL
Deuteronomy 26 in the SNT
Deuteronomy 26 in the SUSU
Deuteronomy 26 in the SUSU2
Deuteronomy 26 in the SYNO
Deuteronomy 26 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 26 in the TBT1E
Deuteronomy 26 in the TBT1E2
Deuteronomy 26 in the TFTIP
Deuteronomy 26 in the TFTU
Deuteronomy 26 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 26 in the THAI
Deuteronomy 26 in the TNFD
Deuteronomy 26 in the TNT
Deuteronomy 26 in the TNTIK
Deuteronomy 26 in the TNTIL
Deuteronomy 26 in the TNTIN
Deuteronomy 26 in the TNTIP
Deuteronomy 26 in the TNTIZ
Deuteronomy 26 in the TOMA
Deuteronomy 26 in the TTENT
Deuteronomy 26 in the UBG
Deuteronomy 26 in the UGV
Deuteronomy 26 in the UGV2
Deuteronomy 26 in the UGV3
Deuteronomy 26 in the VBL
Deuteronomy 26 in the VDCC
Deuteronomy 26 in the YALU
Deuteronomy 26 in the YAPE
Deuteronomy 26 in the YBVTP
Deuteronomy 26 in the ZBP