Ephesians 3 (BOYCB)
1 Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà. 2 Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín; 3 bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí. 4 Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi. 5 Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí; 6 pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìyìnrere. 7 Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. 8 Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà; 9 àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi. 10 Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ, 11 gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa. 12 Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. 13 Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín. 14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. 16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 17 Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; 18 kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. 19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín. 20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. 21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.
In Other Versions
Ephesians 3 in the ANGEFD
Ephesians 3 in the ANTPNG2D
Ephesians 3 in the AS21
Ephesians 3 in the BAGH
Ephesians 3 in the BBPNG
Ephesians 3 in the BBT1E
Ephesians 3 in the BDS
Ephesians 3 in the BEV
Ephesians 3 in the BHAD
Ephesians 3 in the BIB
Ephesians 3 in the BLPT
Ephesians 3 in the BNT
Ephesians 3 in the BNTABOOT
Ephesians 3 in the BNTLV
Ephesians 3 in the BOATCB
Ephesians 3 in the BOATCB2
Ephesians 3 in the BOBCV
Ephesians 3 in the BOCNT
Ephesians 3 in the BOECS
Ephesians 3 in the BOGWICC
Ephesians 3 in the BOHCB
Ephesians 3 in the BOHCV
Ephesians 3 in the BOHLNT
Ephesians 3 in the BOHNTLTAL
Ephesians 3 in the BOICB
Ephesians 3 in the BOILNTAP
Ephesians 3 in the BOITCV
Ephesians 3 in the BOKCV
Ephesians 3 in the BOKCV2
Ephesians 3 in the BOKHWOG
Ephesians 3 in the BOKSSV
Ephesians 3 in the BOLCB
Ephesians 3 in the BOLCB2
Ephesians 3 in the BOMCV
Ephesians 3 in the BONAV
Ephesians 3 in the BONCB
Ephesians 3 in the BONLT
Ephesians 3 in the BONUT2
Ephesians 3 in the BOPLNT
Ephesians 3 in the BOSCB
Ephesians 3 in the BOSNC
Ephesians 3 in the BOTLNT
Ephesians 3 in the BOVCB
Ephesians 3 in the BPBB
Ephesians 3 in the BPH
Ephesians 3 in the BSB
Ephesians 3 in the CCB
Ephesians 3 in the CUV
Ephesians 3 in the CUVS
Ephesians 3 in the DBT
Ephesians 3 in the DGDNT
Ephesians 3 in the DHNT
Ephesians 3 in the DNT
Ephesians 3 in the ELBE
Ephesians 3 in the EMTV
Ephesians 3 in the ESV
Ephesians 3 in the FBV
Ephesians 3 in the FEB
Ephesians 3 in the GGMNT
Ephesians 3 in the GNT
Ephesians 3 in the HARY
Ephesians 3 in the HNT
Ephesians 3 in the IRVA
Ephesians 3 in the IRVB
Ephesians 3 in the IRVG
Ephesians 3 in the IRVH
Ephesians 3 in the IRVK
Ephesians 3 in the IRVM
Ephesians 3 in the IRVM2
Ephesians 3 in the IRVO
Ephesians 3 in the IRVP
Ephesians 3 in the IRVT
Ephesians 3 in the IRVT2
Ephesians 3 in the IRVU
Ephesians 3 in the ISVN
Ephesians 3 in the JSNT
Ephesians 3 in the KAPI
Ephesians 3 in the KBT1ETNIK
Ephesians 3 in the KBV
Ephesians 3 in the KJV
Ephesians 3 in the KNFD
Ephesians 3 in the LBA
Ephesians 3 in the LBLA
Ephesians 3 in the LNT
Ephesians 3 in the LSV
Ephesians 3 in the MAAL
Ephesians 3 in the MBV
Ephesians 3 in the MBV2
Ephesians 3 in the MHNT
Ephesians 3 in the MKNFD
Ephesians 3 in the MNG
Ephesians 3 in the MNT
Ephesians 3 in the MNT2
Ephesians 3 in the MRS1T
Ephesians 3 in the NAA
Ephesians 3 in the NASB
Ephesians 3 in the NBLA
Ephesians 3 in the NBS
Ephesians 3 in the NBVTP
Ephesians 3 in the NET2
Ephesians 3 in the NIV11
Ephesians 3 in the NNT
Ephesians 3 in the NNT2
Ephesians 3 in the NNT3
Ephesians 3 in the PDDPT
Ephesians 3 in the PFNT
Ephesians 3 in the RMNT
Ephesians 3 in the SBIAS
Ephesians 3 in the SBIBS
Ephesians 3 in the SBIBS2
Ephesians 3 in the SBICS
Ephesians 3 in the SBIDS
Ephesians 3 in the SBIGS
Ephesians 3 in the SBIHS
Ephesians 3 in the SBIIS
Ephesians 3 in the SBIIS2
Ephesians 3 in the SBIIS3
Ephesians 3 in the SBIKS
Ephesians 3 in the SBIKS2
Ephesians 3 in the SBIMS
Ephesians 3 in the SBIOS
Ephesians 3 in the SBIPS
Ephesians 3 in the SBISS
Ephesians 3 in the SBITS
Ephesians 3 in the SBITS2
Ephesians 3 in the SBITS3
Ephesians 3 in the SBITS4
Ephesians 3 in the SBIUS
Ephesians 3 in the SBIVS
Ephesians 3 in the SBT
Ephesians 3 in the SBT1E
Ephesians 3 in the SCHL
Ephesians 3 in the SNT
Ephesians 3 in the SUSU
Ephesians 3 in the SUSU2
Ephesians 3 in the SYNO
Ephesians 3 in the TBIAOTANT
Ephesians 3 in the TBT1E
Ephesians 3 in the TBT1E2
Ephesians 3 in the TFTIP
Ephesians 3 in the TFTU
Ephesians 3 in the TGNTATF3T
Ephesians 3 in the THAI
Ephesians 3 in the TNFD
Ephesians 3 in the TNT
Ephesians 3 in the TNTIK
Ephesians 3 in the TNTIL
Ephesians 3 in the TNTIN
Ephesians 3 in the TNTIP
Ephesians 3 in the TNTIZ
Ephesians 3 in the TOMA
Ephesians 3 in the TTENT
Ephesians 3 in the UBG
Ephesians 3 in the UGV
Ephesians 3 in the UGV2
Ephesians 3 in the UGV3
Ephesians 3 in the VBL
Ephesians 3 in the VDCC
Ephesians 3 in the YALU
Ephesians 3 in the YAPE
Ephesians 3 in the YBVTP
Ephesians 3 in the ZBP