Exodus 1 (BOYCB)
1 Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ejibiti, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀: 2 Reubeni, Simeoni, Lefi àti Juda; 3 Isakari, Sebuluni àti Benjamini; 4 Dani àti Naftali;Gadi àti Aṣeri. 5 Àwọn ìran Jakọbu sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Josẹfu sì ti wà ní Ejibiti. 6 Wàyí o, Josẹfu àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú, 7 ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ń bí sí i, wọ́n ń pọ̀ sí i gidigidi, wọ́n kò sì ní òǹkà tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kún ilẹ̀ náà. 8 Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. 9 Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, “Ẹ wò ó, àwọn ará Israẹli ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa. 10 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.” 11 Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pitomi àti Ramesesi gẹ́gẹ́ bí ìlú ìṣúra pamọ́ sí fún Farao. 12 Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tànkálẹ̀. Nítorí náà, àwọn ará Ejibiti bẹ̀rù nítorí àwọn ará Israẹli. 13 Àwọn ará Ejibiti sì mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àsìnpa. 14 Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò. 15 Ọba Ejibiti sọ fún àwọn agbẹ̀bí Heberu ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifura àti Pua pé, 16 “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Heberu, tí ẹ sì kíyèsi wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láààyè.” 17 Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Ejibiti ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láààyè. 18 Ọba Ejibiti pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?” 19 Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Heberu kò rí bí àwọn obìnrin Ejibiti, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.” 20 Nítorí náà Ọlọ́run ṣàánú fún àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn ọmọ Israẹli sì ń le sí i, wọ́n sì ń pọ̀ sí i jọjọ. 21 Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, Ọlọ́run sì fún wọn ni ìdílé tiwọn. 22 Nígbà náà ni Farao pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Naili, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láààyè.”
In Other Versions
Exodus 1 in the ANGEFD
Exodus 1 in the ANTPNG2D
Exodus 1 in the AS21
Exodus 1 in the BAGH
Exodus 1 in the BBPNG
Exodus 1 in the BBT1E
Exodus 1 in the BDS
Exodus 1 in the BEV
Exodus 1 in the BHAD
Exodus 1 in the BIB
Exodus 1 in the BLPT
Exodus 1 in the BNT
Exodus 1 in the BNTABOOT
Exodus 1 in the BNTLV
Exodus 1 in the BOATCB
Exodus 1 in the BOATCB2
Exodus 1 in the BOBCV
Exodus 1 in the BOCNT
Exodus 1 in the BOECS
Exodus 1 in the BOGWICC
Exodus 1 in the BOHCB
Exodus 1 in the BOHCV
Exodus 1 in the BOHLNT
Exodus 1 in the BOHNTLTAL
Exodus 1 in the BOICB
Exodus 1 in the BOILNTAP
Exodus 1 in the BOITCV
Exodus 1 in the BOKCV
Exodus 1 in the BOKCV2
Exodus 1 in the BOKHWOG
Exodus 1 in the BOKSSV
Exodus 1 in the BOLCB
Exodus 1 in the BOLCB2
Exodus 1 in the BOMCV
Exodus 1 in the BONAV
Exodus 1 in the BONCB
Exodus 1 in the BONLT
Exodus 1 in the BONUT2
Exodus 1 in the BOPLNT
Exodus 1 in the BOSCB
Exodus 1 in the BOSNC
Exodus 1 in the BOTLNT
Exodus 1 in the BOVCB
Exodus 1 in the BPBB
Exodus 1 in the BPH
Exodus 1 in the BSB
Exodus 1 in the CCB
Exodus 1 in the CUV
Exodus 1 in the CUVS
Exodus 1 in the DBT
Exodus 1 in the DGDNT
Exodus 1 in the DHNT
Exodus 1 in the DNT
Exodus 1 in the ELBE
Exodus 1 in the EMTV
Exodus 1 in the ESV
Exodus 1 in the FBV
Exodus 1 in the FEB
Exodus 1 in the GGMNT
Exodus 1 in the GNT
Exodus 1 in the HARY
Exodus 1 in the HNT
Exodus 1 in the IRVA
Exodus 1 in the IRVB
Exodus 1 in the IRVG
Exodus 1 in the IRVH
Exodus 1 in the IRVK
Exodus 1 in the IRVM
Exodus 1 in the IRVM2
Exodus 1 in the IRVO
Exodus 1 in the IRVP
Exodus 1 in the IRVT
Exodus 1 in the IRVT2
Exodus 1 in the IRVU
Exodus 1 in the ISVN
Exodus 1 in the JSNT
Exodus 1 in the KAPI
Exodus 1 in the KBT1ETNIK
Exodus 1 in the KBV
Exodus 1 in the KJV
Exodus 1 in the KNFD
Exodus 1 in the LBA
Exodus 1 in the LBLA
Exodus 1 in the LNT
Exodus 1 in the LSV
Exodus 1 in the MAAL
Exodus 1 in the MBV
Exodus 1 in the MBV2
Exodus 1 in the MHNT
Exodus 1 in the MKNFD
Exodus 1 in the MNG
Exodus 1 in the MNT
Exodus 1 in the MNT2
Exodus 1 in the MRS1T
Exodus 1 in the NAA
Exodus 1 in the NASB
Exodus 1 in the NBLA
Exodus 1 in the NBS
Exodus 1 in the NBVTP
Exodus 1 in the NET2
Exodus 1 in the NIV11
Exodus 1 in the NNT
Exodus 1 in the NNT2
Exodus 1 in the NNT3
Exodus 1 in the PDDPT
Exodus 1 in the PFNT
Exodus 1 in the RMNT
Exodus 1 in the SBIAS
Exodus 1 in the SBIBS
Exodus 1 in the SBIBS2
Exodus 1 in the SBICS
Exodus 1 in the SBIDS
Exodus 1 in the SBIGS
Exodus 1 in the SBIHS
Exodus 1 in the SBIIS
Exodus 1 in the SBIIS2
Exodus 1 in the SBIIS3
Exodus 1 in the SBIKS
Exodus 1 in the SBIKS2
Exodus 1 in the SBIMS
Exodus 1 in the SBIOS
Exodus 1 in the SBIPS
Exodus 1 in the SBISS
Exodus 1 in the SBITS
Exodus 1 in the SBITS2
Exodus 1 in the SBITS3
Exodus 1 in the SBITS4
Exodus 1 in the SBIUS
Exodus 1 in the SBIVS
Exodus 1 in the SBT
Exodus 1 in the SBT1E
Exodus 1 in the SCHL
Exodus 1 in the SNT
Exodus 1 in the SUSU
Exodus 1 in the SUSU2
Exodus 1 in the SYNO
Exodus 1 in the TBIAOTANT
Exodus 1 in the TBT1E
Exodus 1 in the TBT1E2
Exodus 1 in the TFTIP
Exodus 1 in the TFTU
Exodus 1 in the TGNTATF3T
Exodus 1 in the THAI
Exodus 1 in the TNFD
Exodus 1 in the TNT
Exodus 1 in the TNTIK
Exodus 1 in the TNTIL
Exodus 1 in the TNTIN
Exodus 1 in the TNTIP
Exodus 1 in the TNTIZ
Exodus 1 in the TOMA
Exodus 1 in the TTENT
Exodus 1 in the UBG
Exodus 1 in the UGV
Exodus 1 in the UGV2
Exodus 1 in the UGV3
Exodus 1 in the VBL
Exodus 1 in the VDCC
Exodus 1 in the YALU
Exodus 1 in the YAPE
Exodus 1 in the YBVTP
Exodus 1 in the ZBP