Exodus 13 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin sọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ tèmi, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.” 3 Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí OLÚWA mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú. 4 Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. 5 Ní ìgbà tí OLÚWA mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí. 6 Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún OLÚWA. 7 Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín. 8 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí OLÚWA ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’ 9 Ṣíṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí àmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin OLÚWA ní ẹnu rẹ. Nítorí OLÚWA mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀. 10 Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún. 11 “Lẹ́yìn tí OLÚWA tí mú ọ wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ̀, 12 ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún OLÚWA. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti OLÚWA. 13 Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́-àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà. 14 “Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní OLÚWA fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú. 15 Ní ìgbà ti Farao ṣe orí kunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, OLÚWA pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rú ẹbọ sí OLÚWA láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’ 16 Èyí yóò sì jẹ́ àmì ni ọwọ́ yín àti àmì ní iwájú orí yín pé OLÚWA mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.” 17 Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.” 18 Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun. 19 Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.” 20 Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Sukkoti lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu ní etí aginjù. 21 OLÚWA sì ń lọ níwájú wọn, nínú ọ̀wọ̀n ìkùùkuu ní ọ̀sán láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú ọ̀wọ̀n iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru. 22 Ìkùùkuu náà kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀wọ̀n iná kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ni òru, ní iwájú àwọn ènìyàn náà.
In Other Versions
Exodus 13 in the ANGEFD
Exodus 13 in the ANTPNG2D
Exodus 13 in the AS21
Exodus 13 in the BAGH
Exodus 13 in the BBPNG
Exodus 13 in the BBT1E
Exodus 13 in the BDS
Exodus 13 in the BEV
Exodus 13 in the BHAD
Exodus 13 in the BIB
Exodus 13 in the BLPT
Exodus 13 in the BNT
Exodus 13 in the BNTABOOT
Exodus 13 in the BNTLV
Exodus 13 in the BOATCB
Exodus 13 in the BOATCB2
Exodus 13 in the BOBCV
Exodus 13 in the BOCNT
Exodus 13 in the BOECS
Exodus 13 in the BOGWICC
Exodus 13 in the BOHCB
Exodus 13 in the BOHCV
Exodus 13 in the BOHLNT
Exodus 13 in the BOHNTLTAL
Exodus 13 in the BOICB
Exodus 13 in the BOILNTAP
Exodus 13 in the BOITCV
Exodus 13 in the BOKCV
Exodus 13 in the BOKCV2
Exodus 13 in the BOKHWOG
Exodus 13 in the BOKSSV
Exodus 13 in the BOLCB
Exodus 13 in the BOLCB2
Exodus 13 in the BOMCV
Exodus 13 in the BONAV
Exodus 13 in the BONCB
Exodus 13 in the BONLT
Exodus 13 in the BONUT2
Exodus 13 in the BOPLNT
Exodus 13 in the BOSCB
Exodus 13 in the BOSNC
Exodus 13 in the BOTLNT
Exodus 13 in the BOVCB
Exodus 13 in the BPBB
Exodus 13 in the BPH
Exodus 13 in the BSB
Exodus 13 in the CCB
Exodus 13 in the CUV
Exodus 13 in the CUVS
Exodus 13 in the DBT
Exodus 13 in the DGDNT
Exodus 13 in the DHNT
Exodus 13 in the DNT
Exodus 13 in the ELBE
Exodus 13 in the EMTV
Exodus 13 in the ESV
Exodus 13 in the FBV
Exodus 13 in the FEB
Exodus 13 in the GGMNT
Exodus 13 in the GNT
Exodus 13 in the HARY
Exodus 13 in the HNT
Exodus 13 in the IRVA
Exodus 13 in the IRVB
Exodus 13 in the IRVG
Exodus 13 in the IRVH
Exodus 13 in the IRVK
Exodus 13 in the IRVM
Exodus 13 in the IRVM2
Exodus 13 in the IRVO
Exodus 13 in the IRVP
Exodus 13 in the IRVT
Exodus 13 in the IRVT2
Exodus 13 in the IRVU
Exodus 13 in the ISVN
Exodus 13 in the JSNT
Exodus 13 in the KAPI
Exodus 13 in the KBT1ETNIK
Exodus 13 in the KBV
Exodus 13 in the KJV
Exodus 13 in the KNFD
Exodus 13 in the LBA
Exodus 13 in the LBLA
Exodus 13 in the LNT
Exodus 13 in the LSV
Exodus 13 in the MAAL
Exodus 13 in the MBV
Exodus 13 in the MBV2
Exodus 13 in the MHNT
Exodus 13 in the MKNFD
Exodus 13 in the MNG
Exodus 13 in the MNT
Exodus 13 in the MNT2
Exodus 13 in the MRS1T
Exodus 13 in the NAA
Exodus 13 in the NASB
Exodus 13 in the NBLA
Exodus 13 in the NBS
Exodus 13 in the NBVTP
Exodus 13 in the NET2
Exodus 13 in the NIV11
Exodus 13 in the NNT
Exodus 13 in the NNT2
Exodus 13 in the NNT3
Exodus 13 in the PDDPT
Exodus 13 in the PFNT
Exodus 13 in the RMNT
Exodus 13 in the SBIAS
Exodus 13 in the SBIBS
Exodus 13 in the SBIBS2
Exodus 13 in the SBICS
Exodus 13 in the SBIDS
Exodus 13 in the SBIGS
Exodus 13 in the SBIHS
Exodus 13 in the SBIIS
Exodus 13 in the SBIIS2
Exodus 13 in the SBIIS3
Exodus 13 in the SBIKS
Exodus 13 in the SBIKS2
Exodus 13 in the SBIMS
Exodus 13 in the SBIOS
Exodus 13 in the SBIPS
Exodus 13 in the SBISS
Exodus 13 in the SBITS
Exodus 13 in the SBITS2
Exodus 13 in the SBITS3
Exodus 13 in the SBITS4
Exodus 13 in the SBIUS
Exodus 13 in the SBIVS
Exodus 13 in the SBT
Exodus 13 in the SBT1E
Exodus 13 in the SCHL
Exodus 13 in the SNT
Exodus 13 in the SUSU
Exodus 13 in the SUSU2
Exodus 13 in the SYNO
Exodus 13 in the TBIAOTANT
Exodus 13 in the TBT1E
Exodus 13 in the TBT1E2
Exodus 13 in the TFTIP
Exodus 13 in the TFTU
Exodus 13 in the TGNTATF3T
Exodus 13 in the THAI
Exodus 13 in the TNFD
Exodus 13 in the TNT
Exodus 13 in the TNTIK
Exodus 13 in the TNTIL
Exodus 13 in the TNTIN
Exodus 13 in the TNTIP
Exodus 13 in the TNTIZ
Exodus 13 in the TOMA
Exodus 13 in the TTENT
Exodus 13 in the UBG
Exodus 13 in the UGV
Exodus 13 in the UGV2
Exodus 13 in the UGV3
Exodus 13 in the VBL
Exodus 13 in the VDCC
Exodus 13 in the YALU
Exodus 13 in the YAPE
Exodus 13 in the YBVTP
Exodus 13 in the ZBP