Exodus 20 (BOYCB)
1 Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé, 2 “Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá. 3 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi. 4 Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 5 Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi OLÚWA Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi. 6 Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́. 7 Ẹ má ṣe ṣi orúkọ OLÚWA Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi. 8 Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́. 9 Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ, 10 ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi OLÚWA Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ. 11 Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni OLÚWA dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni OLÚWA ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́. 12 Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ. 13 Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn. 14 Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà. 15 Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. 16 Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ. 17 Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.” 18 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. 19 Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnra rẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.” 20 Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.” 21 Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà. 22 OLÚWA sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli, ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnra yín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. 23 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín. 24 “ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀. 25 Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lórí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́. 26 Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’
In Other Versions
Exodus 20 in the ANGEFD
Exodus 20 in the ANTPNG2D
Exodus 20 in the AS21
Exodus 20 in the BAGH
Exodus 20 in the BBPNG
Exodus 20 in the BBT1E
Exodus 20 in the BDS
Exodus 20 in the BEV
Exodus 20 in the BHAD
Exodus 20 in the BIB
Exodus 20 in the BLPT
Exodus 20 in the BNT
Exodus 20 in the BNTABOOT
Exodus 20 in the BNTLV
Exodus 20 in the BOATCB
Exodus 20 in the BOATCB2
Exodus 20 in the BOBCV
Exodus 20 in the BOCNT
Exodus 20 in the BOECS
Exodus 20 in the BOGWICC
Exodus 20 in the BOHCB
Exodus 20 in the BOHCV
Exodus 20 in the BOHLNT
Exodus 20 in the BOHNTLTAL
Exodus 20 in the BOICB
Exodus 20 in the BOILNTAP
Exodus 20 in the BOITCV
Exodus 20 in the BOKCV
Exodus 20 in the BOKCV2
Exodus 20 in the BOKHWOG
Exodus 20 in the BOKSSV
Exodus 20 in the BOLCB
Exodus 20 in the BOLCB2
Exodus 20 in the BOMCV
Exodus 20 in the BONAV
Exodus 20 in the BONCB
Exodus 20 in the BONLT
Exodus 20 in the BONUT2
Exodus 20 in the BOPLNT
Exodus 20 in the BOSCB
Exodus 20 in the BOSNC
Exodus 20 in the BOTLNT
Exodus 20 in the BOVCB
Exodus 20 in the BPBB
Exodus 20 in the BPH
Exodus 20 in the BSB
Exodus 20 in the CCB
Exodus 20 in the CUV
Exodus 20 in the CUVS
Exodus 20 in the DBT
Exodus 20 in the DGDNT
Exodus 20 in the DHNT
Exodus 20 in the DNT
Exodus 20 in the ELBE
Exodus 20 in the EMTV
Exodus 20 in the ESV
Exodus 20 in the FBV
Exodus 20 in the FEB
Exodus 20 in the GGMNT
Exodus 20 in the GNT
Exodus 20 in the HARY
Exodus 20 in the HNT
Exodus 20 in the IRVA
Exodus 20 in the IRVB
Exodus 20 in the IRVG
Exodus 20 in the IRVH
Exodus 20 in the IRVK
Exodus 20 in the IRVM
Exodus 20 in the IRVM2
Exodus 20 in the IRVO
Exodus 20 in the IRVP
Exodus 20 in the IRVT
Exodus 20 in the IRVT2
Exodus 20 in the IRVU
Exodus 20 in the ISVN
Exodus 20 in the JSNT
Exodus 20 in the KAPI
Exodus 20 in the KBT1ETNIK
Exodus 20 in the KBV
Exodus 20 in the KJV
Exodus 20 in the KNFD
Exodus 20 in the LBA
Exodus 20 in the LBLA
Exodus 20 in the LNT
Exodus 20 in the LSV
Exodus 20 in the MAAL
Exodus 20 in the MBV
Exodus 20 in the MBV2
Exodus 20 in the MHNT
Exodus 20 in the MKNFD
Exodus 20 in the MNG
Exodus 20 in the MNT
Exodus 20 in the MNT2
Exodus 20 in the MRS1T
Exodus 20 in the NAA
Exodus 20 in the NASB
Exodus 20 in the NBLA
Exodus 20 in the NBS
Exodus 20 in the NBVTP
Exodus 20 in the NET2
Exodus 20 in the NIV11
Exodus 20 in the NNT
Exodus 20 in the NNT2
Exodus 20 in the NNT3
Exodus 20 in the PDDPT
Exodus 20 in the PFNT
Exodus 20 in the RMNT
Exodus 20 in the SBIAS
Exodus 20 in the SBIBS
Exodus 20 in the SBIBS2
Exodus 20 in the SBICS
Exodus 20 in the SBIDS
Exodus 20 in the SBIGS
Exodus 20 in the SBIHS
Exodus 20 in the SBIIS
Exodus 20 in the SBIIS2
Exodus 20 in the SBIIS3
Exodus 20 in the SBIKS
Exodus 20 in the SBIKS2
Exodus 20 in the SBIMS
Exodus 20 in the SBIOS
Exodus 20 in the SBIPS
Exodus 20 in the SBISS
Exodus 20 in the SBITS
Exodus 20 in the SBITS2
Exodus 20 in the SBITS3
Exodus 20 in the SBITS4
Exodus 20 in the SBIUS
Exodus 20 in the SBIVS
Exodus 20 in the SBT
Exodus 20 in the SBT1E
Exodus 20 in the SCHL
Exodus 20 in the SNT
Exodus 20 in the SUSU
Exodus 20 in the SUSU2
Exodus 20 in the SYNO
Exodus 20 in the TBIAOTANT
Exodus 20 in the TBT1E
Exodus 20 in the TBT1E2
Exodus 20 in the TFTIP
Exodus 20 in the TFTU
Exodus 20 in the TGNTATF3T
Exodus 20 in the THAI
Exodus 20 in the TNFD
Exodus 20 in the TNT
Exodus 20 in the TNTIK
Exodus 20 in the TNTIL
Exodus 20 in the TNTIN
Exodus 20 in the TNTIP
Exodus 20 in the TNTIZ
Exodus 20 in the TOMA
Exodus 20 in the TTENT
Exodus 20 in the UBG
Exodus 20 in the UGV
Exodus 20 in the UGV2
Exodus 20 in the UGV3
Exodus 20 in the VBL
Exodus 20 in the VDCC
Exodus 20 in the YALU
Exodus 20 in the YAPE
Exodus 20 in the YBVTP
Exodus 20 in the ZBP