Exodus 24 (BOYCB)

1 Ní ìgbà náà ni OLÚWA sọ fún Mose pé, “Gòkè tọ OLÚWA wá, ìwọ àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré. 2 Ṣùgbọ́n Mose nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ OLÚWA; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.” 3 Nígbà ti Mose lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin OLÚWA, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti OLÚWA wí ni àwa yóò ṣe.” 4 Nígbà náà ni Mose kọ gbogbo ohun tí OLÚWA sọ sílẹ̀.Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó ṣe ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá. 5 Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si OLÚWA. 6 Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ. 7 Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí OLÚWA wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.” 8 Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí OLÚWA ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.” 9 Mose àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli gòkè lọ. 10 Wọ́n sì rí Ọlọ́run Israẹli. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta safire ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ nigínnigín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnra rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbàgbà Israẹli wọ̀nyí; wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. 12 OLÚWA sì sọ fún Mose pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhìn-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní wàláà òkúta pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.” 13 Nígbà náà ni Mose jáde lọ pẹ̀lú Joṣua arákùnrin rẹ̀. Mose lọ sí orí òkè Ọlọ́run. 14 Ó sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsi i, Aaroni àti Huri ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnìkan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.” 15 Nígbà tí Mose gun orí òkè lọ, ìkùùkuu bo orí òkè náà. 16 Ògo OLÚWA sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni OLÚWA kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá. 17 Ni ojú àwọn ọmọ Israẹli ògo OLÚWA náà dàbí iná ajónirun ni orí òkè. 18 Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

In Other Versions

Exodus 24 in the ANGEFD

Exodus 24 in the ANTPNG2D

Exodus 24 in the AS21

Exodus 24 in the BAGH

Exodus 24 in the BBPNG

Exodus 24 in the BBT1E

Exodus 24 in the BDS

Exodus 24 in the BEV

Exodus 24 in the BHAD

Exodus 24 in the BIB

Exodus 24 in the BLPT

Exodus 24 in the BNT

Exodus 24 in the BNTABOOT

Exodus 24 in the BNTLV

Exodus 24 in the BOATCB

Exodus 24 in the BOATCB2

Exodus 24 in the BOBCV

Exodus 24 in the BOCNT

Exodus 24 in the BOECS

Exodus 24 in the BOGWICC

Exodus 24 in the BOHCB

Exodus 24 in the BOHCV

Exodus 24 in the BOHLNT

Exodus 24 in the BOHNTLTAL

Exodus 24 in the BOICB

Exodus 24 in the BOILNTAP

Exodus 24 in the BOITCV

Exodus 24 in the BOKCV

Exodus 24 in the BOKCV2

Exodus 24 in the BOKHWOG

Exodus 24 in the BOKSSV

Exodus 24 in the BOLCB

Exodus 24 in the BOLCB2

Exodus 24 in the BOMCV

Exodus 24 in the BONAV

Exodus 24 in the BONCB

Exodus 24 in the BONLT

Exodus 24 in the BONUT2

Exodus 24 in the BOPLNT

Exodus 24 in the BOSCB

Exodus 24 in the BOSNC

Exodus 24 in the BOTLNT

Exodus 24 in the BOVCB

Exodus 24 in the BPBB

Exodus 24 in the BPH

Exodus 24 in the BSB

Exodus 24 in the CCB

Exodus 24 in the CUV

Exodus 24 in the CUVS

Exodus 24 in the DBT

Exodus 24 in the DGDNT

Exodus 24 in the DHNT

Exodus 24 in the DNT

Exodus 24 in the ELBE

Exodus 24 in the EMTV

Exodus 24 in the ESV

Exodus 24 in the FBV

Exodus 24 in the FEB

Exodus 24 in the GGMNT

Exodus 24 in the GNT

Exodus 24 in the HARY

Exodus 24 in the HNT

Exodus 24 in the IRVA

Exodus 24 in the IRVB

Exodus 24 in the IRVG

Exodus 24 in the IRVH

Exodus 24 in the IRVK

Exodus 24 in the IRVM

Exodus 24 in the IRVM2

Exodus 24 in the IRVO

Exodus 24 in the IRVP

Exodus 24 in the IRVT

Exodus 24 in the IRVT2

Exodus 24 in the IRVU

Exodus 24 in the ISVN

Exodus 24 in the JSNT

Exodus 24 in the KAPI

Exodus 24 in the KBT1ETNIK

Exodus 24 in the KBV

Exodus 24 in the KJV

Exodus 24 in the KNFD

Exodus 24 in the LBA

Exodus 24 in the LBLA

Exodus 24 in the LNT

Exodus 24 in the LSV

Exodus 24 in the MAAL

Exodus 24 in the MBV

Exodus 24 in the MBV2

Exodus 24 in the MHNT

Exodus 24 in the MKNFD

Exodus 24 in the MNG

Exodus 24 in the MNT

Exodus 24 in the MNT2

Exodus 24 in the MRS1T

Exodus 24 in the NAA

Exodus 24 in the NASB

Exodus 24 in the NBLA

Exodus 24 in the NBS

Exodus 24 in the NBVTP

Exodus 24 in the NET2

Exodus 24 in the NIV11

Exodus 24 in the NNT

Exodus 24 in the NNT2

Exodus 24 in the NNT3

Exodus 24 in the PDDPT

Exodus 24 in the PFNT

Exodus 24 in the RMNT

Exodus 24 in the SBIAS

Exodus 24 in the SBIBS

Exodus 24 in the SBIBS2

Exodus 24 in the SBICS

Exodus 24 in the SBIDS

Exodus 24 in the SBIGS

Exodus 24 in the SBIHS

Exodus 24 in the SBIIS

Exodus 24 in the SBIIS2

Exodus 24 in the SBIIS3

Exodus 24 in the SBIKS

Exodus 24 in the SBIKS2

Exodus 24 in the SBIMS

Exodus 24 in the SBIOS

Exodus 24 in the SBIPS

Exodus 24 in the SBISS

Exodus 24 in the SBITS

Exodus 24 in the SBITS2

Exodus 24 in the SBITS3

Exodus 24 in the SBITS4

Exodus 24 in the SBIUS

Exodus 24 in the SBIVS

Exodus 24 in the SBT

Exodus 24 in the SBT1E

Exodus 24 in the SCHL

Exodus 24 in the SNT

Exodus 24 in the SUSU

Exodus 24 in the SUSU2

Exodus 24 in the SYNO

Exodus 24 in the TBIAOTANT

Exodus 24 in the TBT1E

Exodus 24 in the TBT1E2

Exodus 24 in the TFTIP

Exodus 24 in the TFTU

Exodus 24 in the TGNTATF3T

Exodus 24 in the THAI

Exodus 24 in the TNFD

Exodus 24 in the TNT

Exodus 24 in the TNTIK

Exodus 24 in the TNTIL

Exodus 24 in the TNTIN

Exodus 24 in the TNTIP

Exodus 24 in the TNTIZ

Exodus 24 in the TOMA

Exodus 24 in the TTENT

Exodus 24 in the UBG

Exodus 24 in the UGV

Exodus 24 in the UGV2

Exodus 24 in the UGV3

Exodus 24 in the VBL

Exodus 24 in the VDCC

Exodus 24 in the YALU

Exodus 24 in the YAPE

Exodus 24 in the YBVTP

Exodus 24 in the ZBP