Ezekiel 10 (BOYCB)
1 Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta safire nínú òfúrufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́. 2 OLÚWA sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárín àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrín kérúbù, kí o sì fọ́n sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lójú mi. 3 Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹmpili nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùùkuu sì bo inú àgbàlá. 4 Ògo OLÚWA sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo OLÚWA. 5 A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà ní ìta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè bá ń sọ̀rọ̀. 6 Nígbà tí OLÚWA pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, láàrín àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà. 7 Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ sí ibi iná tó wà láàrín kérúbù yòókù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbà á, ó sì jáde lọ. 8 (Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí.) 9 Nígbà tí mo sì wò, kíyèsí i, àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; ìrí àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àwọ̀ òkúta berili. 10 Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn; ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn. 11 Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojúkọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ sí ibi tí orí dojúkọ láì yà. 12 Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ wọn àti ìyẹ́ wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́ kún fún ojú yíkákiri kẹ̀kẹ́, tí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní. 13 Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ àjà.” 14 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì. 15 A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kebari. 16 Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. 17 Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn. 18 Ògo OLÚWA kúrò níbi ìloro tẹmpili, ó sì dúró sórí àwọn kérúbù. 19 Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé OLÚWA, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lórí wọn. 20 Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Israẹli létí odò Kebari, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n. 21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà. 22 Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò Kebari. Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà.
In Other Versions
Ezekiel 10 in the ANGEFD
Ezekiel 10 in the ANTPNG2D
Ezekiel 10 in the AS21
Ezekiel 10 in the BAGH
Ezekiel 10 in the BBPNG
Ezekiel 10 in the BBT1E
Ezekiel 10 in the BDS
Ezekiel 10 in the BEV
Ezekiel 10 in the BHAD
Ezekiel 10 in the BIB
Ezekiel 10 in the BLPT
Ezekiel 10 in the BNT
Ezekiel 10 in the BNTABOOT
Ezekiel 10 in the BNTLV
Ezekiel 10 in the BOATCB
Ezekiel 10 in the BOATCB2
Ezekiel 10 in the BOBCV
Ezekiel 10 in the BOCNT
Ezekiel 10 in the BOECS
Ezekiel 10 in the BOGWICC
Ezekiel 10 in the BOHCB
Ezekiel 10 in the BOHCV
Ezekiel 10 in the BOHLNT
Ezekiel 10 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 10 in the BOICB
Ezekiel 10 in the BOILNTAP
Ezekiel 10 in the BOITCV
Ezekiel 10 in the BOKCV
Ezekiel 10 in the BOKCV2
Ezekiel 10 in the BOKHWOG
Ezekiel 10 in the BOKSSV
Ezekiel 10 in the BOLCB
Ezekiel 10 in the BOLCB2
Ezekiel 10 in the BOMCV
Ezekiel 10 in the BONAV
Ezekiel 10 in the BONCB
Ezekiel 10 in the BONLT
Ezekiel 10 in the BONUT2
Ezekiel 10 in the BOPLNT
Ezekiel 10 in the BOSCB
Ezekiel 10 in the BOSNC
Ezekiel 10 in the BOTLNT
Ezekiel 10 in the BOVCB
Ezekiel 10 in the BPBB
Ezekiel 10 in the BPH
Ezekiel 10 in the BSB
Ezekiel 10 in the CCB
Ezekiel 10 in the CUV
Ezekiel 10 in the CUVS
Ezekiel 10 in the DBT
Ezekiel 10 in the DGDNT
Ezekiel 10 in the DHNT
Ezekiel 10 in the DNT
Ezekiel 10 in the ELBE
Ezekiel 10 in the EMTV
Ezekiel 10 in the ESV
Ezekiel 10 in the FBV
Ezekiel 10 in the FEB
Ezekiel 10 in the GGMNT
Ezekiel 10 in the GNT
Ezekiel 10 in the HARY
Ezekiel 10 in the HNT
Ezekiel 10 in the IRVA
Ezekiel 10 in the IRVB
Ezekiel 10 in the IRVG
Ezekiel 10 in the IRVH
Ezekiel 10 in the IRVK
Ezekiel 10 in the IRVM
Ezekiel 10 in the IRVM2
Ezekiel 10 in the IRVO
Ezekiel 10 in the IRVP
Ezekiel 10 in the IRVT
Ezekiel 10 in the IRVT2
Ezekiel 10 in the IRVU
Ezekiel 10 in the ISVN
Ezekiel 10 in the JSNT
Ezekiel 10 in the KAPI
Ezekiel 10 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 10 in the KBV
Ezekiel 10 in the KJV
Ezekiel 10 in the KNFD
Ezekiel 10 in the LBA
Ezekiel 10 in the LBLA
Ezekiel 10 in the LNT
Ezekiel 10 in the LSV
Ezekiel 10 in the MAAL
Ezekiel 10 in the MBV
Ezekiel 10 in the MBV2
Ezekiel 10 in the MHNT
Ezekiel 10 in the MKNFD
Ezekiel 10 in the MNG
Ezekiel 10 in the MNT
Ezekiel 10 in the MNT2
Ezekiel 10 in the MRS1T
Ezekiel 10 in the NAA
Ezekiel 10 in the NASB
Ezekiel 10 in the NBLA
Ezekiel 10 in the NBS
Ezekiel 10 in the NBVTP
Ezekiel 10 in the NET2
Ezekiel 10 in the NIV11
Ezekiel 10 in the NNT
Ezekiel 10 in the NNT2
Ezekiel 10 in the NNT3
Ezekiel 10 in the PDDPT
Ezekiel 10 in the PFNT
Ezekiel 10 in the RMNT
Ezekiel 10 in the SBIAS
Ezekiel 10 in the SBIBS
Ezekiel 10 in the SBIBS2
Ezekiel 10 in the SBICS
Ezekiel 10 in the SBIDS
Ezekiel 10 in the SBIGS
Ezekiel 10 in the SBIHS
Ezekiel 10 in the SBIIS
Ezekiel 10 in the SBIIS2
Ezekiel 10 in the SBIIS3
Ezekiel 10 in the SBIKS
Ezekiel 10 in the SBIKS2
Ezekiel 10 in the SBIMS
Ezekiel 10 in the SBIOS
Ezekiel 10 in the SBIPS
Ezekiel 10 in the SBISS
Ezekiel 10 in the SBITS
Ezekiel 10 in the SBITS2
Ezekiel 10 in the SBITS3
Ezekiel 10 in the SBITS4
Ezekiel 10 in the SBIUS
Ezekiel 10 in the SBIVS
Ezekiel 10 in the SBT
Ezekiel 10 in the SBT1E
Ezekiel 10 in the SCHL
Ezekiel 10 in the SNT
Ezekiel 10 in the SUSU
Ezekiel 10 in the SUSU2
Ezekiel 10 in the SYNO
Ezekiel 10 in the TBIAOTANT
Ezekiel 10 in the TBT1E
Ezekiel 10 in the TBT1E2
Ezekiel 10 in the TFTIP
Ezekiel 10 in the TFTU
Ezekiel 10 in the TGNTATF3T
Ezekiel 10 in the THAI
Ezekiel 10 in the TNFD
Ezekiel 10 in the TNT
Ezekiel 10 in the TNTIK
Ezekiel 10 in the TNTIL
Ezekiel 10 in the TNTIN
Ezekiel 10 in the TNTIP
Ezekiel 10 in the TNTIZ
Ezekiel 10 in the TOMA
Ezekiel 10 in the TTENT
Ezekiel 10 in the UBG
Ezekiel 10 in the UGV
Ezekiel 10 in the UGV2
Ezekiel 10 in the UGV3
Ezekiel 10 in the VBL
Ezekiel 10 in the VDCC
Ezekiel 10 in the YALU
Ezekiel 10 in the YAPE
Ezekiel 10 in the YBVTP
Ezekiel 10 in the ZBP