Ezekiel 11 (BOYCB)
1 Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu-ọ̀nà ilé OLÚWA èyí tó dojúkọ ìlà-oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wá, mo rí Jaaṣaniah ọmọ Assuri àti Pelatiah ọmọ Benaiah, tí wọ́n jẹ́ ìjòyè àwọn ènìyàn. 2 OLÚWA sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gbé ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú. 3 Wọ́n ní, ‘Kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’. 4 Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀.” 5 Ẹ̀mí OLÚWA sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni OLÚWA wí, ohun tí ẹ ń sọ nìyìí, ilé Israẹli, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín. 6 Ẹ̀yin ti sọ òkú yín di púpọ̀ nínú ìlú yìí, òkú sì ti kún gbogbo ìgboro rẹ̀. 7 “Torí náà, báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí, àwọn òkú tí ẹ fọn sílẹ̀ sí àárín yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n èmi yóò le yín jáde níbẹ̀. 8 Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA Olódùmarè wí. 9 Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí. 10 Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA. 11 Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. 12 Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.” 13 Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pelatiah ọmọ Benaiah kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Háà! OLÚWA Olódùmarè! Ṣé ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli run pátápátá ni?” 14 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé, 15 “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Israẹli pátápátá, ni àwọn ará Jerusalẹmu ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí OLÚWA, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’ 16 “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, èmi yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’ 17 “Nítorí náà, wí pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí, Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli padà.’ 18 “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà rẹ̀ kúrò. 19 Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn, Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran. 20 Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 21 Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sí orí wọn bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA Olódùmarè wí.” 22 Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lókè orí wọn. 23 Ògo OLÚWA sì gòkè lọ kúrò láàrín ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà-oòrùn ìlú náà. 24 Lẹ́yìn náà, Ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi wá sí Kaldea lójú ìran, nípa ti Ẹ̀mí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ àwọn ti ìgbèkùn.Bẹ́ẹ̀ ni ìran tí mo rí lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, 25 mo sì sọ gbogbo ohun tí OLÚWA fihàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.
In Other Versions
Ezekiel 11 in the ANGEFD
Ezekiel 11 in the ANTPNG2D
Ezekiel 11 in the AS21
Ezekiel 11 in the BAGH
Ezekiel 11 in the BBPNG
Ezekiel 11 in the BBT1E
Ezekiel 11 in the BDS
Ezekiel 11 in the BEV
Ezekiel 11 in the BHAD
Ezekiel 11 in the BIB
Ezekiel 11 in the BLPT
Ezekiel 11 in the BNT
Ezekiel 11 in the BNTABOOT
Ezekiel 11 in the BNTLV
Ezekiel 11 in the BOATCB
Ezekiel 11 in the BOATCB2
Ezekiel 11 in the BOBCV
Ezekiel 11 in the BOCNT
Ezekiel 11 in the BOECS
Ezekiel 11 in the BOGWICC
Ezekiel 11 in the BOHCB
Ezekiel 11 in the BOHCV
Ezekiel 11 in the BOHLNT
Ezekiel 11 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 11 in the BOICB
Ezekiel 11 in the BOILNTAP
Ezekiel 11 in the BOITCV
Ezekiel 11 in the BOKCV
Ezekiel 11 in the BOKCV2
Ezekiel 11 in the BOKHWOG
Ezekiel 11 in the BOKSSV
Ezekiel 11 in the BOLCB
Ezekiel 11 in the BOLCB2
Ezekiel 11 in the BOMCV
Ezekiel 11 in the BONAV
Ezekiel 11 in the BONCB
Ezekiel 11 in the BONLT
Ezekiel 11 in the BONUT2
Ezekiel 11 in the BOPLNT
Ezekiel 11 in the BOSCB
Ezekiel 11 in the BOSNC
Ezekiel 11 in the BOTLNT
Ezekiel 11 in the BOVCB
Ezekiel 11 in the BPBB
Ezekiel 11 in the BPH
Ezekiel 11 in the BSB
Ezekiel 11 in the CCB
Ezekiel 11 in the CUV
Ezekiel 11 in the CUVS
Ezekiel 11 in the DBT
Ezekiel 11 in the DGDNT
Ezekiel 11 in the DHNT
Ezekiel 11 in the DNT
Ezekiel 11 in the ELBE
Ezekiel 11 in the EMTV
Ezekiel 11 in the ESV
Ezekiel 11 in the FBV
Ezekiel 11 in the FEB
Ezekiel 11 in the GGMNT
Ezekiel 11 in the GNT
Ezekiel 11 in the HARY
Ezekiel 11 in the HNT
Ezekiel 11 in the IRVA
Ezekiel 11 in the IRVB
Ezekiel 11 in the IRVG
Ezekiel 11 in the IRVH
Ezekiel 11 in the IRVK
Ezekiel 11 in the IRVM
Ezekiel 11 in the IRVM2
Ezekiel 11 in the IRVO
Ezekiel 11 in the IRVP
Ezekiel 11 in the IRVT
Ezekiel 11 in the IRVT2
Ezekiel 11 in the IRVU
Ezekiel 11 in the ISVN
Ezekiel 11 in the JSNT
Ezekiel 11 in the KAPI
Ezekiel 11 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 11 in the KBV
Ezekiel 11 in the KJV
Ezekiel 11 in the KNFD
Ezekiel 11 in the LBA
Ezekiel 11 in the LBLA
Ezekiel 11 in the LNT
Ezekiel 11 in the LSV
Ezekiel 11 in the MAAL
Ezekiel 11 in the MBV
Ezekiel 11 in the MBV2
Ezekiel 11 in the MHNT
Ezekiel 11 in the MKNFD
Ezekiel 11 in the MNG
Ezekiel 11 in the MNT
Ezekiel 11 in the MNT2
Ezekiel 11 in the MRS1T
Ezekiel 11 in the NAA
Ezekiel 11 in the NASB
Ezekiel 11 in the NBLA
Ezekiel 11 in the NBS
Ezekiel 11 in the NBVTP
Ezekiel 11 in the NET2
Ezekiel 11 in the NIV11
Ezekiel 11 in the NNT
Ezekiel 11 in the NNT2
Ezekiel 11 in the NNT3
Ezekiel 11 in the PDDPT
Ezekiel 11 in the PFNT
Ezekiel 11 in the RMNT
Ezekiel 11 in the SBIAS
Ezekiel 11 in the SBIBS
Ezekiel 11 in the SBIBS2
Ezekiel 11 in the SBICS
Ezekiel 11 in the SBIDS
Ezekiel 11 in the SBIGS
Ezekiel 11 in the SBIHS
Ezekiel 11 in the SBIIS
Ezekiel 11 in the SBIIS2
Ezekiel 11 in the SBIIS3
Ezekiel 11 in the SBIKS
Ezekiel 11 in the SBIKS2
Ezekiel 11 in the SBIMS
Ezekiel 11 in the SBIOS
Ezekiel 11 in the SBIPS
Ezekiel 11 in the SBISS
Ezekiel 11 in the SBITS
Ezekiel 11 in the SBITS2
Ezekiel 11 in the SBITS3
Ezekiel 11 in the SBITS4
Ezekiel 11 in the SBIUS
Ezekiel 11 in the SBIVS
Ezekiel 11 in the SBT
Ezekiel 11 in the SBT1E
Ezekiel 11 in the SCHL
Ezekiel 11 in the SNT
Ezekiel 11 in the SUSU
Ezekiel 11 in the SUSU2
Ezekiel 11 in the SYNO
Ezekiel 11 in the TBIAOTANT
Ezekiel 11 in the TBT1E
Ezekiel 11 in the TBT1E2
Ezekiel 11 in the TFTIP
Ezekiel 11 in the TFTU
Ezekiel 11 in the TGNTATF3T
Ezekiel 11 in the THAI
Ezekiel 11 in the TNFD
Ezekiel 11 in the TNT
Ezekiel 11 in the TNTIK
Ezekiel 11 in the TNTIL
Ezekiel 11 in the TNTIN
Ezekiel 11 in the TNTIP
Ezekiel 11 in the TNTIZ
Ezekiel 11 in the TOMA
Ezekiel 11 in the TTENT
Ezekiel 11 in the UBG
Ezekiel 11 in the UGV
Ezekiel 11 in the UGV2
Ezekiel 11 in the UGV3
Ezekiel 11 in the VBL
Ezekiel 11 in the VDCC
Ezekiel 11 in the YALU
Ezekiel 11 in the YAPE
Ezekiel 11 in the YBVTP
Ezekiel 11 in the ZBP