Ezekiel 8 (BOYCB)

1 Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà ọdún kẹfà bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Juda níwájú mi, ọwọ́ OLÚWA Olódùmarè bà lé mi níbẹ̀. 2 Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí ó jọ ènìyàn. Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà. 3 Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi ní irun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jerusalẹmu, ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère owú tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi. 4 Sì kíyèsi i, ògo Ọlọ́run Israẹli wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀. 5 Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu-ọ̀nà ibi pẹpẹ. 6 Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra ńlá tí ilé Israẹli ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù èyí lọ.” 7 Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. 8 Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan. 9 Ó sì wí fún mi pé, “Wọlé kí ìwọ kí ó rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.” 10 Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n yà sára ògiri. 11 Níwájú wọn ni àádọ́rin ọkùnrin tó jẹ́ àgbàgbà ilé Israẹli dúró sí, Jaaṣaniah ọmọ Ṣafani sì dúró sí àárín wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde. 12 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbàgbà ilé Israẹli ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘OLÚWA kò rí wa; OLÚWA ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ” 13 Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.” 14 Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé OLÚWA tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu-ọ̀nà ilé OLÚWA tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Tamusi. 15 Ó sọ fún mi pé, “Ṣé ìwọ rí báyìí, ọmọ ènìyàn? Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ.” 16 Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé OLÚWA, ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili OLÚWA, láàrín ìloro àti pẹpẹ, ni ìwọ̀n ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) wà, tí wọ́n kẹ́yìn sí tẹmpili OLÚWA tí wọn sì kọjú sí ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún oòrùn ní apá ìlà-oòrùn. 17 Ó sì wí fún mi, “Ṣé ìwọ ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékeré ni fún ilé Juda láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé o tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn ṣe n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn. 18 Nítorí náà, èmi yóò fi ìbínú bá wọn wí; èmi kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ní fojú àánú wò wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, èmi kò ní fetí sí wọn.”

In Other Versions

Ezekiel 8 in the ANGEFD

Ezekiel 8 in the ANTPNG2D

Ezekiel 8 in the AS21

Ezekiel 8 in the BAGH

Ezekiel 8 in the BBPNG

Ezekiel 8 in the BBT1E

Ezekiel 8 in the BDS

Ezekiel 8 in the BEV

Ezekiel 8 in the BHAD

Ezekiel 8 in the BIB

Ezekiel 8 in the BLPT

Ezekiel 8 in the BNT

Ezekiel 8 in the BNTABOOT

Ezekiel 8 in the BNTLV

Ezekiel 8 in the BOATCB

Ezekiel 8 in the BOATCB2

Ezekiel 8 in the BOBCV

Ezekiel 8 in the BOCNT

Ezekiel 8 in the BOECS

Ezekiel 8 in the BOGWICC

Ezekiel 8 in the BOHCB

Ezekiel 8 in the BOHCV

Ezekiel 8 in the BOHLNT

Ezekiel 8 in the BOHNTLTAL

Ezekiel 8 in the BOICB

Ezekiel 8 in the BOILNTAP

Ezekiel 8 in the BOITCV

Ezekiel 8 in the BOKCV

Ezekiel 8 in the BOKCV2

Ezekiel 8 in the BOKHWOG

Ezekiel 8 in the BOKSSV

Ezekiel 8 in the BOLCB

Ezekiel 8 in the BOLCB2

Ezekiel 8 in the BOMCV

Ezekiel 8 in the BONAV

Ezekiel 8 in the BONCB

Ezekiel 8 in the BONLT

Ezekiel 8 in the BONUT2

Ezekiel 8 in the BOPLNT

Ezekiel 8 in the BOSCB

Ezekiel 8 in the BOSNC

Ezekiel 8 in the BOTLNT

Ezekiel 8 in the BOVCB

Ezekiel 8 in the BPBB

Ezekiel 8 in the BPH

Ezekiel 8 in the BSB

Ezekiel 8 in the CCB

Ezekiel 8 in the CUV

Ezekiel 8 in the CUVS

Ezekiel 8 in the DBT

Ezekiel 8 in the DGDNT

Ezekiel 8 in the DHNT

Ezekiel 8 in the DNT

Ezekiel 8 in the ELBE

Ezekiel 8 in the EMTV

Ezekiel 8 in the ESV

Ezekiel 8 in the FBV

Ezekiel 8 in the FEB

Ezekiel 8 in the GGMNT

Ezekiel 8 in the GNT

Ezekiel 8 in the HARY

Ezekiel 8 in the HNT

Ezekiel 8 in the IRVA

Ezekiel 8 in the IRVB

Ezekiel 8 in the IRVG

Ezekiel 8 in the IRVH

Ezekiel 8 in the IRVK

Ezekiel 8 in the IRVM

Ezekiel 8 in the IRVM2

Ezekiel 8 in the IRVO

Ezekiel 8 in the IRVP

Ezekiel 8 in the IRVT

Ezekiel 8 in the IRVT2

Ezekiel 8 in the IRVU

Ezekiel 8 in the ISVN

Ezekiel 8 in the JSNT

Ezekiel 8 in the KAPI

Ezekiel 8 in the KBT1ETNIK

Ezekiel 8 in the KBV

Ezekiel 8 in the KJV

Ezekiel 8 in the KNFD

Ezekiel 8 in the LBA

Ezekiel 8 in the LBLA

Ezekiel 8 in the LNT

Ezekiel 8 in the LSV

Ezekiel 8 in the MAAL

Ezekiel 8 in the MBV

Ezekiel 8 in the MBV2

Ezekiel 8 in the MHNT

Ezekiel 8 in the MKNFD

Ezekiel 8 in the MNG

Ezekiel 8 in the MNT

Ezekiel 8 in the MNT2

Ezekiel 8 in the MRS1T

Ezekiel 8 in the NAA

Ezekiel 8 in the NASB

Ezekiel 8 in the NBLA

Ezekiel 8 in the NBS

Ezekiel 8 in the NBVTP

Ezekiel 8 in the NET2

Ezekiel 8 in the NIV11

Ezekiel 8 in the NNT

Ezekiel 8 in the NNT2

Ezekiel 8 in the NNT3

Ezekiel 8 in the PDDPT

Ezekiel 8 in the PFNT

Ezekiel 8 in the RMNT

Ezekiel 8 in the SBIAS

Ezekiel 8 in the SBIBS

Ezekiel 8 in the SBIBS2

Ezekiel 8 in the SBICS

Ezekiel 8 in the SBIDS

Ezekiel 8 in the SBIGS

Ezekiel 8 in the SBIHS

Ezekiel 8 in the SBIIS

Ezekiel 8 in the SBIIS2

Ezekiel 8 in the SBIIS3

Ezekiel 8 in the SBIKS

Ezekiel 8 in the SBIKS2

Ezekiel 8 in the SBIMS

Ezekiel 8 in the SBIOS

Ezekiel 8 in the SBIPS

Ezekiel 8 in the SBISS

Ezekiel 8 in the SBITS

Ezekiel 8 in the SBITS2

Ezekiel 8 in the SBITS3

Ezekiel 8 in the SBITS4

Ezekiel 8 in the SBIUS

Ezekiel 8 in the SBIVS

Ezekiel 8 in the SBT

Ezekiel 8 in the SBT1E

Ezekiel 8 in the SCHL

Ezekiel 8 in the SNT

Ezekiel 8 in the SUSU

Ezekiel 8 in the SUSU2

Ezekiel 8 in the SYNO

Ezekiel 8 in the TBIAOTANT

Ezekiel 8 in the TBT1E

Ezekiel 8 in the TBT1E2

Ezekiel 8 in the TFTIP

Ezekiel 8 in the TFTU

Ezekiel 8 in the TGNTATF3T

Ezekiel 8 in the THAI

Ezekiel 8 in the TNFD

Ezekiel 8 in the TNT

Ezekiel 8 in the TNTIK

Ezekiel 8 in the TNTIL

Ezekiel 8 in the TNTIN

Ezekiel 8 in the TNTIP

Ezekiel 8 in the TNTIZ

Ezekiel 8 in the TOMA

Ezekiel 8 in the TTENT

Ezekiel 8 in the UBG

Ezekiel 8 in the UGV

Ezekiel 8 in the UGV2

Ezekiel 8 in the UGV3

Ezekiel 8 in the VBL

Ezekiel 8 in the VDCC

Ezekiel 8 in the YALU

Ezekiel 8 in the YAPE

Ezekiel 8 in the YBVTP

Ezekiel 8 in the ZBP