Galatians 1 (BOYCB)
1 Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú. 2 Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi, Sí àwọn ìjọ ní Galatia: 3 Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa, 4 ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa, 5 ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín. 6 Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìyìnrere mìíràn. 7 Nítòótọ́, kò sí ìyìnrere mìíràn bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìnrere Kristi padà. 8 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìyìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! 9 Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé, bí ẹnìkan bá wàásù ìyìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! 10 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi. 11 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìyìnrere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn. 12 N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi. 13 Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́. 14 Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọ́pọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi. 15 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. 16 Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù ìyìnrere rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni, 17 bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerusalẹmu tọ àwọn tí í ṣe aposteli ṣáájú mi, ṣùgbọ́n mo lọ sí Arabia, mo sì tún padà wá sí Damasku. 18 Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerusalẹmu láti lọ kì Peteru, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, 19 èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ aposteli, bí kò ṣe Jakọbu arákùnrin Olúwa. 20 Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí, kíyèsi i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké. 21 Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia. 22 Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea. 23 Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsin yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.” 24 Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.
In Other Versions
Galatians 1 in the ANGEFD
Galatians 1 in the ANTPNG2D
Galatians 1 in the AS21
Galatians 1 in the BAGH
Galatians 1 in the BBPNG
Galatians 1 in the BBT1E
Galatians 1 in the BDS
Galatians 1 in the BEV
Galatians 1 in the BHAD
Galatians 1 in the BIB
Galatians 1 in the BLPT
Galatians 1 in the BNT
Galatians 1 in the BNTABOOT
Galatians 1 in the BNTLV
Galatians 1 in the BOATCB
Galatians 1 in the BOATCB2
Galatians 1 in the BOBCV
Galatians 1 in the BOCNT
Galatians 1 in the BOECS
Galatians 1 in the BOGWICC
Galatians 1 in the BOHCB
Galatians 1 in the BOHCV
Galatians 1 in the BOHLNT
Galatians 1 in the BOHNTLTAL
Galatians 1 in the BOICB
Galatians 1 in the BOILNTAP
Galatians 1 in the BOITCV
Galatians 1 in the BOKCV
Galatians 1 in the BOKCV2
Galatians 1 in the BOKHWOG
Galatians 1 in the BOKSSV
Galatians 1 in the BOLCB
Galatians 1 in the BOLCB2
Galatians 1 in the BOMCV
Galatians 1 in the BONAV
Galatians 1 in the BONCB
Galatians 1 in the BONLT
Galatians 1 in the BONUT2
Galatians 1 in the BOPLNT
Galatians 1 in the BOSCB
Galatians 1 in the BOSNC
Galatians 1 in the BOTLNT
Galatians 1 in the BOVCB
Galatians 1 in the BPBB
Galatians 1 in the BPH
Galatians 1 in the BSB
Galatians 1 in the CCB
Galatians 1 in the CUV
Galatians 1 in the CUVS
Galatians 1 in the DBT
Galatians 1 in the DGDNT
Galatians 1 in the DHNT
Galatians 1 in the DNT
Galatians 1 in the ELBE
Galatians 1 in the EMTV
Galatians 1 in the ESV
Galatians 1 in the FBV
Galatians 1 in the FEB
Galatians 1 in the GGMNT
Galatians 1 in the GNT
Galatians 1 in the HARY
Galatians 1 in the HNT
Galatians 1 in the IRVA
Galatians 1 in the IRVB
Galatians 1 in the IRVG
Galatians 1 in the IRVH
Galatians 1 in the IRVK
Galatians 1 in the IRVM
Galatians 1 in the IRVM2
Galatians 1 in the IRVO
Galatians 1 in the IRVP
Galatians 1 in the IRVT
Galatians 1 in the IRVT2
Galatians 1 in the IRVU
Galatians 1 in the ISVN
Galatians 1 in the JSNT
Galatians 1 in the KAPI
Galatians 1 in the KBT1ETNIK
Galatians 1 in the KBV
Galatians 1 in the KJV
Galatians 1 in the KNFD
Galatians 1 in the LBA
Galatians 1 in the LBLA
Galatians 1 in the LNT
Galatians 1 in the LSV
Galatians 1 in the MAAL
Galatians 1 in the MBV
Galatians 1 in the MBV2
Galatians 1 in the MHNT
Galatians 1 in the MKNFD
Galatians 1 in the MNG
Galatians 1 in the MNT
Galatians 1 in the MNT2
Galatians 1 in the MRS1T
Galatians 1 in the NAA
Galatians 1 in the NASB
Galatians 1 in the NBLA
Galatians 1 in the NBS
Galatians 1 in the NBVTP
Galatians 1 in the NET2
Galatians 1 in the NIV11
Galatians 1 in the NNT
Galatians 1 in the NNT2
Galatians 1 in the NNT3
Galatians 1 in the PDDPT
Galatians 1 in the PFNT
Galatians 1 in the RMNT
Galatians 1 in the SBIAS
Galatians 1 in the SBIBS
Galatians 1 in the SBIBS2
Galatians 1 in the SBICS
Galatians 1 in the SBIDS
Galatians 1 in the SBIGS
Galatians 1 in the SBIHS
Galatians 1 in the SBIIS
Galatians 1 in the SBIIS2
Galatians 1 in the SBIIS3
Galatians 1 in the SBIKS
Galatians 1 in the SBIKS2
Galatians 1 in the SBIMS
Galatians 1 in the SBIOS
Galatians 1 in the SBIPS
Galatians 1 in the SBISS
Galatians 1 in the SBITS
Galatians 1 in the SBITS2
Galatians 1 in the SBITS3
Galatians 1 in the SBITS4
Galatians 1 in the SBIUS
Galatians 1 in the SBIVS
Galatians 1 in the SBT
Galatians 1 in the SBT1E
Galatians 1 in the SCHL
Galatians 1 in the SNT
Galatians 1 in the SUSU
Galatians 1 in the SUSU2
Galatians 1 in the SYNO
Galatians 1 in the TBIAOTANT
Galatians 1 in the TBT1E
Galatians 1 in the TBT1E2
Galatians 1 in the TFTIP
Galatians 1 in the TFTU
Galatians 1 in the TGNTATF3T
Galatians 1 in the THAI
Galatians 1 in the TNFD
Galatians 1 in the TNT
Galatians 1 in the TNTIK
Galatians 1 in the TNTIL
Galatians 1 in the TNTIN
Galatians 1 in the TNTIP
Galatians 1 in the TNTIZ
Galatians 1 in the TOMA
Galatians 1 in the TTENT
Galatians 1 in the UBG
Galatians 1 in the UGV
Galatians 1 in the UGV2
Galatians 1 in the UGV3
Galatians 1 in the VBL
Galatians 1 in the VDCC
Galatians 1 in the YALU
Galatians 1 in the YAPE
Galatians 1 in the YBVTP
Galatians 1 in the ZBP