Genesis 2 (BOYCB)

1 Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. 2 Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. 3 Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe. 4 Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí OLÚWA Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run. 5 Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí OLÚWA Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀. 6 Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀. 7 OLÚWA Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn. 8 OLÚWA Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. 9 OLÚWA Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀, àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà. 10 Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. 11 Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. 12 (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). 13 Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. 14 Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate. 15 OLÚWA Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 16 OLÚWA Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà; 17 ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.” 18 OLÚWA Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.” 19 Lẹ́yìn tí OLÚWA Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. 20 Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ.Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. 21 Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. 22 OLÚWA Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá. 23 Ọkùnrin náà sì wí pé,“Èyí ni egungun láti inú egungun miàti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.” 24 Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan. 25 Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

In Other Versions

Genesis 2 in the ANGEFD

Genesis 2 in the ANTPNG2D

Genesis 2 in the AS21

Genesis 2 in the BAGH

Genesis 2 in the BBPNG

Genesis 2 in the BBT1E

Genesis 2 in the BDS

Genesis 2 in the BEV

Genesis 2 in the BHAD

Genesis 2 in the BIB

Genesis 2 in the BLPT

Genesis 2 in the BNT

Genesis 2 in the BNTABOOT

Genesis 2 in the BNTLV

Genesis 2 in the BOATCB

Genesis 2 in the BOATCB2

Genesis 2 in the BOBCV

Genesis 2 in the BOCNT

Genesis 2 in the BOECS

Genesis 2 in the BOGWICC

Genesis 2 in the BOHCB

Genesis 2 in the BOHCV

Genesis 2 in the BOHLNT

Genesis 2 in the BOHNTLTAL

Genesis 2 in the BOICB

Genesis 2 in the BOILNTAP

Genesis 2 in the BOITCV

Genesis 2 in the BOKCV

Genesis 2 in the BOKCV2

Genesis 2 in the BOKHWOG

Genesis 2 in the BOKSSV

Genesis 2 in the BOLCB

Genesis 2 in the BOLCB2

Genesis 2 in the BOMCV

Genesis 2 in the BONAV

Genesis 2 in the BONCB

Genesis 2 in the BONLT

Genesis 2 in the BONUT2

Genesis 2 in the BOPLNT

Genesis 2 in the BOSCB

Genesis 2 in the BOSNC

Genesis 2 in the BOTLNT

Genesis 2 in the BOVCB

Genesis 2 in the BPBB

Genesis 2 in the BPH

Genesis 2 in the BSB

Genesis 2 in the CCB

Genesis 2 in the CUV

Genesis 2 in the CUVS

Genesis 2 in the DBT

Genesis 2 in the DGDNT

Genesis 2 in the DHNT

Genesis 2 in the DNT

Genesis 2 in the ELBE

Genesis 2 in the EMTV

Genesis 2 in the ESV

Genesis 2 in the FBV

Genesis 2 in the FEB

Genesis 2 in the GGMNT

Genesis 2 in the GNT

Genesis 2 in the HARY

Genesis 2 in the HNT

Genesis 2 in the IRVA

Genesis 2 in the IRVB

Genesis 2 in the IRVG

Genesis 2 in the IRVH

Genesis 2 in the IRVK

Genesis 2 in the IRVM

Genesis 2 in the IRVM2

Genesis 2 in the IRVO

Genesis 2 in the IRVP

Genesis 2 in the IRVT

Genesis 2 in the IRVT2

Genesis 2 in the IRVU

Genesis 2 in the ISVN

Genesis 2 in the JSNT

Genesis 2 in the KAPI

Genesis 2 in the KBT1ETNIK

Genesis 2 in the KBV

Genesis 2 in the KJV

Genesis 2 in the KNFD

Genesis 2 in the LBA

Genesis 2 in the LBLA

Genesis 2 in the LNT

Genesis 2 in the LSV

Genesis 2 in the MAAL

Genesis 2 in the MBV

Genesis 2 in the MBV2

Genesis 2 in the MHNT

Genesis 2 in the MKNFD

Genesis 2 in the MNG

Genesis 2 in the MNT

Genesis 2 in the MNT2

Genesis 2 in the MRS1T

Genesis 2 in the NAA

Genesis 2 in the NASB

Genesis 2 in the NBLA

Genesis 2 in the NBS

Genesis 2 in the NBVTP

Genesis 2 in the NET2

Genesis 2 in the NIV11

Genesis 2 in the NNT

Genesis 2 in the NNT2

Genesis 2 in the NNT3

Genesis 2 in the PDDPT

Genesis 2 in the PFNT

Genesis 2 in the RMNT

Genesis 2 in the SBIAS

Genesis 2 in the SBIBS

Genesis 2 in the SBIBS2

Genesis 2 in the SBICS

Genesis 2 in the SBIDS

Genesis 2 in the SBIGS

Genesis 2 in the SBIHS

Genesis 2 in the SBIIS

Genesis 2 in the SBIIS2

Genesis 2 in the SBIIS3

Genesis 2 in the SBIKS

Genesis 2 in the SBIKS2

Genesis 2 in the SBIMS

Genesis 2 in the SBIOS

Genesis 2 in the SBIPS

Genesis 2 in the SBISS

Genesis 2 in the SBITS

Genesis 2 in the SBITS2

Genesis 2 in the SBITS3

Genesis 2 in the SBITS4

Genesis 2 in the SBIUS

Genesis 2 in the SBIVS

Genesis 2 in the SBT

Genesis 2 in the SBT1E

Genesis 2 in the SCHL

Genesis 2 in the SNT

Genesis 2 in the SUSU

Genesis 2 in the SUSU2

Genesis 2 in the SYNO

Genesis 2 in the TBIAOTANT

Genesis 2 in the TBT1E

Genesis 2 in the TBT1E2

Genesis 2 in the TFTIP

Genesis 2 in the TFTU

Genesis 2 in the TGNTATF3T

Genesis 2 in the THAI

Genesis 2 in the TNFD

Genesis 2 in the TNT

Genesis 2 in the TNTIK

Genesis 2 in the TNTIL

Genesis 2 in the TNTIN

Genesis 2 in the TNTIP

Genesis 2 in the TNTIZ

Genesis 2 in the TOMA

Genesis 2 in the TTENT

Genesis 2 in the UBG

Genesis 2 in the UGV

Genesis 2 in the UGV2

Genesis 2 in the UGV3

Genesis 2 in the VBL

Genesis 2 in the VDCC

Genesis 2 in the YALU

Genesis 2 in the YAPE

Genesis 2 in the YBVTP

Genesis 2 in the ZBP