Genesis 8 (BOYCB)
1 Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà. 2 Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró. 3 Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yìn àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà. 4 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè Ararati. 5 Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, orí àwọn òkè sì farahàn. 6 Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀. 7 Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti sẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀. 8 Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. 9 Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Noa. Noa na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀. 10 Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. 11 Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. 12 Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. 13 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ. 14 Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátápátá. 15 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé. 16 “Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn. 17 Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde: àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn lórí ilẹ̀.” 18 Noa, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde. 19 Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátápátá ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn. 20 Noa sì mọ pẹpẹ fún OLÚWA, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. 21 OLÚWA sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe. 22 “Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà,ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórèìgbà òtútù àti ìgbà ooru,ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò,ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru,yóò wà títí láé.”
In Other Versions
Genesis 8 in the ANGEFD
Genesis 8 in the ANTPNG2D
Genesis 8 in the AS21
Genesis 8 in the BAGH
Genesis 8 in the BBPNG
Genesis 8 in the BBT1E
Genesis 8 in the BDS
Genesis 8 in the BEV
Genesis 8 in the BHAD
Genesis 8 in the BIB
Genesis 8 in the BLPT
Genesis 8 in the BNT
Genesis 8 in the BNTABOOT
Genesis 8 in the BNTLV
Genesis 8 in the BOATCB
Genesis 8 in the BOATCB2
Genesis 8 in the BOBCV
Genesis 8 in the BOCNT
Genesis 8 in the BOECS
Genesis 8 in the BOGWICC
Genesis 8 in the BOHCB
Genesis 8 in the BOHCV
Genesis 8 in the BOHLNT
Genesis 8 in the BOHNTLTAL
Genesis 8 in the BOICB
Genesis 8 in the BOILNTAP
Genesis 8 in the BOITCV
Genesis 8 in the BOKCV
Genesis 8 in the BOKCV2
Genesis 8 in the BOKHWOG
Genesis 8 in the BOKSSV
Genesis 8 in the BOLCB
Genesis 8 in the BOLCB2
Genesis 8 in the BOMCV
Genesis 8 in the BONAV
Genesis 8 in the BONCB
Genesis 8 in the BONLT
Genesis 8 in the BONUT2
Genesis 8 in the BOPLNT
Genesis 8 in the BOSCB
Genesis 8 in the BOSNC
Genesis 8 in the BOTLNT
Genesis 8 in the BOVCB
Genesis 8 in the BPBB
Genesis 8 in the BPH
Genesis 8 in the BSB
Genesis 8 in the CCB
Genesis 8 in the CUV
Genesis 8 in the CUVS
Genesis 8 in the DBT
Genesis 8 in the DGDNT
Genesis 8 in the DHNT
Genesis 8 in the DNT
Genesis 8 in the ELBE
Genesis 8 in the EMTV
Genesis 8 in the ESV
Genesis 8 in the FBV
Genesis 8 in the FEB
Genesis 8 in the GGMNT
Genesis 8 in the GNT
Genesis 8 in the HARY
Genesis 8 in the HNT
Genesis 8 in the IRVA
Genesis 8 in the IRVB
Genesis 8 in the IRVG
Genesis 8 in the IRVH
Genesis 8 in the IRVK
Genesis 8 in the IRVM
Genesis 8 in the IRVM2
Genesis 8 in the IRVO
Genesis 8 in the IRVP
Genesis 8 in the IRVT
Genesis 8 in the IRVT2
Genesis 8 in the IRVU
Genesis 8 in the ISVN
Genesis 8 in the JSNT
Genesis 8 in the KAPI
Genesis 8 in the KBT1ETNIK
Genesis 8 in the KBV
Genesis 8 in the KJV
Genesis 8 in the KNFD
Genesis 8 in the LBA
Genesis 8 in the LBLA
Genesis 8 in the LNT
Genesis 8 in the LSV
Genesis 8 in the MAAL
Genesis 8 in the MBV
Genesis 8 in the MBV2
Genesis 8 in the MHNT
Genesis 8 in the MKNFD
Genesis 8 in the MNG
Genesis 8 in the MNT
Genesis 8 in the MNT2
Genesis 8 in the MRS1T
Genesis 8 in the NAA
Genesis 8 in the NASB
Genesis 8 in the NBLA
Genesis 8 in the NBS
Genesis 8 in the NBVTP
Genesis 8 in the NET2
Genesis 8 in the NIV11
Genesis 8 in the NNT
Genesis 8 in the NNT2
Genesis 8 in the NNT3
Genesis 8 in the PDDPT
Genesis 8 in the PFNT
Genesis 8 in the RMNT
Genesis 8 in the SBIAS
Genesis 8 in the SBIBS
Genesis 8 in the SBIBS2
Genesis 8 in the SBICS
Genesis 8 in the SBIDS
Genesis 8 in the SBIGS
Genesis 8 in the SBIHS
Genesis 8 in the SBIIS
Genesis 8 in the SBIIS2
Genesis 8 in the SBIIS3
Genesis 8 in the SBIKS
Genesis 8 in the SBIKS2
Genesis 8 in the SBIMS
Genesis 8 in the SBIOS
Genesis 8 in the SBIPS
Genesis 8 in the SBISS
Genesis 8 in the SBITS
Genesis 8 in the SBITS2
Genesis 8 in the SBITS3
Genesis 8 in the SBITS4
Genesis 8 in the SBIUS
Genesis 8 in the SBIVS
Genesis 8 in the SBT
Genesis 8 in the SBT1E
Genesis 8 in the SCHL
Genesis 8 in the SNT
Genesis 8 in the SUSU
Genesis 8 in the SUSU2
Genesis 8 in the SYNO
Genesis 8 in the TBIAOTANT
Genesis 8 in the TBT1E
Genesis 8 in the TBT1E2
Genesis 8 in the TFTIP
Genesis 8 in the TFTU
Genesis 8 in the TGNTATF3T
Genesis 8 in the THAI
Genesis 8 in the TNFD
Genesis 8 in the TNT
Genesis 8 in the TNTIK
Genesis 8 in the TNTIL
Genesis 8 in the TNTIN
Genesis 8 in the TNTIP
Genesis 8 in the TNTIZ
Genesis 8 in the TOMA
Genesis 8 in the TTENT
Genesis 8 in the UBG
Genesis 8 in the UGV
Genesis 8 in the UGV2
Genesis 8 in the UGV3
Genesis 8 in the VBL
Genesis 8 in the VDCC
Genesis 8 in the YALU
Genesis 8 in the YAPE
Genesis 8 in the YBVTP
Genesis 8 in the ZBP