Genesis 9 (BOYCB)
1 Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé. 2 Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. 3 Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín. 4 “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 5 Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn. 6 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀,láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.Nítorí ní àwòrán Ọlọ́runni Ọlọ́run dá ènìyàn. 7 Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.” 8 Ọlọ́run sì wí fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, 9 “Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn. 10 Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé. 11 Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.” 12 Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀: 13 Mo ti fi òṣùmàrè sí àwọsánmọ̀, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín èmi àti ayé. 14 Nígbàkígbà tí mo bá mú kí òjò ṣú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní àwọsánmọ̀. 15 Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run. 16 Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.” 17 Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrín èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.” 18 Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani.) 19 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Noa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé. 20 Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà. 21 Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀. 22 Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. 23 Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn. 24 Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. 25 Ó wí pé,“Ègún ni fún Kenaani.Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣefún àwọn arákùnrin rẹ̀.” 26 Ó sì tún wí pé,“Olùbùkún ni OLÚWA, Ọlọ́run ṢemuKenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu. 27 Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀,Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ ṢemuKenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.” 28 Noa wà láààyè fún irinwó ọdún dín àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. 29 Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín làádọ́ta (950), ó sì kú.
In Other Versions
Genesis 9 in the ANGEFD
Genesis 9 in the ANTPNG2D
Genesis 9 in the AS21
Genesis 9 in the BAGH
Genesis 9 in the BBPNG
Genesis 9 in the BBT1E
Genesis 9 in the BDS
Genesis 9 in the BEV
Genesis 9 in the BHAD
Genesis 9 in the BIB
Genesis 9 in the BLPT
Genesis 9 in the BNT
Genesis 9 in the BNTABOOT
Genesis 9 in the BNTLV
Genesis 9 in the BOATCB
Genesis 9 in the BOATCB2
Genesis 9 in the BOBCV
Genesis 9 in the BOCNT
Genesis 9 in the BOECS
Genesis 9 in the BOGWICC
Genesis 9 in the BOHCB
Genesis 9 in the BOHCV
Genesis 9 in the BOHLNT
Genesis 9 in the BOHNTLTAL
Genesis 9 in the BOICB
Genesis 9 in the BOILNTAP
Genesis 9 in the BOITCV
Genesis 9 in the BOKCV
Genesis 9 in the BOKCV2
Genesis 9 in the BOKHWOG
Genesis 9 in the BOKSSV
Genesis 9 in the BOLCB
Genesis 9 in the BOLCB2
Genesis 9 in the BOMCV
Genesis 9 in the BONAV
Genesis 9 in the BONCB
Genesis 9 in the BONLT
Genesis 9 in the BONUT2
Genesis 9 in the BOPLNT
Genesis 9 in the BOSCB
Genesis 9 in the BOSNC
Genesis 9 in the BOTLNT
Genesis 9 in the BOVCB
Genesis 9 in the BPBB
Genesis 9 in the BPH
Genesis 9 in the BSB
Genesis 9 in the CCB
Genesis 9 in the CUV
Genesis 9 in the CUVS
Genesis 9 in the DBT
Genesis 9 in the DGDNT
Genesis 9 in the DHNT
Genesis 9 in the DNT
Genesis 9 in the ELBE
Genesis 9 in the EMTV
Genesis 9 in the ESV
Genesis 9 in the FBV
Genesis 9 in the FEB
Genesis 9 in the GGMNT
Genesis 9 in the GNT
Genesis 9 in the HARY
Genesis 9 in the HNT
Genesis 9 in the IRVA
Genesis 9 in the IRVB
Genesis 9 in the IRVG
Genesis 9 in the IRVH
Genesis 9 in the IRVK
Genesis 9 in the IRVM
Genesis 9 in the IRVM2
Genesis 9 in the IRVO
Genesis 9 in the IRVP
Genesis 9 in the IRVT
Genesis 9 in the IRVT2
Genesis 9 in the IRVU
Genesis 9 in the ISVN
Genesis 9 in the JSNT
Genesis 9 in the KAPI
Genesis 9 in the KBT1ETNIK
Genesis 9 in the KBV
Genesis 9 in the KJV
Genesis 9 in the KNFD
Genesis 9 in the LBA
Genesis 9 in the LBLA
Genesis 9 in the LNT
Genesis 9 in the LSV
Genesis 9 in the MAAL
Genesis 9 in the MBV
Genesis 9 in the MBV2
Genesis 9 in the MHNT
Genesis 9 in the MKNFD
Genesis 9 in the MNG
Genesis 9 in the MNT
Genesis 9 in the MNT2
Genesis 9 in the MRS1T
Genesis 9 in the NAA
Genesis 9 in the NASB
Genesis 9 in the NBLA
Genesis 9 in the NBS
Genesis 9 in the NBVTP
Genesis 9 in the NET2
Genesis 9 in the NIV11
Genesis 9 in the NNT
Genesis 9 in the NNT2
Genesis 9 in the NNT3
Genesis 9 in the PDDPT
Genesis 9 in the PFNT
Genesis 9 in the RMNT
Genesis 9 in the SBIAS
Genesis 9 in the SBIBS
Genesis 9 in the SBIBS2
Genesis 9 in the SBICS
Genesis 9 in the SBIDS
Genesis 9 in the SBIGS
Genesis 9 in the SBIHS
Genesis 9 in the SBIIS
Genesis 9 in the SBIIS2
Genesis 9 in the SBIIS3
Genesis 9 in the SBIKS
Genesis 9 in the SBIKS2
Genesis 9 in the SBIMS
Genesis 9 in the SBIOS
Genesis 9 in the SBIPS
Genesis 9 in the SBISS
Genesis 9 in the SBITS
Genesis 9 in the SBITS2
Genesis 9 in the SBITS3
Genesis 9 in the SBITS4
Genesis 9 in the SBIUS
Genesis 9 in the SBIVS
Genesis 9 in the SBT
Genesis 9 in the SBT1E
Genesis 9 in the SCHL
Genesis 9 in the SNT
Genesis 9 in the SUSU
Genesis 9 in the SUSU2
Genesis 9 in the SYNO
Genesis 9 in the TBIAOTANT
Genesis 9 in the TBT1E
Genesis 9 in the TBT1E2
Genesis 9 in the TFTIP
Genesis 9 in the TFTU
Genesis 9 in the TGNTATF3T
Genesis 9 in the THAI
Genesis 9 in the TNFD
Genesis 9 in the TNT
Genesis 9 in the TNTIK
Genesis 9 in the TNTIL
Genesis 9 in the TNTIN
Genesis 9 in the TNTIP
Genesis 9 in the TNTIZ
Genesis 9 in the TOMA
Genesis 9 in the TTENT
Genesis 9 in the UBG
Genesis 9 in the UGV
Genesis 9 in the UGV2
Genesis 9 in the UGV3
Genesis 9 in the VBL
Genesis 9 in the VDCC
Genesis 9 in the YALU
Genesis 9 in the YAPE
Genesis 9 in the YBVTP
Genesis 9 in the ZBP