Judges 14 (BOYCB)
1 Nígbà kan Samsoni gòkè lọ sí Timna níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Filistini kan. 2 Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.” 3 Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?”Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.” 4 (Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ OLÚWA ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Filistini jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Israẹli ní àkókò náà.) 5 Samsoni sọ̀kalẹ̀ lọ sí Timna òun àti baba àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Timna, láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. 6 Ẹ̀mí OLÚWA sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀. 7 Ó sì lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, inú Samsoni sì yọ́ sí i. 8 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin, 9 ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà. 10 Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Samsoni sì ṣe àsè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà. 11 Nígbà tí ó fi ara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́. 12 Samsoni sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtumọ̀ rẹ̀ láàrín ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àlọ́ náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìyàwó. 13 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.”Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.” 14 Ó dáhùn pé,“Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá;láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.”Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtumọ̀ sí àlọ́ náà. 15 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Samsoni, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòṣì tàbí kó wa lẹ́rú ni?” 16 Nígbà náà ni ìyàwó Samsoni ṣubú lé e láyà, ó sì sọkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! O kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”“Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.” 17 Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sọkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀. 18 Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé,“Kí ni ó dùn ju oyin lọ?Kí ni ó sì lágbára ju kìnnìún lọ?”Samsoni dá wọn lóhùn pé,“Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ abo màlúù mi kọ ilẹ̀,ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.” 19 Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí OLÚWA bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Aṣkeloni, ó pa ọgbọ̀n nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru. 20 Wọ́n sì fi ìyàwó Samsoni fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ nígbà ìgbéyàwó rẹ̀.
In Other Versions
Judges 14 in the ANGEFD
Judges 14 in the ANTPNG2D
Judges 14 in the AS21
Judges 14 in the BAGH
Judges 14 in the BBPNG
Judges 14 in the BBT1E
Judges 14 in the BDS
Judges 14 in the BEV
Judges 14 in the BHAD
Judges 14 in the BIB
Judges 14 in the BLPT
Judges 14 in the BNT
Judges 14 in the BNTABOOT
Judges 14 in the BNTLV
Judges 14 in the BOATCB
Judges 14 in the BOATCB2
Judges 14 in the BOBCV
Judges 14 in the BOCNT
Judges 14 in the BOECS
Judges 14 in the BOGWICC
Judges 14 in the BOHCB
Judges 14 in the BOHCV
Judges 14 in the BOHLNT
Judges 14 in the BOHNTLTAL
Judges 14 in the BOICB
Judges 14 in the BOILNTAP
Judges 14 in the BOITCV
Judges 14 in the BOKCV
Judges 14 in the BOKCV2
Judges 14 in the BOKHWOG
Judges 14 in the BOKSSV
Judges 14 in the BOLCB
Judges 14 in the BOLCB2
Judges 14 in the BOMCV
Judges 14 in the BONAV
Judges 14 in the BONCB
Judges 14 in the BONLT
Judges 14 in the BONUT2
Judges 14 in the BOPLNT
Judges 14 in the BOSCB
Judges 14 in the BOSNC
Judges 14 in the BOTLNT
Judges 14 in the BOVCB
Judges 14 in the BPBB
Judges 14 in the BPH
Judges 14 in the BSB
Judges 14 in the CCB
Judges 14 in the CUV
Judges 14 in the CUVS
Judges 14 in the DBT
Judges 14 in the DGDNT
Judges 14 in the DHNT
Judges 14 in the DNT
Judges 14 in the ELBE
Judges 14 in the EMTV
Judges 14 in the ESV
Judges 14 in the FBV
Judges 14 in the FEB
Judges 14 in the GGMNT
Judges 14 in the GNT
Judges 14 in the HARY
Judges 14 in the HNT
Judges 14 in the IRVA
Judges 14 in the IRVB
Judges 14 in the IRVG
Judges 14 in the IRVH
Judges 14 in the IRVK
Judges 14 in the IRVM
Judges 14 in the IRVM2
Judges 14 in the IRVO
Judges 14 in the IRVP
Judges 14 in the IRVT
Judges 14 in the IRVT2
Judges 14 in the IRVU
Judges 14 in the ISVN
Judges 14 in the JSNT
Judges 14 in the KAPI
Judges 14 in the KBT1ETNIK
Judges 14 in the KBV
Judges 14 in the KJV
Judges 14 in the KNFD
Judges 14 in the LBA
Judges 14 in the LBLA
Judges 14 in the LNT
Judges 14 in the LSV
Judges 14 in the MAAL
Judges 14 in the MBV
Judges 14 in the MBV2
Judges 14 in the MHNT
Judges 14 in the MKNFD
Judges 14 in the MNG
Judges 14 in the MNT
Judges 14 in the MNT2
Judges 14 in the MRS1T
Judges 14 in the NAA
Judges 14 in the NASB
Judges 14 in the NBLA
Judges 14 in the NBS
Judges 14 in the NBVTP
Judges 14 in the NET2
Judges 14 in the NIV11
Judges 14 in the NNT
Judges 14 in the NNT2
Judges 14 in the NNT3
Judges 14 in the PDDPT
Judges 14 in the PFNT
Judges 14 in the RMNT
Judges 14 in the SBIAS
Judges 14 in the SBIBS
Judges 14 in the SBIBS2
Judges 14 in the SBICS
Judges 14 in the SBIDS
Judges 14 in the SBIGS
Judges 14 in the SBIHS
Judges 14 in the SBIIS
Judges 14 in the SBIIS2
Judges 14 in the SBIIS3
Judges 14 in the SBIKS
Judges 14 in the SBIKS2
Judges 14 in the SBIMS
Judges 14 in the SBIOS
Judges 14 in the SBIPS
Judges 14 in the SBISS
Judges 14 in the SBITS
Judges 14 in the SBITS2
Judges 14 in the SBITS3
Judges 14 in the SBITS4
Judges 14 in the SBIUS
Judges 14 in the SBIVS
Judges 14 in the SBT
Judges 14 in the SBT1E
Judges 14 in the SCHL
Judges 14 in the SNT
Judges 14 in the SUSU
Judges 14 in the SUSU2
Judges 14 in the SYNO
Judges 14 in the TBIAOTANT
Judges 14 in the TBT1E
Judges 14 in the TBT1E2
Judges 14 in the TFTIP
Judges 14 in the TFTU
Judges 14 in the TGNTATF3T
Judges 14 in the THAI
Judges 14 in the TNFD
Judges 14 in the TNT
Judges 14 in the TNTIK
Judges 14 in the TNTIL
Judges 14 in the TNTIN
Judges 14 in the TNTIP
Judges 14 in the TNTIZ
Judges 14 in the TOMA
Judges 14 in the TTENT
Judges 14 in the UBG
Judges 14 in the UGV
Judges 14 in the UGV2
Judges 14 in the UGV3
Judges 14 in the VBL
Judges 14 in the VDCC
Judges 14 in the YALU
Judges 14 in the YAPE
Judges 14 in the YBVTP
Judges 14 in the ZBP