Jeremiah 41 (BOYCB)
1 Ní oṣù keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, àti àwọn ìjòyè ọba, àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu wá ní Mispa; níbẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ jẹun ní Mispa. 2 Iṣmaeli ọmọ Netaniah àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ilẹ̀ náà. 3 Iṣmaeli sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Gedaliah ní Mispa, àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun Babeli tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà. 4 Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Gedaliah kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀, 5 àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣekemu, Ṣilo àti Samaria, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n ṣá ara wọn lọ́gbẹ́, wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé OLÚWA. 6 Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah jáde kúrò láti Mispa láti lọ pàdé wọn. Ó sì ń sọkún bí ó ti ṣe ń lọ, nígbà tí ó pàdé wọn, ó wí pé, “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu.” 7 Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ihò kan. 8 Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Iṣmaeli pé, “Má ṣe pa wá! Àwa ní ọkà àti barle, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀: kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yòókù. 9 Nísinsin yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Gedaliah sí ni ọba Asa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí ọba Baaṣa ti Israẹli. Iṣmaeli ọmọ Netaniah sì ti kó òkú kún inú rẹ̀. 10 Iṣmaeli sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mispa nígbèkùn, ọmọbìnrin ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tókù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti fi yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ṣe olórí. Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ammoni. 11 Nígbà tí Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti ṣe. 12 Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Iṣmaeli ọmọ Netaniah jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gibeoni. 13 Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Iṣmaeli tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Johanani ọmọkùnrin Karea àti àwọn olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀. 14 Gbogbo àwọn ènìyàn tí Iṣmaeli ti kó ní ìgbèkùn ní Mispa yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Johanani ọmọ Karea. 15 Ṣùgbọ́n Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn mẹ́jọ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Johanani, wọ́n sì sálọ sí Ammoni. 16 Lẹ́yìn náà Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mispa; àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah; lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu. Àwọn ọmọ-ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gibeoni. 17 Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n dúró ní Geruti Kimhamu ní ẹ̀bá Bẹtilẹhẹmu ní ọ́nà ìrìnàjò wọn sí Ejibiti. 18 Láti gba àwọn Babeli sílẹ̀. Wọ́n bẹ̀rù wọn nítorí wí pé, “Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu èyí tí ọba Babeli ti yàn gẹ́gẹ́ bí i gómìnà lórí ilẹ̀ náà.”
In Other Versions
Jeremiah 41 in the ANGEFD
Jeremiah 41 in the ANTPNG2D
Jeremiah 41 in the AS21
Jeremiah 41 in the BAGH
Jeremiah 41 in the BBPNG
Jeremiah 41 in the BBT1E
Jeremiah 41 in the BDS
Jeremiah 41 in the BEV
Jeremiah 41 in the BHAD
Jeremiah 41 in the BIB
Jeremiah 41 in the BLPT
Jeremiah 41 in the BNT
Jeremiah 41 in the BNTABOOT
Jeremiah 41 in the BNTLV
Jeremiah 41 in the BOATCB
Jeremiah 41 in the BOATCB2
Jeremiah 41 in the BOBCV
Jeremiah 41 in the BOCNT
Jeremiah 41 in the BOECS
Jeremiah 41 in the BOGWICC
Jeremiah 41 in the BOHCB
Jeremiah 41 in the BOHCV
Jeremiah 41 in the BOHLNT
Jeremiah 41 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 41 in the BOICB
Jeremiah 41 in the BOILNTAP
Jeremiah 41 in the BOITCV
Jeremiah 41 in the BOKCV
Jeremiah 41 in the BOKCV2
Jeremiah 41 in the BOKHWOG
Jeremiah 41 in the BOKSSV
Jeremiah 41 in the BOLCB
Jeremiah 41 in the BOLCB2
Jeremiah 41 in the BOMCV
Jeremiah 41 in the BONAV
Jeremiah 41 in the BONCB
Jeremiah 41 in the BONLT
Jeremiah 41 in the BONUT2
Jeremiah 41 in the BOPLNT
Jeremiah 41 in the BOSCB
Jeremiah 41 in the BOSNC
Jeremiah 41 in the BOTLNT
Jeremiah 41 in the BOVCB
Jeremiah 41 in the BPBB
Jeremiah 41 in the BPH
Jeremiah 41 in the BSB
Jeremiah 41 in the CCB
Jeremiah 41 in the CUV
Jeremiah 41 in the CUVS
Jeremiah 41 in the DBT
Jeremiah 41 in the DGDNT
Jeremiah 41 in the DHNT
Jeremiah 41 in the DNT
Jeremiah 41 in the ELBE
Jeremiah 41 in the EMTV
Jeremiah 41 in the ESV
Jeremiah 41 in the FBV
Jeremiah 41 in the FEB
Jeremiah 41 in the GGMNT
Jeremiah 41 in the GNT
Jeremiah 41 in the HARY
Jeremiah 41 in the HNT
Jeremiah 41 in the IRVA
Jeremiah 41 in the IRVB
Jeremiah 41 in the IRVG
Jeremiah 41 in the IRVH
Jeremiah 41 in the IRVK
Jeremiah 41 in the IRVM
Jeremiah 41 in the IRVM2
Jeremiah 41 in the IRVO
Jeremiah 41 in the IRVP
Jeremiah 41 in the IRVT
Jeremiah 41 in the IRVT2
Jeremiah 41 in the IRVU
Jeremiah 41 in the ISVN
Jeremiah 41 in the JSNT
Jeremiah 41 in the KAPI
Jeremiah 41 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 41 in the KBV
Jeremiah 41 in the KJV
Jeremiah 41 in the KNFD
Jeremiah 41 in the LBA
Jeremiah 41 in the LBLA
Jeremiah 41 in the LNT
Jeremiah 41 in the LSV
Jeremiah 41 in the MAAL
Jeremiah 41 in the MBV
Jeremiah 41 in the MBV2
Jeremiah 41 in the MHNT
Jeremiah 41 in the MKNFD
Jeremiah 41 in the MNG
Jeremiah 41 in the MNT
Jeremiah 41 in the MNT2
Jeremiah 41 in the MRS1T
Jeremiah 41 in the NAA
Jeremiah 41 in the NASB
Jeremiah 41 in the NBLA
Jeremiah 41 in the NBS
Jeremiah 41 in the NBVTP
Jeremiah 41 in the NET2
Jeremiah 41 in the NIV11
Jeremiah 41 in the NNT
Jeremiah 41 in the NNT2
Jeremiah 41 in the NNT3
Jeremiah 41 in the PDDPT
Jeremiah 41 in the PFNT
Jeremiah 41 in the RMNT
Jeremiah 41 in the SBIAS
Jeremiah 41 in the SBIBS
Jeremiah 41 in the SBIBS2
Jeremiah 41 in the SBICS
Jeremiah 41 in the SBIDS
Jeremiah 41 in the SBIGS
Jeremiah 41 in the SBIHS
Jeremiah 41 in the SBIIS
Jeremiah 41 in the SBIIS2
Jeremiah 41 in the SBIIS3
Jeremiah 41 in the SBIKS
Jeremiah 41 in the SBIKS2
Jeremiah 41 in the SBIMS
Jeremiah 41 in the SBIOS
Jeremiah 41 in the SBIPS
Jeremiah 41 in the SBISS
Jeremiah 41 in the SBITS
Jeremiah 41 in the SBITS2
Jeremiah 41 in the SBITS3
Jeremiah 41 in the SBITS4
Jeremiah 41 in the SBIUS
Jeremiah 41 in the SBIVS
Jeremiah 41 in the SBT
Jeremiah 41 in the SBT1E
Jeremiah 41 in the SCHL
Jeremiah 41 in the SNT
Jeremiah 41 in the SUSU
Jeremiah 41 in the SUSU2
Jeremiah 41 in the SYNO
Jeremiah 41 in the TBIAOTANT
Jeremiah 41 in the TBT1E
Jeremiah 41 in the TBT1E2
Jeremiah 41 in the TFTIP
Jeremiah 41 in the TFTU
Jeremiah 41 in the TGNTATF3T
Jeremiah 41 in the THAI
Jeremiah 41 in the TNFD
Jeremiah 41 in the TNT
Jeremiah 41 in the TNTIK
Jeremiah 41 in the TNTIL
Jeremiah 41 in the TNTIN
Jeremiah 41 in the TNTIP
Jeremiah 41 in the TNTIZ
Jeremiah 41 in the TOMA
Jeremiah 41 in the TTENT
Jeremiah 41 in the UBG
Jeremiah 41 in the UGV
Jeremiah 41 in the UGV2
Jeremiah 41 in the UGV3
Jeremiah 41 in the VBL
Jeremiah 41 in the VDCC
Jeremiah 41 in the YALU
Jeremiah 41 in the YAPE
Jeremiah 41 in the YBVTP
Jeremiah 41 in the ZBP