Job 40 (BOYCB)

1 OLÚWA dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé, 2 “Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!” 3 Nígbà náà ni Jobu dá OLÚWA lóhùn wá ó sì wí pé, 4 “Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi. 5 Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.” 6 Nígbà náà ní OLÚWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé, 7 “Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,èmi ó bi ọ léèrè,kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn. 8 “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo. 9 Ìwọ ni apá bí Ọlọ́runtàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun? 10 Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ. 11 Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. 12 Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn. 13 Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú. 14 Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là. 15 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,tí mo dá pẹ̀lú rẹ,òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù. 16 Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ. 17 Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari,iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀. 18 Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ,Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin. 19 Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́. 20 Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀. 21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀. 22 Igi lótusì síji wọn bò o;igi arọrọ odò yí i káàkiri. 23 Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀. 24 Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?

In Other Versions

Job 40 in the ANGEFD

Job 40 in the ANTPNG2D

Job 40 in the AS21

Job 40 in the BAGH

Job 40 in the BBPNG

Job 40 in the BBT1E

Job 40 in the BDS

Job 40 in the BEV

Job 40 in the BHAD

Job 40 in the BIB

Job 40 in the BLPT

Job 40 in the BNT

Job 40 in the BNTABOOT

Job 40 in the BNTLV

Job 40 in the BOATCB

Job 40 in the BOATCB2

Job 40 in the BOBCV

Job 40 in the BOCNT

Job 40 in the BOECS

Job 40 in the BOGWICC

Job 40 in the BOHCB

Job 40 in the BOHCV

Job 40 in the BOHLNT

Job 40 in the BOHNTLTAL

Job 40 in the BOICB

Job 40 in the BOILNTAP

Job 40 in the BOITCV

Job 40 in the BOKCV

Job 40 in the BOKCV2

Job 40 in the BOKHWOG

Job 40 in the BOKSSV

Job 40 in the BOLCB

Job 40 in the BOLCB2

Job 40 in the BOMCV

Job 40 in the BONAV

Job 40 in the BONCB

Job 40 in the BONLT

Job 40 in the BONUT2

Job 40 in the BOPLNT

Job 40 in the BOSCB

Job 40 in the BOSNC

Job 40 in the BOTLNT

Job 40 in the BOVCB

Job 40 in the BPBB

Job 40 in the BPH

Job 40 in the BSB

Job 40 in the CCB

Job 40 in the CUV

Job 40 in the CUVS

Job 40 in the DBT

Job 40 in the DGDNT

Job 40 in the DHNT

Job 40 in the DNT

Job 40 in the ELBE

Job 40 in the EMTV

Job 40 in the ESV

Job 40 in the FBV

Job 40 in the FEB

Job 40 in the GGMNT

Job 40 in the GNT

Job 40 in the HARY

Job 40 in the HNT

Job 40 in the IRVA

Job 40 in the IRVB

Job 40 in the IRVG

Job 40 in the IRVH

Job 40 in the IRVK

Job 40 in the IRVM

Job 40 in the IRVM2

Job 40 in the IRVO

Job 40 in the IRVP

Job 40 in the IRVT

Job 40 in the IRVT2

Job 40 in the IRVU

Job 40 in the ISVN

Job 40 in the JSNT

Job 40 in the KAPI

Job 40 in the KBT1ETNIK

Job 40 in the KBV

Job 40 in the KJV

Job 40 in the KNFD

Job 40 in the LBA

Job 40 in the LBLA

Job 40 in the LNT

Job 40 in the LSV

Job 40 in the MAAL

Job 40 in the MBV

Job 40 in the MBV2

Job 40 in the MHNT

Job 40 in the MKNFD

Job 40 in the MNG

Job 40 in the MNT

Job 40 in the MNT2

Job 40 in the MRS1T

Job 40 in the NAA

Job 40 in the NASB

Job 40 in the NBLA

Job 40 in the NBS

Job 40 in the NBVTP

Job 40 in the NET2

Job 40 in the NIV11

Job 40 in the NNT

Job 40 in the NNT2

Job 40 in the NNT3

Job 40 in the PDDPT

Job 40 in the PFNT

Job 40 in the RMNT

Job 40 in the SBIAS

Job 40 in the SBIBS

Job 40 in the SBIBS2

Job 40 in the SBICS

Job 40 in the SBIDS

Job 40 in the SBIGS

Job 40 in the SBIHS

Job 40 in the SBIIS

Job 40 in the SBIIS2

Job 40 in the SBIIS3

Job 40 in the SBIKS

Job 40 in the SBIKS2

Job 40 in the SBIMS

Job 40 in the SBIOS

Job 40 in the SBIPS

Job 40 in the SBISS

Job 40 in the SBITS

Job 40 in the SBITS2

Job 40 in the SBITS3

Job 40 in the SBITS4

Job 40 in the SBIUS

Job 40 in the SBIVS

Job 40 in the SBT

Job 40 in the SBT1E

Job 40 in the SCHL

Job 40 in the SNT

Job 40 in the SUSU

Job 40 in the SUSU2

Job 40 in the SYNO

Job 40 in the TBIAOTANT

Job 40 in the TBT1E

Job 40 in the TBT1E2

Job 40 in the TFTIP

Job 40 in the TFTU

Job 40 in the TGNTATF3T

Job 40 in the THAI

Job 40 in the TNFD

Job 40 in the TNT

Job 40 in the TNTIK

Job 40 in the TNTIL

Job 40 in the TNTIN

Job 40 in the TNTIP

Job 40 in the TNTIZ

Job 40 in the TOMA

Job 40 in the TTENT

Job 40 in the UBG

Job 40 in the UGV

Job 40 in the UGV2

Job 40 in the UGV3

Job 40 in the VBL

Job 40 in the VDCC

Job 40 in the YALU

Job 40 in the YAPE

Job 40 in the YBVTP

Job 40 in the ZBP