Leviticus 6 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí OLÚWA nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ, 3 tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀. 4 Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he, 5 tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀. 6 Fún ìtánràn rẹ̀, ó gbọdọ̀ mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá fún àlùfáà, àní síwájú OLÚWA, ẹbọ ẹ̀bi, àgbò aláìlábùkù, tó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. 7 Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú OLÚWA, a ó sì dáríjì í nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú un jẹ̀bi.” 8 OLÚWA sọ fún Mose pé, 9 “Pàṣẹ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun; ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ 10 kí àlùfáà sì wọ ẹ̀wù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà níbi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 11 Nígbà náà ni yóò bọ́ aṣọ rẹ̀, yóò sì wọ òmíràn, yóò wá gbé eérú náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tí a kà sí mímọ́. 12 Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀. 13 Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú. 14 “ ‘Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Aaroni gbé ẹbọ sísun náà wá síwájú OLÚWA níwájú pẹpẹ. 15 Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí OLÚWA. 16 Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò jẹ ìyókù ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ láìsí máa wú máa wú ohun tí ń mú àkàrà wú nínú rẹ̀ ní ibi mímọ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé ni kí wọn ó ti jẹ ẹ́. 17 Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú ìwúkàrà. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi. Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́. 18 Èyíkéyìí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Aaroni ló le jẹ ẹ́. Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí OLÚWA láti ìrandíran. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́.’ ” 19 OLÚWA sọ fún Mose pé, 20 “Èyí ni ọrẹ tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún OLÚWA ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́. 21 Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéékèèké bí òórùn dídùn sí OLÚWA. 22 Ọmọkùnrin Aaroni tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti OLÚWA títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátápátá. 23 Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ ti àlùfáà ni wọ́n gbọdọ̀ sun pátápátá, wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.” 24 OLÚWA sọ fún Mose pé, 25 “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLÚWA, níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 26 Àlùfáà tó rú ẹbọ náà ni kí ó jẹ ẹ́, ibi mímọ́ ni kí ó ti jẹ ẹ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé. 27 Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́, bí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá sì ta sí ara aṣọ kan, ẹ gbọdọ̀ fọ̀ ọ́ ní ibi mímọ́. 28 Ẹ gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí ẹ fi se ẹran náà, ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìkòkò idẹ ni ẹ fi sè é, ẹ gbọdọ̀ bó o, kí ẹ sì fi omi sìn ín dáradára. 29 Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 30 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kankan, èyí tí wọ́n bá mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ètùtù ní Ibi Mímọ́, sísun ni kí ẹ sun ún.
In Other Versions
Leviticus 6 in the ANGEFD
Leviticus 6 in the ANTPNG2D
Leviticus 6 in the AS21
Leviticus 6 in the BAGH
Leviticus 6 in the BBPNG
Leviticus 6 in the BBT1E
Leviticus 6 in the BDS
Leviticus 6 in the BEV
Leviticus 6 in the BHAD
Leviticus 6 in the BIB
Leviticus 6 in the BLPT
Leviticus 6 in the BNT
Leviticus 6 in the BNTABOOT
Leviticus 6 in the BNTLV
Leviticus 6 in the BOATCB
Leviticus 6 in the BOATCB2
Leviticus 6 in the BOBCV
Leviticus 6 in the BOCNT
Leviticus 6 in the BOECS
Leviticus 6 in the BOGWICC
Leviticus 6 in the BOHCB
Leviticus 6 in the BOHCV
Leviticus 6 in the BOHLNT
Leviticus 6 in the BOHNTLTAL
Leviticus 6 in the BOICB
Leviticus 6 in the BOILNTAP
Leviticus 6 in the BOITCV
Leviticus 6 in the BOKCV
Leviticus 6 in the BOKCV2
Leviticus 6 in the BOKHWOG
Leviticus 6 in the BOKSSV
Leviticus 6 in the BOLCB
Leviticus 6 in the BOLCB2
Leviticus 6 in the BOMCV
Leviticus 6 in the BONAV
Leviticus 6 in the BONCB
Leviticus 6 in the BONLT
Leviticus 6 in the BONUT2
Leviticus 6 in the BOPLNT
Leviticus 6 in the BOSCB
Leviticus 6 in the BOSNC
Leviticus 6 in the BOTLNT
Leviticus 6 in the BOVCB
Leviticus 6 in the BPBB
Leviticus 6 in the BPH
Leviticus 6 in the BSB
Leviticus 6 in the CCB
Leviticus 6 in the CUV
Leviticus 6 in the CUVS
Leviticus 6 in the DBT
Leviticus 6 in the DGDNT
Leviticus 6 in the DHNT
Leviticus 6 in the DNT
Leviticus 6 in the ELBE
Leviticus 6 in the EMTV
Leviticus 6 in the ESV
Leviticus 6 in the FBV
Leviticus 6 in the FEB
Leviticus 6 in the GGMNT
Leviticus 6 in the GNT
Leviticus 6 in the HARY
Leviticus 6 in the HNT
Leviticus 6 in the IRVA
Leviticus 6 in the IRVB
Leviticus 6 in the IRVG
Leviticus 6 in the IRVH
Leviticus 6 in the IRVK
Leviticus 6 in the IRVM
Leviticus 6 in the IRVM2
Leviticus 6 in the IRVO
Leviticus 6 in the IRVP
Leviticus 6 in the IRVT
Leviticus 6 in the IRVT2
Leviticus 6 in the IRVU
Leviticus 6 in the ISVN
Leviticus 6 in the JSNT
Leviticus 6 in the KAPI
Leviticus 6 in the KBT1ETNIK
Leviticus 6 in the KBV
Leviticus 6 in the KJV
Leviticus 6 in the KNFD
Leviticus 6 in the LBA
Leviticus 6 in the LBLA
Leviticus 6 in the LNT
Leviticus 6 in the LSV
Leviticus 6 in the MAAL
Leviticus 6 in the MBV
Leviticus 6 in the MBV2
Leviticus 6 in the MHNT
Leviticus 6 in the MKNFD
Leviticus 6 in the MNG
Leviticus 6 in the MNT
Leviticus 6 in the MNT2
Leviticus 6 in the MRS1T
Leviticus 6 in the NAA
Leviticus 6 in the NASB
Leviticus 6 in the NBLA
Leviticus 6 in the NBS
Leviticus 6 in the NBVTP
Leviticus 6 in the NET2
Leviticus 6 in the NIV11
Leviticus 6 in the NNT
Leviticus 6 in the NNT2
Leviticus 6 in the NNT3
Leviticus 6 in the PDDPT
Leviticus 6 in the PFNT
Leviticus 6 in the RMNT
Leviticus 6 in the SBIAS
Leviticus 6 in the SBIBS
Leviticus 6 in the SBIBS2
Leviticus 6 in the SBICS
Leviticus 6 in the SBIDS
Leviticus 6 in the SBIGS
Leviticus 6 in the SBIHS
Leviticus 6 in the SBIIS
Leviticus 6 in the SBIIS2
Leviticus 6 in the SBIIS3
Leviticus 6 in the SBIKS
Leviticus 6 in the SBIKS2
Leviticus 6 in the SBIMS
Leviticus 6 in the SBIOS
Leviticus 6 in the SBIPS
Leviticus 6 in the SBISS
Leviticus 6 in the SBITS
Leviticus 6 in the SBITS2
Leviticus 6 in the SBITS3
Leviticus 6 in the SBITS4
Leviticus 6 in the SBIUS
Leviticus 6 in the SBIVS
Leviticus 6 in the SBT
Leviticus 6 in the SBT1E
Leviticus 6 in the SCHL
Leviticus 6 in the SNT
Leviticus 6 in the SUSU
Leviticus 6 in the SUSU2
Leviticus 6 in the SYNO
Leviticus 6 in the TBIAOTANT
Leviticus 6 in the TBT1E
Leviticus 6 in the TBT1E2
Leviticus 6 in the TFTIP
Leviticus 6 in the TFTU
Leviticus 6 in the TGNTATF3T
Leviticus 6 in the THAI
Leviticus 6 in the TNFD
Leviticus 6 in the TNT
Leviticus 6 in the TNTIK
Leviticus 6 in the TNTIL
Leviticus 6 in the TNTIN
Leviticus 6 in the TNTIP
Leviticus 6 in the TNTIZ
Leviticus 6 in the TOMA
Leviticus 6 in the TTENT
Leviticus 6 in the UBG
Leviticus 6 in the UGV
Leviticus 6 in the UGV2
Leviticus 6 in the UGV3
Leviticus 6 in the VBL
Leviticus 6 in the VDCC
Leviticus 6 in the YALU
Leviticus 6 in the YAPE
Leviticus 6 in the YBVTP
Leviticus 6 in the ZBP