Leviticus 8 (BOYCB)

1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀. 3 Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” 4 Mose sì ṣe bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 5 Mose sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA ti pàṣẹ pé kí á ṣe.” 6 Nígbà náà ni Mose mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n. 7 Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní efodu; aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlekè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí. 8 Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Urimu àti Tumimu sí ibi ìgbàyà náà. 9 Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tí í ṣe adé mímọ́ síwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose. 10 Mose sì fi òróró ìtasórí ya àgọ́ àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ sí mímọ́. 11 Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́, 12 ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí Aaroni, ó sì yà á sí mímọ́. 13 Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dìwọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose. 14 Ó sì mú akọ màlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà. 15 Mose pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un. 16 Mose tún mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ. 17 Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú awọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti paláṣẹ fún Mose. 18 Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà. 19 Mose sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká. 20 Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mose sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀. 21 Ó fi omi fọ gbogbo nǹkan inú àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun odidi àgbò náà lórí pẹpẹ bí ẹbọ sísun òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí OLÚWA gẹ́gẹ́ bí OLÚWA tí pàṣẹ fún Mose. 22 Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí. 23 Mose sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. 24 Mose sì tún mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká. 25 Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún. 26 Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú OLÚWA àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà. 27 Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLÚWA. 28 Lẹ́yìn náà, Mose gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí OLÚWA. 29 Mose sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fì í níwájú OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose. 30 Mose sì mú díẹ̀ lára òróró ìtasórí àti díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ láti orí pẹpẹ, ó wọ́n sára àwọn ọmọ Aaroni àti aṣọ rẹ̀, ó sì tún wọ́n sára àwọn ọmọ Aaroni àti aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Mose ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn sí mímọ́. 31 Mose sì sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ se ẹran náà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú àkàrà tí a mú láti inú apẹ̀rẹ̀ ọrẹ ìfinijoyè àlùfáà gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé, ‘Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó jẹ ẹ́.’ 32 Kí ẹ fi iná sun ìyókù àkàrà àti ẹran náà. 33 Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje, títí tí ọjọ́ ìfinijoyè àlùfáà yín yóò fi pé, nítorí pé ìfinijoyè àlùfáà yín yóò gba ọjọ́ méje gbáko. 34 Ohun tí a ṣe lónìí jẹ́ ohun tí OLÚWA ti pàṣẹ láti ṣe ètùtù fún yín. 35 Ẹ gbọdọ̀ wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé lọ́sàn án àti lóru fún ọjọ́ méje kí ẹ sì ṣe ohun tí OLÚWA fẹ́, kí ẹ má ba à kú, nítorí ohun tí OLÚWA pàṣẹ fún mi ni èyí.” 36 Báyìí ni Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo tí OLÚWA pàṣẹ láti ẹnu Mose.

In Other Versions

Leviticus 8 in the ANGEFD

Leviticus 8 in the ANTPNG2D

Leviticus 8 in the AS21

Leviticus 8 in the BAGH

Leviticus 8 in the BBPNG

Leviticus 8 in the BBT1E

Leviticus 8 in the BDS

Leviticus 8 in the BEV

Leviticus 8 in the BHAD

Leviticus 8 in the BIB

Leviticus 8 in the BLPT

Leviticus 8 in the BNT

Leviticus 8 in the BNTABOOT

Leviticus 8 in the BNTLV

Leviticus 8 in the BOATCB

Leviticus 8 in the BOATCB2

Leviticus 8 in the BOBCV

Leviticus 8 in the BOCNT

Leviticus 8 in the BOECS

Leviticus 8 in the BOGWICC

Leviticus 8 in the BOHCB

Leviticus 8 in the BOHCV

Leviticus 8 in the BOHLNT

Leviticus 8 in the BOHNTLTAL

Leviticus 8 in the BOICB

Leviticus 8 in the BOILNTAP

Leviticus 8 in the BOITCV

Leviticus 8 in the BOKCV

Leviticus 8 in the BOKCV2

Leviticus 8 in the BOKHWOG

Leviticus 8 in the BOKSSV

Leviticus 8 in the BOLCB

Leviticus 8 in the BOLCB2

Leviticus 8 in the BOMCV

Leviticus 8 in the BONAV

Leviticus 8 in the BONCB

Leviticus 8 in the BONLT

Leviticus 8 in the BONUT2

Leviticus 8 in the BOPLNT

Leviticus 8 in the BOSCB

Leviticus 8 in the BOSNC

Leviticus 8 in the BOTLNT

Leviticus 8 in the BOVCB

Leviticus 8 in the BPBB

Leviticus 8 in the BPH

Leviticus 8 in the BSB

Leviticus 8 in the CCB

Leviticus 8 in the CUV

Leviticus 8 in the CUVS

Leviticus 8 in the DBT

Leviticus 8 in the DGDNT

Leviticus 8 in the DHNT

Leviticus 8 in the DNT

Leviticus 8 in the ELBE

Leviticus 8 in the EMTV

Leviticus 8 in the ESV

Leviticus 8 in the FBV

Leviticus 8 in the FEB

Leviticus 8 in the GGMNT

Leviticus 8 in the GNT

Leviticus 8 in the HARY

Leviticus 8 in the HNT

Leviticus 8 in the IRVA

Leviticus 8 in the IRVB

Leviticus 8 in the IRVG

Leviticus 8 in the IRVH

Leviticus 8 in the IRVK

Leviticus 8 in the IRVM

Leviticus 8 in the IRVM2

Leviticus 8 in the IRVO

Leviticus 8 in the IRVP

Leviticus 8 in the IRVT

Leviticus 8 in the IRVT2

Leviticus 8 in the IRVU

Leviticus 8 in the ISVN

Leviticus 8 in the JSNT

Leviticus 8 in the KAPI

Leviticus 8 in the KBT1ETNIK

Leviticus 8 in the KBV

Leviticus 8 in the KJV

Leviticus 8 in the KNFD

Leviticus 8 in the LBA

Leviticus 8 in the LBLA

Leviticus 8 in the LNT

Leviticus 8 in the LSV

Leviticus 8 in the MAAL

Leviticus 8 in the MBV

Leviticus 8 in the MBV2

Leviticus 8 in the MHNT

Leviticus 8 in the MKNFD

Leviticus 8 in the MNG

Leviticus 8 in the MNT

Leviticus 8 in the MNT2

Leviticus 8 in the MRS1T

Leviticus 8 in the NAA

Leviticus 8 in the NASB

Leviticus 8 in the NBLA

Leviticus 8 in the NBS

Leviticus 8 in the NBVTP

Leviticus 8 in the NET2

Leviticus 8 in the NIV11

Leviticus 8 in the NNT

Leviticus 8 in the NNT2

Leviticus 8 in the NNT3

Leviticus 8 in the PDDPT

Leviticus 8 in the PFNT

Leviticus 8 in the RMNT

Leviticus 8 in the SBIAS

Leviticus 8 in the SBIBS

Leviticus 8 in the SBIBS2

Leviticus 8 in the SBICS

Leviticus 8 in the SBIDS

Leviticus 8 in the SBIGS

Leviticus 8 in the SBIHS

Leviticus 8 in the SBIIS

Leviticus 8 in the SBIIS2

Leviticus 8 in the SBIIS3

Leviticus 8 in the SBIKS

Leviticus 8 in the SBIKS2

Leviticus 8 in the SBIMS

Leviticus 8 in the SBIOS

Leviticus 8 in the SBIPS

Leviticus 8 in the SBISS

Leviticus 8 in the SBITS

Leviticus 8 in the SBITS2

Leviticus 8 in the SBITS3

Leviticus 8 in the SBITS4

Leviticus 8 in the SBIUS

Leviticus 8 in the SBIVS

Leviticus 8 in the SBT

Leviticus 8 in the SBT1E

Leviticus 8 in the SCHL

Leviticus 8 in the SNT

Leviticus 8 in the SUSU

Leviticus 8 in the SUSU2

Leviticus 8 in the SYNO

Leviticus 8 in the TBIAOTANT

Leviticus 8 in the TBT1E

Leviticus 8 in the TBT1E2

Leviticus 8 in the TFTIP

Leviticus 8 in the TFTU

Leviticus 8 in the TGNTATF3T

Leviticus 8 in the THAI

Leviticus 8 in the TNFD

Leviticus 8 in the TNT

Leviticus 8 in the TNTIK

Leviticus 8 in the TNTIL

Leviticus 8 in the TNTIN

Leviticus 8 in the TNTIP

Leviticus 8 in the TNTIZ

Leviticus 8 in the TOMA

Leviticus 8 in the TTENT

Leviticus 8 in the UBG

Leviticus 8 in the UGV

Leviticus 8 in the UGV2

Leviticus 8 in the UGV3

Leviticus 8 in the VBL

Leviticus 8 in the VDCC

Leviticus 8 in the YALU

Leviticus 8 in the YAPE

Leviticus 8 in the YBVTP

Leviticus 8 in the ZBP