Malachi 1 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀: ọ̀rọ̀ OLÚWA sí Israẹli láti ẹnu Malaki. 2 “Èmí ti fẹ́ ẹ yín,” ni OLÚWA wí.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ wa?’“Esau kì í ha ṣe arákùnrin Jakọbu bí?” ni OLÚWA wí. “Síbẹ̀ èmi fẹ́ràn Jakọbu, 3 ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra, mo ti sọ àwọn òkè ńlá rẹ̀ di aṣálẹ̀, mo sì fi ìní rẹ̀ fún àwọn akátá aginjù.” 4 Edomu lè wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a run wá, àwa yóò padà wá, a ó sì tún ibùgbé náà kọ́.”Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn lè kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò wó palẹ̀. Wọn yóò sì pè wọ́n ní ilẹ̀ búburú, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń wà ní ìbínú OLÚWA. 5 Ẹ̀yin yóò sì fi ojú yín rí i, ẹ̀yin yóò sì wí pé, ‘Títóbi ni OLÚWA, títóbi rẹ̀ tayọ kọjá agbègbè Israẹli.’ 6 “Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.“Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’ 7 “Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi.“Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’“Nípa sísọ pé tábìlì OLÚWA di ẹ̀gàn. 8 Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 9 “Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 10 “Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín. 11 Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 12 “Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn. 13 Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.“Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni OLÚWA wí. 14 “Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹran tó lábùkù rú ẹbọ sí OLÚWA; nítorí ọba ńlá ni Èmi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
In Other Versions
Malachi 1 in the ANGEFD
Malachi 1 in the ANTPNG2D
Malachi 1 in the AS21
Malachi 1 in the BAGH
Malachi 1 in the BBPNG
Malachi 1 in the BBT1E
Malachi 1 in the BDS
Malachi 1 in the BEV
Malachi 1 in the BHAD
Malachi 1 in the BIB
Malachi 1 in the BLPT
Malachi 1 in the BNT
Malachi 1 in the BNTABOOT
Malachi 1 in the BNTLV
Malachi 1 in the BOATCB
Malachi 1 in the BOATCB2
Malachi 1 in the BOBCV
Malachi 1 in the BOCNT
Malachi 1 in the BOECS
Malachi 1 in the BOGWICC
Malachi 1 in the BOHCB
Malachi 1 in the BOHCV
Malachi 1 in the BOHLNT
Malachi 1 in the BOHNTLTAL
Malachi 1 in the BOICB
Malachi 1 in the BOILNTAP
Malachi 1 in the BOITCV
Malachi 1 in the BOKCV
Malachi 1 in the BOKCV2
Malachi 1 in the BOKHWOG
Malachi 1 in the BOKSSV
Malachi 1 in the BOLCB
Malachi 1 in the BOLCB2
Malachi 1 in the BOMCV
Malachi 1 in the BONAV
Malachi 1 in the BONCB
Malachi 1 in the BONLT
Malachi 1 in the BONUT2
Malachi 1 in the BOPLNT
Malachi 1 in the BOSCB
Malachi 1 in the BOSNC
Malachi 1 in the BOTLNT
Malachi 1 in the BOVCB
Malachi 1 in the BPBB
Malachi 1 in the BPH
Malachi 1 in the BSB
Malachi 1 in the CCB
Malachi 1 in the CUV
Malachi 1 in the CUVS
Malachi 1 in the DBT
Malachi 1 in the DGDNT
Malachi 1 in the DHNT
Malachi 1 in the DNT
Malachi 1 in the ELBE
Malachi 1 in the EMTV
Malachi 1 in the ESV
Malachi 1 in the FBV
Malachi 1 in the FEB
Malachi 1 in the GGMNT
Malachi 1 in the GNT
Malachi 1 in the HARY
Malachi 1 in the HNT
Malachi 1 in the IRVA
Malachi 1 in the IRVB
Malachi 1 in the IRVG
Malachi 1 in the IRVH
Malachi 1 in the IRVK
Malachi 1 in the IRVM
Malachi 1 in the IRVM2
Malachi 1 in the IRVO
Malachi 1 in the IRVP
Malachi 1 in the IRVT
Malachi 1 in the IRVT2
Malachi 1 in the IRVU
Malachi 1 in the ISVN
Malachi 1 in the JSNT
Malachi 1 in the KAPI
Malachi 1 in the KBT1ETNIK
Malachi 1 in the KBV
Malachi 1 in the KJV
Malachi 1 in the KNFD
Malachi 1 in the LBA
Malachi 1 in the LBLA
Malachi 1 in the LNT
Malachi 1 in the LSV
Malachi 1 in the MAAL
Malachi 1 in the MBV
Malachi 1 in the MBV2
Malachi 1 in the MHNT
Malachi 1 in the MKNFD
Malachi 1 in the MNG
Malachi 1 in the MNT
Malachi 1 in the MNT2
Malachi 1 in the MRS1T
Malachi 1 in the NAA
Malachi 1 in the NASB
Malachi 1 in the NBLA
Malachi 1 in the NBS
Malachi 1 in the NBVTP
Malachi 1 in the NET2
Malachi 1 in the NIV11
Malachi 1 in the NNT
Malachi 1 in the NNT2
Malachi 1 in the NNT3
Malachi 1 in the PDDPT
Malachi 1 in the PFNT
Malachi 1 in the RMNT
Malachi 1 in the SBIAS
Malachi 1 in the SBIBS
Malachi 1 in the SBIBS2
Malachi 1 in the SBICS
Malachi 1 in the SBIDS
Malachi 1 in the SBIGS
Malachi 1 in the SBIHS
Malachi 1 in the SBIIS
Malachi 1 in the SBIIS2
Malachi 1 in the SBIIS3
Malachi 1 in the SBIKS
Malachi 1 in the SBIKS2
Malachi 1 in the SBIMS
Malachi 1 in the SBIOS
Malachi 1 in the SBIPS
Malachi 1 in the SBISS
Malachi 1 in the SBITS
Malachi 1 in the SBITS2
Malachi 1 in the SBITS3
Malachi 1 in the SBITS4
Malachi 1 in the SBIUS
Malachi 1 in the SBIVS
Malachi 1 in the SBT
Malachi 1 in the SBT1E
Malachi 1 in the SCHL
Malachi 1 in the SNT
Malachi 1 in the SUSU
Malachi 1 in the SUSU2
Malachi 1 in the SYNO
Malachi 1 in the TBIAOTANT
Malachi 1 in the TBT1E
Malachi 1 in the TBT1E2
Malachi 1 in the TFTIP
Malachi 1 in the TFTU
Malachi 1 in the TGNTATF3T
Malachi 1 in the THAI
Malachi 1 in the TNFD
Malachi 1 in the TNT
Malachi 1 in the TNTIK
Malachi 1 in the TNTIL
Malachi 1 in the TNTIN
Malachi 1 in the TNTIP
Malachi 1 in the TNTIZ
Malachi 1 in the TOMA
Malachi 1 in the TTENT
Malachi 1 in the UBG
Malachi 1 in the UGV
Malachi 1 in the UGV2
Malachi 1 in the UGV3
Malachi 1 in the VBL
Malachi 1 in the VDCC
Malachi 1 in the YALU
Malachi 1 in the YAPE
Malachi 1 in the YBVTP
Malachi 1 in the ZBP