Matthew 17 (BOYCB)
1 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin rẹ̀, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dádúró. 2 Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn. Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀. 3 Lójijì, Mose àti Elijah fi ara hàn, wọ́n sì ń bá Jesu sọ̀rọ̀. 4 Peteru sọ fún Jesu pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” 5 Bí Peteru ti sọ̀rọ̀ tán, àwọsánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!” 6 Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojúbolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 7 Ṣùgbọ́n Jesu sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.” 8 Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jesu nìkan ni wọn rí. 9 Bí wọ́n sì ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú.” 10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Elijah ní láti kọ́ padà wá?” 11 Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Elijah wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò. 12 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ Ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.” 13 Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Johanu onítẹ̀bọmi fún wọn ni. 14 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ Jesu wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé, 15 “Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubú sínú iná tàbí sínú omi. 16 Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.” 17 Jesu sì dáhùn wí pé, “A! Ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fi ara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.” 18 Nígbà náà ni Jesu bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ. 19 Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jesu níkọ̀kọ̀ pé, “Èéṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?” 20 Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.” 22 Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́. 23 Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi. 24 Nígbà tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kapernaumu, àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ Peteru wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?” 25 Peteru sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.”Nígbà tí Peteru wọ ilé láti bá Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jesu ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jesu bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Simoni? Ǹjẹ́ àwọn ọba ayé ń gba owó orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?” 26 Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.”Jesu sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó òde? 27 Síbẹ̀síbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú. Nítorí náà, ẹ lọ sí etí Òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó orí tèmi àti tirẹ̀.”
In Other Versions
Matthew 17 in the ANGEFD
Matthew 17 in the ANTPNG2D
Matthew 17 in the AS21
Matthew 17 in the BAGH
Matthew 17 in the BBPNG
Matthew 17 in the BBT1E
Matthew 17 in the BDS
Matthew 17 in the BEV
Matthew 17 in the BHAD
Matthew 17 in the BIB
Matthew 17 in the BLPT
Matthew 17 in the BNT
Matthew 17 in the BNTABOOT
Matthew 17 in the BNTLV
Matthew 17 in the BOATCB
Matthew 17 in the BOATCB2
Matthew 17 in the BOBCV
Matthew 17 in the BOCNT
Matthew 17 in the BOECS
Matthew 17 in the BOGWICC
Matthew 17 in the BOHCB
Matthew 17 in the BOHCV
Matthew 17 in the BOHLNT
Matthew 17 in the BOHNTLTAL
Matthew 17 in the BOICB
Matthew 17 in the BOILNTAP
Matthew 17 in the BOITCV
Matthew 17 in the BOKCV
Matthew 17 in the BOKCV2
Matthew 17 in the BOKHWOG
Matthew 17 in the BOKSSV
Matthew 17 in the BOLCB
Matthew 17 in the BOLCB2
Matthew 17 in the BOMCV
Matthew 17 in the BONAV
Matthew 17 in the BONCB
Matthew 17 in the BONLT
Matthew 17 in the BONUT2
Matthew 17 in the BOPLNT
Matthew 17 in the BOSCB
Matthew 17 in the BOSNC
Matthew 17 in the BOTLNT
Matthew 17 in the BOVCB
Matthew 17 in the BPBB
Matthew 17 in the BPH
Matthew 17 in the BSB
Matthew 17 in the CCB
Matthew 17 in the CUV
Matthew 17 in the CUVS
Matthew 17 in the DBT
Matthew 17 in the DGDNT
Matthew 17 in the DHNT
Matthew 17 in the DNT
Matthew 17 in the ELBE
Matthew 17 in the EMTV
Matthew 17 in the ESV
Matthew 17 in the FBV
Matthew 17 in the FEB
Matthew 17 in the GGMNT
Matthew 17 in the GNT
Matthew 17 in the HARY
Matthew 17 in the HNT
Matthew 17 in the IRVA
Matthew 17 in the IRVB
Matthew 17 in the IRVG
Matthew 17 in the IRVH
Matthew 17 in the IRVK
Matthew 17 in the IRVM
Matthew 17 in the IRVM2
Matthew 17 in the IRVO
Matthew 17 in the IRVP
Matthew 17 in the IRVT
Matthew 17 in the IRVT2
Matthew 17 in the IRVU
Matthew 17 in the ISVN
Matthew 17 in the JSNT
Matthew 17 in the KAPI
Matthew 17 in the KBT1ETNIK
Matthew 17 in the KBV
Matthew 17 in the KJV
Matthew 17 in the KNFD
Matthew 17 in the LBA
Matthew 17 in the LBLA
Matthew 17 in the LNT
Matthew 17 in the LSV
Matthew 17 in the MAAL
Matthew 17 in the MBV
Matthew 17 in the MBV2
Matthew 17 in the MHNT
Matthew 17 in the MKNFD
Matthew 17 in the MNG
Matthew 17 in the MNT
Matthew 17 in the MNT2
Matthew 17 in the MRS1T
Matthew 17 in the NAA
Matthew 17 in the NASB
Matthew 17 in the NBLA
Matthew 17 in the NBS
Matthew 17 in the NBVTP
Matthew 17 in the NET2
Matthew 17 in the NIV11
Matthew 17 in the NNT
Matthew 17 in the NNT2
Matthew 17 in the NNT3
Matthew 17 in the PDDPT
Matthew 17 in the PFNT
Matthew 17 in the RMNT
Matthew 17 in the SBIAS
Matthew 17 in the SBIBS
Matthew 17 in the SBIBS2
Matthew 17 in the SBICS
Matthew 17 in the SBIDS
Matthew 17 in the SBIGS
Matthew 17 in the SBIHS
Matthew 17 in the SBIIS
Matthew 17 in the SBIIS2
Matthew 17 in the SBIIS3
Matthew 17 in the SBIKS
Matthew 17 in the SBIKS2
Matthew 17 in the SBIMS
Matthew 17 in the SBIOS
Matthew 17 in the SBIPS
Matthew 17 in the SBISS
Matthew 17 in the SBITS
Matthew 17 in the SBITS2
Matthew 17 in the SBITS3
Matthew 17 in the SBITS4
Matthew 17 in the SBIUS
Matthew 17 in the SBIVS
Matthew 17 in the SBT
Matthew 17 in the SBT1E
Matthew 17 in the SCHL
Matthew 17 in the SNT
Matthew 17 in the SUSU
Matthew 17 in the SUSU2
Matthew 17 in the SYNO
Matthew 17 in the TBIAOTANT
Matthew 17 in the TBT1E
Matthew 17 in the TBT1E2
Matthew 17 in the TFTIP
Matthew 17 in the TFTU
Matthew 17 in the TGNTATF3T
Matthew 17 in the THAI
Matthew 17 in the TNFD
Matthew 17 in the TNT
Matthew 17 in the TNTIK
Matthew 17 in the TNTIL
Matthew 17 in the TNTIN
Matthew 17 in the TNTIP
Matthew 17 in the TNTIZ
Matthew 17 in the TOMA
Matthew 17 in the TTENT
Matthew 17 in the UBG
Matthew 17 in the UGV
Matthew 17 in the UGV2
Matthew 17 in the UGV3
Matthew 17 in the VBL
Matthew 17 in the VDCC
Matthew 17 in the YALU
Matthew 17 in the YAPE
Matthew 17 in the YBVTP
Matthew 17 in the ZBP