Nehemiah 6 (BOYCB)
1 Nígbà tí Sanballati, Tobiah Geṣemu ará Arabia àti àwọn ọ̀tá wa tókù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́kù nínú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì ri àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà. 2 Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé, “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.”Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi; 3 bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé, “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?” 4 Wọ́n rán iṣẹ́ náà sí mi nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì fún wọn ní èsì bákan náà fún ìgbà kọ̀ọ̀kan. 5 Ní ìgbà karùn-ún, Sanballati rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí mi pẹ̀lú irú iṣẹ́ kan náà, lẹ́tà kan tí a kò fi sínú àpò ìwé wà ní ọwọ́ rẹ̀ 6 tí a kọ sínú un rẹ̀ pé,“A ròyìn rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, Geṣemu sì sọ pé, òtítọ́ ni, pé ìwọ àti àwọn Júù ń gbèrò láti ṣọ̀tẹ̀, nítorí náà ni ẹ ṣe ń mọ odi. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn yìí, ìwọ sì ń gbèrò láti di ọba wọn 7 àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jerusalẹmu: ‘Ọba kan wà ní Juda!’ Nísinsin yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.” 8 Mo dá èsì yìí padà sí i pé, “Kò sí ohun kan nínú irú ohun tí ìwọ sọ tí ó ṣẹlẹ̀; ìwọ kàn rò wọ́n ní orí ara rẹ ni.” 9 Gbogbo wọn múra láti dẹ́rùbà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní parí rẹ̀.”Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsin yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.” 10 Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemaiah ọmọ Delaiah, ọmọ Mehetabeeli, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú tẹmpili, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹmpili dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.” 11 Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sálọ? Tàbí kí ènìyàn bí èmi sálọ sínú tẹmpili láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là? Èmi kò ní lọ!” 12 Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán an, ṣùgbọ́n ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tobiah àti Sanballati ti bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀. 13 Wọ́n bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rùbà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn. 14 A! Ọlọ́run mi, rántí Tobiah àti Sanballati, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Noadiah wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbèrò láti dẹ́rùbà mí. 15 Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli, láàrín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta. 16 Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa. 17 Bákan náà, ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tobiah, èsì láti ọ̀dọ̀ Tobiah sì ń wá sí ọ̀dọ̀ wọn. 18 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Juda ti mulẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekaniah ọmọ Arah (Sanballati fẹ́ ọmọ Ṣekaniah), ọmọ rẹ̀ Jehohanani sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Meṣullamu ọmọ Berekiah. 19 Síwájú sí í, wọ́n túbọ̀ ń ròyìn iṣẹ́ rere rẹ̀ fún mi, wọ́n sì ń sọ ohun tí mo sọ fún un. Tobiah sì ń kọ àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi láti dẹ́rùbà mí.
In Other Versions
Nehemiah 6 in the ANGEFD
Nehemiah 6 in the ANTPNG2D
Nehemiah 6 in the AS21
Nehemiah 6 in the BAGH
Nehemiah 6 in the BBPNG
Nehemiah 6 in the BBT1E
Nehemiah 6 in the BDS
Nehemiah 6 in the BEV
Nehemiah 6 in the BHAD
Nehemiah 6 in the BIB
Nehemiah 6 in the BLPT
Nehemiah 6 in the BNT
Nehemiah 6 in the BNTABOOT
Nehemiah 6 in the BNTLV
Nehemiah 6 in the BOATCB
Nehemiah 6 in the BOATCB2
Nehemiah 6 in the BOBCV
Nehemiah 6 in the BOCNT
Nehemiah 6 in the BOECS
Nehemiah 6 in the BOGWICC
Nehemiah 6 in the BOHCB
Nehemiah 6 in the BOHCV
Nehemiah 6 in the BOHLNT
Nehemiah 6 in the BOHNTLTAL
Nehemiah 6 in the BOICB
Nehemiah 6 in the BOILNTAP
Nehemiah 6 in the BOITCV
Nehemiah 6 in the BOKCV
Nehemiah 6 in the BOKCV2
Nehemiah 6 in the BOKHWOG
Nehemiah 6 in the BOKSSV
Nehemiah 6 in the BOLCB
Nehemiah 6 in the BOLCB2
Nehemiah 6 in the BOMCV
Nehemiah 6 in the BONAV
Nehemiah 6 in the BONCB
Nehemiah 6 in the BONLT
Nehemiah 6 in the BONUT2
Nehemiah 6 in the BOPLNT
Nehemiah 6 in the BOSCB
Nehemiah 6 in the BOSNC
Nehemiah 6 in the BOTLNT
Nehemiah 6 in the BOVCB
Nehemiah 6 in the BPBB
Nehemiah 6 in the BPH
Nehemiah 6 in the BSB
Nehemiah 6 in the CCB
Nehemiah 6 in the CUV
Nehemiah 6 in the CUVS
Nehemiah 6 in the DBT
Nehemiah 6 in the DGDNT
Nehemiah 6 in the DHNT
Nehemiah 6 in the DNT
Nehemiah 6 in the ELBE
Nehemiah 6 in the EMTV
Nehemiah 6 in the ESV
Nehemiah 6 in the FBV
Nehemiah 6 in the FEB
Nehemiah 6 in the GGMNT
Nehemiah 6 in the GNT
Nehemiah 6 in the HARY
Nehemiah 6 in the HNT
Nehemiah 6 in the IRVA
Nehemiah 6 in the IRVB
Nehemiah 6 in the IRVG
Nehemiah 6 in the IRVH
Nehemiah 6 in the IRVK
Nehemiah 6 in the IRVM
Nehemiah 6 in the IRVM2
Nehemiah 6 in the IRVO
Nehemiah 6 in the IRVP
Nehemiah 6 in the IRVT
Nehemiah 6 in the IRVT2
Nehemiah 6 in the IRVU
Nehemiah 6 in the ISVN
Nehemiah 6 in the JSNT
Nehemiah 6 in the KAPI
Nehemiah 6 in the KBT1ETNIK
Nehemiah 6 in the KBV
Nehemiah 6 in the KJV
Nehemiah 6 in the KNFD
Nehemiah 6 in the LBA
Nehemiah 6 in the LBLA
Nehemiah 6 in the LNT
Nehemiah 6 in the LSV
Nehemiah 6 in the MAAL
Nehemiah 6 in the MBV
Nehemiah 6 in the MBV2
Nehemiah 6 in the MHNT
Nehemiah 6 in the MKNFD
Nehemiah 6 in the MNG
Nehemiah 6 in the MNT
Nehemiah 6 in the MNT2
Nehemiah 6 in the MRS1T
Nehemiah 6 in the NAA
Nehemiah 6 in the NASB
Nehemiah 6 in the NBLA
Nehemiah 6 in the NBS
Nehemiah 6 in the NBVTP
Nehemiah 6 in the NET2
Nehemiah 6 in the NIV11
Nehemiah 6 in the NNT
Nehemiah 6 in the NNT2
Nehemiah 6 in the NNT3
Nehemiah 6 in the PDDPT
Nehemiah 6 in the PFNT
Nehemiah 6 in the RMNT
Nehemiah 6 in the SBIAS
Nehemiah 6 in the SBIBS
Nehemiah 6 in the SBIBS2
Nehemiah 6 in the SBICS
Nehemiah 6 in the SBIDS
Nehemiah 6 in the SBIGS
Nehemiah 6 in the SBIHS
Nehemiah 6 in the SBIIS
Nehemiah 6 in the SBIIS2
Nehemiah 6 in the SBIIS3
Nehemiah 6 in the SBIKS
Nehemiah 6 in the SBIKS2
Nehemiah 6 in the SBIMS
Nehemiah 6 in the SBIOS
Nehemiah 6 in the SBIPS
Nehemiah 6 in the SBISS
Nehemiah 6 in the SBITS
Nehemiah 6 in the SBITS2
Nehemiah 6 in the SBITS3
Nehemiah 6 in the SBITS4
Nehemiah 6 in the SBIUS
Nehemiah 6 in the SBIVS
Nehemiah 6 in the SBT
Nehemiah 6 in the SBT1E
Nehemiah 6 in the SCHL
Nehemiah 6 in the SNT
Nehemiah 6 in the SUSU
Nehemiah 6 in the SUSU2
Nehemiah 6 in the SYNO
Nehemiah 6 in the TBIAOTANT
Nehemiah 6 in the TBT1E
Nehemiah 6 in the TBT1E2
Nehemiah 6 in the TFTIP
Nehemiah 6 in the TFTU
Nehemiah 6 in the TGNTATF3T
Nehemiah 6 in the THAI
Nehemiah 6 in the TNFD
Nehemiah 6 in the TNT
Nehemiah 6 in the TNTIK
Nehemiah 6 in the TNTIL
Nehemiah 6 in the TNTIN
Nehemiah 6 in the TNTIP
Nehemiah 6 in the TNTIZ
Nehemiah 6 in the TOMA
Nehemiah 6 in the TTENT
Nehemiah 6 in the UBG
Nehemiah 6 in the UGV
Nehemiah 6 in the UGV2
Nehemiah 6 in the UGV3
Nehemiah 6 in the VBL
Nehemiah 6 in the VDCC
Nehemiah 6 in the YALU
Nehemiah 6 in the YAPE
Nehemiah 6 in the YBVTP
Nehemiah 6 in the ZBP