Numbers 30 (BOYCB)
1 Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA pàṣẹ, 2 nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí OLÚWA tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ. 3 “Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLÚWA tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ 4 tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró. 5 Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; OLÚWA yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un. 6 “Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè, 7 tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró. 8 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, OLÚWA yóò sì dáríjì í. 9 “Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀. 10 “Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, 11 tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró. 12 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, OLÚWA yóò tú u sílẹ̀. 13 Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀. 14 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó ṣe ìwádìí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ láìsọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀. 15 Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.” 16 Èyí ni ìlànà tí OLÚWA fún Mose nípa ìbátan láàrín ọkùnrin àti obìnrin àti láàrín baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀.
In Other Versions
Numbers 30 in the ANGEFD
Numbers 30 in the ANTPNG2D
Numbers 30 in the AS21
Numbers 30 in the BAGH
Numbers 30 in the BBPNG
Numbers 30 in the BBT1E
Numbers 30 in the BDS
Numbers 30 in the BEV
Numbers 30 in the BHAD
Numbers 30 in the BIB
Numbers 30 in the BLPT
Numbers 30 in the BNT
Numbers 30 in the BNTABOOT
Numbers 30 in the BNTLV
Numbers 30 in the BOATCB
Numbers 30 in the BOATCB2
Numbers 30 in the BOBCV
Numbers 30 in the BOCNT
Numbers 30 in the BOECS
Numbers 30 in the BOGWICC
Numbers 30 in the BOHCB
Numbers 30 in the BOHCV
Numbers 30 in the BOHLNT
Numbers 30 in the BOHNTLTAL
Numbers 30 in the BOICB
Numbers 30 in the BOILNTAP
Numbers 30 in the BOITCV
Numbers 30 in the BOKCV
Numbers 30 in the BOKCV2
Numbers 30 in the BOKHWOG
Numbers 30 in the BOKSSV
Numbers 30 in the BOLCB
Numbers 30 in the BOLCB2
Numbers 30 in the BOMCV
Numbers 30 in the BONAV
Numbers 30 in the BONCB
Numbers 30 in the BONLT
Numbers 30 in the BONUT2
Numbers 30 in the BOPLNT
Numbers 30 in the BOSCB
Numbers 30 in the BOSNC
Numbers 30 in the BOTLNT
Numbers 30 in the BOVCB
Numbers 30 in the BPBB
Numbers 30 in the BPH
Numbers 30 in the BSB
Numbers 30 in the CCB
Numbers 30 in the CUV
Numbers 30 in the CUVS
Numbers 30 in the DBT
Numbers 30 in the DGDNT
Numbers 30 in the DHNT
Numbers 30 in the DNT
Numbers 30 in the ELBE
Numbers 30 in the EMTV
Numbers 30 in the ESV
Numbers 30 in the FBV
Numbers 30 in the FEB
Numbers 30 in the GGMNT
Numbers 30 in the GNT
Numbers 30 in the HARY
Numbers 30 in the HNT
Numbers 30 in the IRVA
Numbers 30 in the IRVB
Numbers 30 in the IRVG
Numbers 30 in the IRVH
Numbers 30 in the IRVK
Numbers 30 in the IRVM
Numbers 30 in the IRVM2
Numbers 30 in the IRVO
Numbers 30 in the IRVP
Numbers 30 in the IRVT
Numbers 30 in the IRVT2
Numbers 30 in the IRVU
Numbers 30 in the ISVN
Numbers 30 in the JSNT
Numbers 30 in the KAPI
Numbers 30 in the KBT1ETNIK
Numbers 30 in the KBV
Numbers 30 in the KJV
Numbers 30 in the KNFD
Numbers 30 in the LBA
Numbers 30 in the LBLA
Numbers 30 in the LNT
Numbers 30 in the LSV
Numbers 30 in the MAAL
Numbers 30 in the MBV
Numbers 30 in the MBV2
Numbers 30 in the MHNT
Numbers 30 in the MKNFD
Numbers 30 in the MNG
Numbers 30 in the MNT
Numbers 30 in the MNT2
Numbers 30 in the MRS1T
Numbers 30 in the NAA
Numbers 30 in the NASB
Numbers 30 in the NBLA
Numbers 30 in the NBS
Numbers 30 in the NBVTP
Numbers 30 in the NET2
Numbers 30 in the NIV11
Numbers 30 in the NNT
Numbers 30 in the NNT2
Numbers 30 in the NNT3
Numbers 30 in the PDDPT
Numbers 30 in the PFNT
Numbers 30 in the RMNT
Numbers 30 in the SBIAS
Numbers 30 in the SBIBS
Numbers 30 in the SBIBS2
Numbers 30 in the SBICS
Numbers 30 in the SBIDS
Numbers 30 in the SBIGS
Numbers 30 in the SBIHS
Numbers 30 in the SBIIS
Numbers 30 in the SBIIS2
Numbers 30 in the SBIIS3
Numbers 30 in the SBIKS
Numbers 30 in the SBIKS2
Numbers 30 in the SBIMS
Numbers 30 in the SBIOS
Numbers 30 in the SBIPS
Numbers 30 in the SBISS
Numbers 30 in the SBITS
Numbers 30 in the SBITS2
Numbers 30 in the SBITS3
Numbers 30 in the SBITS4
Numbers 30 in the SBIUS
Numbers 30 in the SBIVS
Numbers 30 in the SBT
Numbers 30 in the SBT1E
Numbers 30 in the SCHL
Numbers 30 in the SNT
Numbers 30 in the SUSU
Numbers 30 in the SUSU2
Numbers 30 in the SYNO
Numbers 30 in the TBIAOTANT
Numbers 30 in the TBT1E
Numbers 30 in the TBT1E2
Numbers 30 in the TFTIP
Numbers 30 in the TFTU
Numbers 30 in the TGNTATF3T
Numbers 30 in the THAI
Numbers 30 in the TNFD
Numbers 30 in the TNT
Numbers 30 in the TNTIK
Numbers 30 in the TNTIL
Numbers 30 in the TNTIN
Numbers 30 in the TNTIP
Numbers 30 in the TNTIZ
Numbers 30 in the TOMA
Numbers 30 in the TTENT
Numbers 30 in the UBG
Numbers 30 in the UGV
Numbers 30 in the UGV2
Numbers 30 in the UGV3
Numbers 30 in the VBL
Numbers 30 in the VDCC
Numbers 30 in the YALU
Numbers 30 in the YAPE
Numbers 30 in the YBVTP
Numbers 30 in the ZBP