Proverbs 12 (BOYCB)
1 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n. 2 Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ OLÚWAṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi. 3 A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburúṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu. 4 Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà. 5 Èrò àwọn olódodo tọ́,ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn. 6 Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là. 7 A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin. 8 A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn. 9 Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ. 10 Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò,ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni. 11 Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n. 12 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkàṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀. 13 A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú. 14 Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rerebí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú. 15 Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn. 16 Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ. 17 Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ ríṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́. 18 Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá. 19 Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláéṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́. 20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburúṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀. 21 Ibi kì í ṣubú lu olódodo ráráṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn. 22 OLÚWA kórìíra ètè tí ń parọ́ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. 23 Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde. 24 Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọbaṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe. 25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodòṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀. 26 Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà. 27 Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀. 28 Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wàní ọ̀nà náà ni àìkú wà.