Psalms 12 (BOYCB)
undefined Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi. 1 Ràn wá lọ́wọ́, OLÚWA, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn. 2 Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn. 3 Kí OLÚWA kí ó gé ètè èké wọnàti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu 4 tí ó wí pé,“Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?” 5 “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni OLÚWA wí.“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.” 6 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì jẹ aláìlábùkù,gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,tí a sọ di mímọ́ nígbà méje. 7 OLÚWA, ìwọ yóò pa wá mọ́kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé. 8 Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kirinígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.