Psalms 128 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. 1 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA:tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ. 3 Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rereeléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká. 4 Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,tí ó bẹ̀rù OLÚWA. 5 Kí OLÚWA kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,kí ìwọ kí ó sì máa rí ìreJerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo. 6 Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.Láti àlàáfíà lára Israẹli.