Psalms 150 (BOYCB)
1 Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA. Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀,ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀. 2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀. 3 Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín. 4 Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ínfi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín, 5 Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro. 6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin OLÚWA. Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA.