Psalms 23 (BOYCB)
undefined Saamu ti Dafidi. 1 OLÚWA ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní. 2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù,Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́, 3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò.Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodonítorí orúkọ rẹ̀. 4 Bí mo tilẹ̀ ń rìnláàrín àfonífojì òjìji ikú,èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,wọ́n ń tù mí nínú. 5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú miní ojú àwọn ọ̀tá à mi.Ìwọ ta òróró sí mi ní orí;ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀. 6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìnní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,èmi yóò sì máa gbé inú ilé OLÚWAtítí láéláé.