Psalms 3 (BOYCB)
undefined Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu. 1 OLÚWA, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó! 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela. 3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, OLÚWA;ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè. 4 OLÚWA ni mo kígbe sókè sí,ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela. 5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;mo sì tún padà jí, nítorí OLÚWA ni ó ń gbé mi ró. 6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàntí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká. 7 Dìde, OLÚWA!Gbà mí, Ọlọ́run mi!Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú. 8 Láti ọ̀dọ̀ OLÚWA ni ìgbàlà ti wá.Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.