1 Kings 19 (BOYCB)

1 Ahabu sì sọ gbogbo ohun tí Elijah ti ṣe fún Jesebeli àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì. 2 Nítorí náà Jesebeli rán oníṣẹ́ kan sí Elijah wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.” 3 Elijah sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Beerṣeba ti Juda, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, 4 nígbà tí òun tìkára rẹ̀ sì lọ ní ìrìn ọjọ́ kan sí aginjù, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, OLÚWA, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ.” 5 Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ.Sì wò ó, angẹli fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí o jẹun.” 6 Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yín iná, àti orù-omi wà lẹ́bàá orí rẹ̀. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀. 7 Angẹli OLÚWA sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jì fún ọ.” 8 Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run. 9 Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀.Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?” 10 Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.” 11 OLÚWA sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú OLÚWA, nítorí OLÚWA fẹ́ rékọjá.”Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú OLÚWA; ṣùgbọ́n OLÚWA kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n OLÚWA kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà. 12 Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n OLÚWA kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá. 13 Nígbà tí Elijah sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà.Nígbà náà ni ohùn kan tọ̀ ọ́ wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín, Elijah?” 14 Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.” 15 OLÚWA sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí aginjù Damasku. Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hasaeli ní ọba lórí Aramu. 16 Tún fi òróró yan Jehu ọmọ Nimṣi ní ọba lórí Israẹli, àti kí o fi òróró yan Eliṣa ọmọ Ṣafati, ará Abeli-Mehola ní wòlíì ní ipò rẹ. 17 Jehu yóò pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Hasaeli, Eliṣa yóò sì pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Jehu. 18 Síbẹ̀, èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Israẹli, àní gbogbo eékún tí kò ì tí ì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Baali, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.” 19 Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Eliṣa ọmọ Ṣafati. Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú èkejìlá. Elijah sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó. 20 Nígbà náà ni Eliṣa sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì sáré tọ Elijah lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”Elijah sì dáhùn wí pé, “Padà sẹ́yìn, kí ni mo fi ṣe ọ́?” 21 Eliṣa sì fi í sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn. Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n. Ó sì fi ohun èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ. Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Elijah lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.

In Other Versions

1 Kings 19 in the ANGEFD

1 Kings 19 in the ANTPNG2D

1 Kings 19 in the AS21

1 Kings 19 in the BAGH

1 Kings 19 in the BBPNG

1 Kings 19 in the BBT1E

1 Kings 19 in the BDS

1 Kings 19 in the BEV

1 Kings 19 in the BHAD

1 Kings 19 in the BIB

1 Kings 19 in the BLPT

1 Kings 19 in the BNT

1 Kings 19 in the BNTABOOT

1 Kings 19 in the BNTLV

1 Kings 19 in the BOATCB

1 Kings 19 in the BOATCB2

1 Kings 19 in the BOBCV

1 Kings 19 in the BOCNT

1 Kings 19 in the BOECS

1 Kings 19 in the BOGWICC

1 Kings 19 in the BOHCB

1 Kings 19 in the BOHCV

1 Kings 19 in the BOHLNT

1 Kings 19 in the BOHNTLTAL

1 Kings 19 in the BOICB

1 Kings 19 in the BOILNTAP

1 Kings 19 in the BOITCV

1 Kings 19 in the BOKCV

1 Kings 19 in the BOKCV2

1 Kings 19 in the BOKHWOG

1 Kings 19 in the BOKSSV

1 Kings 19 in the BOLCB

1 Kings 19 in the BOLCB2

1 Kings 19 in the BOMCV

1 Kings 19 in the BONAV

1 Kings 19 in the BONCB

1 Kings 19 in the BONLT

1 Kings 19 in the BONUT2

1 Kings 19 in the BOPLNT

1 Kings 19 in the BOSCB

1 Kings 19 in the BOSNC

1 Kings 19 in the BOTLNT

1 Kings 19 in the BOVCB

1 Kings 19 in the BPBB

1 Kings 19 in the BPH

1 Kings 19 in the BSB

1 Kings 19 in the CCB

1 Kings 19 in the CUV

1 Kings 19 in the CUVS

1 Kings 19 in the DBT

1 Kings 19 in the DGDNT

1 Kings 19 in the DHNT

1 Kings 19 in the DNT

1 Kings 19 in the ELBE

1 Kings 19 in the EMTV

1 Kings 19 in the ESV

1 Kings 19 in the FBV

1 Kings 19 in the FEB

1 Kings 19 in the GGMNT

1 Kings 19 in the GNT

1 Kings 19 in the HARY

1 Kings 19 in the HNT

1 Kings 19 in the IRVA

1 Kings 19 in the IRVB

1 Kings 19 in the IRVG

1 Kings 19 in the IRVH

1 Kings 19 in the IRVK

1 Kings 19 in the IRVM

1 Kings 19 in the IRVM2

1 Kings 19 in the IRVO

1 Kings 19 in the IRVP

1 Kings 19 in the IRVT

1 Kings 19 in the IRVT2

1 Kings 19 in the IRVU

1 Kings 19 in the ISVN

1 Kings 19 in the JSNT

1 Kings 19 in the KAPI

1 Kings 19 in the KBT1ETNIK

1 Kings 19 in the KBV

1 Kings 19 in the KJV

1 Kings 19 in the KNFD

1 Kings 19 in the LBA

1 Kings 19 in the LBLA

1 Kings 19 in the LNT

1 Kings 19 in the LSV

1 Kings 19 in the MAAL

1 Kings 19 in the MBV

1 Kings 19 in the MBV2

1 Kings 19 in the MHNT

1 Kings 19 in the MKNFD

1 Kings 19 in the MNG

1 Kings 19 in the MNT

1 Kings 19 in the MNT2

1 Kings 19 in the MRS1T

1 Kings 19 in the NAA

1 Kings 19 in the NASB

1 Kings 19 in the NBLA

1 Kings 19 in the NBS

1 Kings 19 in the NBVTP

1 Kings 19 in the NET2

1 Kings 19 in the NIV11

1 Kings 19 in the NNT

1 Kings 19 in the NNT2

1 Kings 19 in the NNT3

1 Kings 19 in the PDDPT

1 Kings 19 in the PFNT

1 Kings 19 in the RMNT

1 Kings 19 in the SBIAS

1 Kings 19 in the SBIBS

1 Kings 19 in the SBIBS2

1 Kings 19 in the SBICS

1 Kings 19 in the SBIDS

1 Kings 19 in the SBIGS

1 Kings 19 in the SBIHS

1 Kings 19 in the SBIIS

1 Kings 19 in the SBIIS2

1 Kings 19 in the SBIIS3

1 Kings 19 in the SBIKS

1 Kings 19 in the SBIKS2

1 Kings 19 in the SBIMS

1 Kings 19 in the SBIOS

1 Kings 19 in the SBIPS

1 Kings 19 in the SBISS

1 Kings 19 in the SBITS

1 Kings 19 in the SBITS2

1 Kings 19 in the SBITS3

1 Kings 19 in the SBITS4

1 Kings 19 in the SBIUS

1 Kings 19 in the SBIVS

1 Kings 19 in the SBT

1 Kings 19 in the SBT1E

1 Kings 19 in the SCHL

1 Kings 19 in the SNT

1 Kings 19 in the SUSU

1 Kings 19 in the SUSU2

1 Kings 19 in the SYNO

1 Kings 19 in the TBIAOTANT

1 Kings 19 in the TBT1E

1 Kings 19 in the TBT1E2

1 Kings 19 in the TFTIP

1 Kings 19 in the TFTU

1 Kings 19 in the TGNTATF3T

1 Kings 19 in the THAI

1 Kings 19 in the TNFD

1 Kings 19 in the TNT

1 Kings 19 in the TNTIK

1 Kings 19 in the TNTIL

1 Kings 19 in the TNTIN

1 Kings 19 in the TNTIP

1 Kings 19 in the TNTIZ

1 Kings 19 in the TOMA

1 Kings 19 in the TTENT

1 Kings 19 in the UBG

1 Kings 19 in the UGV

1 Kings 19 in the UGV2

1 Kings 19 in the UGV3

1 Kings 19 in the VBL

1 Kings 19 in the VDCC

1 Kings 19 in the YALU

1 Kings 19 in the YAPE

1 Kings 19 in the YBVTP

1 Kings 19 in the ZBP