1 Peter 5 (BOYCB)

1 Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn. 2 Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan. 3 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo. 4 Nígbà tí Olórí Olùṣọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í sá. 5 Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹríba fún àwọn alàgbà. Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹríba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín ní aṣọ: nítorí,“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” 6 Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. 7 Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín. 8 Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ. 9 Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ. 10 Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀. 11 Tìrẹ ni ògo àti agbára títí láé. Àmín. 12 Nítorí Sila, arákùnrin wa olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkúrú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run: ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. 13 Ìjọ tí ń bẹ ní Babeli, tí a yàn, pẹ̀lú kí yín, bẹ́ẹ̀ sì ni Marku ọmọ mi pẹ̀lú. 14 Ẹ fi ìfẹ́nukonu ìfẹ́ kí ara, yín. Àlàáfíà fún gbogbo yín tí ẹ wà nínú Kristi.

In Other Versions

1 Peter 5 in the ANGEFD

1 Peter 5 in the ANTPNG2D

1 Peter 5 in the AS21

1 Peter 5 in the BAGH

1 Peter 5 in the BBPNG

1 Peter 5 in the BBT1E

1 Peter 5 in the BDS

1 Peter 5 in the BEV

1 Peter 5 in the BHAD

1 Peter 5 in the BIB

1 Peter 5 in the BLPT

1 Peter 5 in the BNT

1 Peter 5 in the BNTABOOT

1 Peter 5 in the BNTLV

1 Peter 5 in the BOATCB

1 Peter 5 in the BOATCB2

1 Peter 5 in the BOBCV

1 Peter 5 in the BOCNT

1 Peter 5 in the BOECS

1 Peter 5 in the BOGWICC

1 Peter 5 in the BOHCB

1 Peter 5 in the BOHCV

1 Peter 5 in the BOHLNT

1 Peter 5 in the BOHNTLTAL

1 Peter 5 in the BOICB

1 Peter 5 in the BOILNTAP

1 Peter 5 in the BOITCV

1 Peter 5 in the BOKCV

1 Peter 5 in the BOKCV2

1 Peter 5 in the BOKHWOG

1 Peter 5 in the BOKSSV

1 Peter 5 in the BOLCB

1 Peter 5 in the BOLCB2

1 Peter 5 in the BOMCV

1 Peter 5 in the BONAV

1 Peter 5 in the BONCB

1 Peter 5 in the BONLT

1 Peter 5 in the BONUT2

1 Peter 5 in the BOPLNT

1 Peter 5 in the BOSCB

1 Peter 5 in the BOSNC

1 Peter 5 in the BOTLNT

1 Peter 5 in the BOVCB

1 Peter 5 in the BPBB

1 Peter 5 in the BPH

1 Peter 5 in the BSB

1 Peter 5 in the CCB

1 Peter 5 in the CUV

1 Peter 5 in the CUVS

1 Peter 5 in the DBT

1 Peter 5 in the DGDNT

1 Peter 5 in the DHNT

1 Peter 5 in the DNT

1 Peter 5 in the ELBE

1 Peter 5 in the EMTV

1 Peter 5 in the ESV

1 Peter 5 in the FBV

1 Peter 5 in the FEB

1 Peter 5 in the GGMNT

1 Peter 5 in the GNT

1 Peter 5 in the HARY

1 Peter 5 in the HNT

1 Peter 5 in the IRVA

1 Peter 5 in the IRVB

1 Peter 5 in the IRVG

1 Peter 5 in the IRVH

1 Peter 5 in the IRVK

1 Peter 5 in the IRVM

1 Peter 5 in the IRVM2

1 Peter 5 in the IRVO

1 Peter 5 in the IRVP

1 Peter 5 in the IRVT

1 Peter 5 in the IRVT2

1 Peter 5 in the IRVU

1 Peter 5 in the ISVN

1 Peter 5 in the JSNT

1 Peter 5 in the KAPI

1 Peter 5 in the KBT1ETNIK

1 Peter 5 in the KBV

1 Peter 5 in the KJV

1 Peter 5 in the KNFD

1 Peter 5 in the LBA

1 Peter 5 in the LBLA

1 Peter 5 in the LNT

1 Peter 5 in the LSV

1 Peter 5 in the MAAL

1 Peter 5 in the MBV

1 Peter 5 in the MBV2

1 Peter 5 in the MHNT

1 Peter 5 in the MKNFD

1 Peter 5 in the MNG

1 Peter 5 in the MNT

1 Peter 5 in the MNT2

1 Peter 5 in the MRS1T

1 Peter 5 in the NAA

1 Peter 5 in the NASB

1 Peter 5 in the NBLA

1 Peter 5 in the NBS

1 Peter 5 in the NBVTP

1 Peter 5 in the NET2

1 Peter 5 in the NIV11

1 Peter 5 in the NNT

1 Peter 5 in the NNT2

1 Peter 5 in the NNT3

1 Peter 5 in the PDDPT

1 Peter 5 in the PFNT

1 Peter 5 in the RMNT

1 Peter 5 in the SBIAS

1 Peter 5 in the SBIBS

1 Peter 5 in the SBIBS2

1 Peter 5 in the SBICS

1 Peter 5 in the SBIDS

1 Peter 5 in the SBIGS

1 Peter 5 in the SBIHS

1 Peter 5 in the SBIIS

1 Peter 5 in the SBIIS2

1 Peter 5 in the SBIIS3

1 Peter 5 in the SBIKS

1 Peter 5 in the SBIKS2

1 Peter 5 in the SBIMS

1 Peter 5 in the SBIOS

1 Peter 5 in the SBIPS

1 Peter 5 in the SBISS

1 Peter 5 in the SBITS

1 Peter 5 in the SBITS2

1 Peter 5 in the SBITS3

1 Peter 5 in the SBITS4

1 Peter 5 in the SBIUS

1 Peter 5 in the SBIVS

1 Peter 5 in the SBT

1 Peter 5 in the SBT1E

1 Peter 5 in the SCHL

1 Peter 5 in the SNT

1 Peter 5 in the SUSU

1 Peter 5 in the SUSU2

1 Peter 5 in the SYNO

1 Peter 5 in the TBIAOTANT

1 Peter 5 in the TBT1E

1 Peter 5 in the TBT1E2

1 Peter 5 in the TFTIP

1 Peter 5 in the TFTU

1 Peter 5 in the TGNTATF3T

1 Peter 5 in the THAI

1 Peter 5 in the TNFD

1 Peter 5 in the TNT

1 Peter 5 in the TNTIK

1 Peter 5 in the TNTIL

1 Peter 5 in the TNTIN

1 Peter 5 in the TNTIP

1 Peter 5 in the TNTIZ

1 Peter 5 in the TOMA

1 Peter 5 in the TTENT

1 Peter 5 in the UBG

1 Peter 5 in the UGV

1 Peter 5 in the UGV2

1 Peter 5 in the UGV3

1 Peter 5 in the VBL

1 Peter 5 in the VDCC

1 Peter 5 in the YALU

1 Peter 5 in the YAPE

1 Peter 5 in the YBVTP

1 Peter 5 in the ZBP