1 Samuel 11 (BOYCB)

1 Nahaṣi ará Ammoni gòkè lọ, ó sì dó ti Jabesi Gileadi, gbogbo ọkùnrin Jabesi sì wí fún Nahaṣi pé, “Bá wa dá májẹ̀mú, àwa yóò sì máa sìn ọ́.” 2 Ṣùgbọ́n Nahaṣi ará Ammoni sì wí fún un pé, “Nípa èyí ni èmi yóò fi bá a yín ṣe ìpinnu, nípa yíyọ gbogbo ojú ọ̀tún yín kúrò, èmi yóò ṣì fi yín ṣe ẹlẹ́yà lójú gbogbo Israẹli.” 3 Àwọn àgbàgbà Jabesi sì wí fún un pé, “Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Israẹli; àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ.” 4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gibeah tí ó jẹ́ ìlú Saulu, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún. 5 Nígbà náà gan an ni Saulu padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sọkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi. 6 Nígbà tí Saulu sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè. 7 Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyẹẹyọ sí gbogbo Israẹli nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Saulu àti Samuẹli lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLÚWA sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo. 8 Nígbà tí Saulu sì kó wọn jọ ní Beseki, àwọn ọkùnrin Israẹli tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000), àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000). 9 Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jabesi, inú wọn sì dùn. 10 Wọ́n sọ fún àwọn ará Jabesi pé, “Àwa yóò fi ara wa fún un yín ní ọ̀la, kí ẹ̀yin kí ó ṣe gbogbo èyí tí ó tọ́ lójú yín sí wa.” 11 Ní ọjọ́ kejì Saulu pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ammoni ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóoru ọjọ́. Àwọn tókù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan. 12 Àwọn ènìyàn sọ fún Samuẹli pé, “Ta ni ó béèrè wí pé, Saulu yóò ha jẹ ọba lórí wa? Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n.” 13 Ṣùgbọ́n Saulu wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni OLÚWA ṣiṣẹ́ ìgbàlà ní Israẹli.” 14 Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gilgali, kí a lè fi ẹsẹ̀ Saulu múlẹ̀ bí ọba.” 15 Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gilgali, wọn sí fi Saulu jẹ ọba ní iwájú OLÚWA. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní iwájú OLÚWA, Saulu àti gbogbo Israẹli ṣe àjọyọ̀ ńlá.

In Other Versions

1 Samuel 11 in the ANGEFD

1 Samuel 11 in the ANTPNG2D

1 Samuel 11 in the AS21

1 Samuel 11 in the BAGH

1 Samuel 11 in the BBPNG

1 Samuel 11 in the BBT1E

1 Samuel 11 in the BDS

1 Samuel 11 in the BEV

1 Samuel 11 in the BHAD

1 Samuel 11 in the BIB

1 Samuel 11 in the BLPT

1 Samuel 11 in the BNT

1 Samuel 11 in the BNTABOOT

1 Samuel 11 in the BNTLV

1 Samuel 11 in the BOATCB

1 Samuel 11 in the BOATCB2

1 Samuel 11 in the BOBCV

1 Samuel 11 in the BOCNT

1 Samuel 11 in the BOECS

1 Samuel 11 in the BOGWICC

1 Samuel 11 in the BOHCB

1 Samuel 11 in the BOHCV

1 Samuel 11 in the BOHLNT

1 Samuel 11 in the BOHNTLTAL

1 Samuel 11 in the BOICB

1 Samuel 11 in the BOILNTAP

1 Samuel 11 in the BOITCV

1 Samuel 11 in the BOKCV

1 Samuel 11 in the BOKCV2

1 Samuel 11 in the BOKHWOG

1 Samuel 11 in the BOKSSV

1 Samuel 11 in the BOLCB

1 Samuel 11 in the BOLCB2

1 Samuel 11 in the BOMCV

1 Samuel 11 in the BONAV

1 Samuel 11 in the BONCB

1 Samuel 11 in the BONLT

1 Samuel 11 in the BONUT2

1 Samuel 11 in the BOPLNT

1 Samuel 11 in the BOSCB

1 Samuel 11 in the BOSNC

1 Samuel 11 in the BOTLNT

1 Samuel 11 in the BOVCB

1 Samuel 11 in the BPBB

1 Samuel 11 in the BPH

1 Samuel 11 in the BSB

1 Samuel 11 in the CCB

1 Samuel 11 in the CUV

1 Samuel 11 in the CUVS

1 Samuel 11 in the DBT

1 Samuel 11 in the DGDNT

1 Samuel 11 in the DHNT

1 Samuel 11 in the DNT

1 Samuel 11 in the ELBE

1 Samuel 11 in the EMTV

1 Samuel 11 in the ESV

1 Samuel 11 in the FBV

1 Samuel 11 in the FEB

1 Samuel 11 in the GGMNT

1 Samuel 11 in the GNT

1 Samuel 11 in the HARY

1 Samuel 11 in the HNT

1 Samuel 11 in the IRVA

1 Samuel 11 in the IRVB

1 Samuel 11 in the IRVG

1 Samuel 11 in the IRVH

1 Samuel 11 in the IRVK

1 Samuel 11 in the IRVM

1 Samuel 11 in the IRVM2

1 Samuel 11 in the IRVO

1 Samuel 11 in the IRVP

1 Samuel 11 in the IRVT

1 Samuel 11 in the IRVT2

1 Samuel 11 in the IRVU

1 Samuel 11 in the ISVN

1 Samuel 11 in the JSNT

1 Samuel 11 in the KAPI

1 Samuel 11 in the KBT1ETNIK

1 Samuel 11 in the KBV

1 Samuel 11 in the KJV

1 Samuel 11 in the KNFD

1 Samuel 11 in the LBA

1 Samuel 11 in the LBLA

1 Samuel 11 in the LNT

1 Samuel 11 in the LSV

1 Samuel 11 in the MAAL

1 Samuel 11 in the MBV

1 Samuel 11 in the MBV2

1 Samuel 11 in the MHNT

1 Samuel 11 in the MKNFD

1 Samuel 11 in the MNG

1 Samuel 11 in the MNT

1 Samuel 11 in the MNT2

1 Samuel 11 in the MRS1T

1 Samuel 11 in the NAA

1 Samuel 11 in the NASB

1 Samuel 11 in the NBLA

1 Samuel 11 in the NBS

1 Samuel 11 in the NBVTP

1 Samuel 11 in the NET2

1 Samuel 11 in the NIV11

1 Samuel 11 in the NNT

1 Samuel 11 in the NNT2

1 Samuel 11 in the NNT3

1 Samuel 11 in the PDDPT

1 Samuel 11 in the PFNT

1 Samuel 11 in the RMNT

1 Samuel 11 in the SBIAS

1 Samuel 11 in the SBIBS

1 Samuel 11 in the SBIBS2

1 Samuel 11 in the SBICS

1 Samuel 11 in the SBIDS

1 Samuel 11 in the SBIGS

1 Samuel 11 in the SBIHS

1 Samuel 11 in the SBIIS

1 Samuel 11 in the SBIIS2

1 Samuel 11 in the SBIIS3

1 Samuel 11 in the SBIKS

1 Samuel 11 in the SBIKS2

1 Samuel 11 in the SBIMS

1 Samuel 11 in the SBIOS

1 Samuel 11 in the SBIPS

1 Samuel 11 in the SBISS

1 Samuel 11 in the SBITS

1 Samuel 11 in the SBITS2

1 Samuel 11 in the SBITS3

1 Samuel 11 in the SBITS4

1 Samuel 11 in the SBIUS

1 Samuel 11 in the SBIVS

1 Samuel 11 in the SBT

1 Samuel 11 in the SBT1E

1 Samuel 11 in the SCHL

1 Samuel 11 in the SNT

1 Samuel 11 in the SUSU

1 Samuel 11 in the SUSU2

1 Samuel 11 in the SYNO

1 Samuel 11 in the TBIAOTANT

1 Samuel 11 in the TBT1E

1 Samuel 11 in the TBT1E2

1 Samuel 11 in the TFTIP

1 Samuel 11 in the TFTU

1 Samuel 11 in the TGNTATF3T

1 Samuel 11 in the THAI

1 Samuel 11 in the TNFD

1 Samuel 11 in the TNT

1 Samuel 11 in the TNTIK

1 Samuel 11 in the TNTIL

1 Samuel 11 in the TNTIN

1 Samuel 11 in the TNTIP

1 Samuel 11 in the TNTIZ

1 Samuel 11 in the TOMA

1 Samuel 11 in the TTENT

1 Samuel 11 in the UBG

1 Samuel 11 in the UGV

1 Samuel 11 in the UGV2

1 Samuel 11 in the UGV3

1 Samuel 11 in the VBL

1 Samuel 11 in the VDCC

1 Samuel 11 in the YALU

1 Samuel 11 in the YAPE

1 Samuel 11 in the YBVTP

1 Samuel 11 in the ZBP