2 Kings 21 (BOYCB)
1 Manase jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hẹfisiba. 2 Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLÚWA lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 3 Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n. 4 Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA, èyí tí OLÚWA ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.” 5 Ní àgbàlá méjèèjì ilé OLÚWA, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú OLÚWA, ó sì mú un bínú. 6 Ó fi àwọn ọmọ ara rẹ̀ rú ẹbọ nínú iná, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú OLÚWA láti mú un bínú. 7 Ó sì gbé ère fínfín òrìṣà Aṣerah tí ó ti ṣe, ó sì gbé e sínú ilé OLÚWA, èyí tí OLÚWA ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé OLÚWA yìí àti ní Jerusalẹmu, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé. 8 Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn baba ńlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Mose fi fún wọn mọ́.” 9 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí. Manase tàn wọ́n síwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLÚWA tí parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli lọ. 10 OLÚWA sì wí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì pé, 11 “Manase ọba Juda ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra. Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Amori lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Juda sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀. 12 Nítorí náà èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Israẹli, wí, Èmi le è lọ mú irú ibi báyìí wá sórí Jerusalẹmu àti Juda kí gbogbo etí olúkúlùkù tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ le è hó. 13 Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀n kan tí a lò lórí Jerusalẹmu àti lórí Samaria àti òjé ìdiwọ̀n ti a lò lórí ilé Ahabu. Èmi yóò sì nu Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù tí o ń nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò. 14 Èmi yóò sì kọ ìyókù àwọn ìní mi sílẹ̀ èmi yóò sì kó wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì di ìkógun àti ìjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, 15 nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí baba ńlá wọn ti jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí.” 16 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Manase pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jerusalẹmu láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Juda ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú OLÚWA. 17 Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Manase, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda? 18 Manase sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Ussa. Amoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 19 Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Orúkọ màmá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Meṣulemeti ọmọbìnrin Harusi: ó wá láti Jotba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì. 20 Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe. 21 Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà baba rẹ̀: Ó sì ń sin àwọn ère tí baba rẹ̀ ń sìn, ó sì ń tẹrí rẹ̀ ba fún wọn. 22 Ó sì kọ OLÚWA Ọlọ́run baba rẹ̀ sílẹ̀ kò sì rìn ní ọ̀nà ti OLÚWA. 23 Àwọn ìránṣẹ́ Amoni dìtẹ̀ lórí rẹ̀ wọ́n sì lu ọba pa ní àárín ilé rẹ̀. 24 Nígbà náà àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí ó dìtẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì fi Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ààyè rẹ̀. 25 Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ti ìjọba Amoni àti ohun tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda? 26 Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú nínú ọgbà Ussa. Josiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
In Other Versions
2 Kings 21 in the ANGEFD
2 Kings 21 in the ANTPNG2D
2 Kings 21 in the AS21
2 Kings 21 in the BAGH
2 Kings 21 in the BBPNG
2 Kings 21 in the BBT1E
2 Kings 21 in the BDS
2 Kings 21 in the BEV
2 Kings 21 in the BHAD
2 Kings 21 in the BIB
2 Kings 21 in the BLPT
2 Kings 21 in the BNT
2 Kings 21 in the BNTABOOT
2 Kings 21 in the BNTLV
2 Kings 21 in the BOATCB
2 Kings 21 in the BOATCB2
2 Kings 21 in the BOBCV
2 Kings 21 in the BOCNT
2 Kings 21 in the BOECS
2 Kings 21 in the BOGWICC
2 Kings 21 in the BOHCB
2 Kings 21 in the BOHCV
2 Kings 21 in the BOHLNT
2 Kings 21 in the BOHNTLTAL
2 Kings 21 in the BOICB
2 Kings 21 in the BOILNTAP
2 Kings 21 in the BOITCV
2 Kings 21 in the BOKCV
2 Kings 21 in the BOKCV2
2 Kings 21 in the BOKHWOG
2 Kings 21 in the BOKSSV
2 Kings 21 in the BOLCB
2 Kings 21 in the BOLCB2
2 Kings 21 in the BOMCV
2 Kings 21 in the BONAV
2 Kings 21 in the BONCB
2 Kings 21 in the BONLT
2 Kings 21 in the BONUT2
2 Kings 21 in the BOPLNT
2 Kings 21 in the BOSCB
2 Kings 21 in the BOSNC
2 Kings 21 in the BOTLNT
2 Kings 21 in the BOVCB
2 Kings 21 in the BPBB
2 Kings 21 in the BPH
2 Kings 21 in the BSB
2 Kings 21 in the CCB
2 Kings 21 in the CUV
2 Kings 21 in the CUVS
2 Kings 21 in the DBT
2 Kings 21 in the DGDNT
2 Kings 21 in the DHNT
2 Kings 21 in the DNT
2 Kings 21 in the ELBE
2 Kings 21 in the EMTV
2 Kings 21 in the ESV
2 Kings 21 in the FBV
2 Kings 21 in the FEB
2 Kings 21 in the GGMNT
2 Kings 21 in the GNT
2 Kings 21 in the HARY
2 Kings 21 in the HNT
2 Kings 21 in the IRVA
2 Kings 21 in the IRVB
2 Kings 21 in the IRVG
2 Kings 21 in the IRVH
2 Kings 21 in the IRVK
2 Kings 21 in the IRVM
2 Kings 21 in the IRVM2
2 Kings 21 in the IRVO
2 Kings 21 in the IRVP
2 Kings 21 in the IRVT
2 Kings 21 in the IRVT2
2 Kings 21 in the IRVU
2 Kings 21 in the ISVN
2 Kings 21 in the JSNT
2 Kings 21 in the KAPI
2 Kings 21 in the KBT1ETNIK
2 Kings 21 in the KBV
2 Kings 21 in the KJV
2 Kings 21 in the KNFD
2 Kings 21 in the LBA
2 Kings 21 in the LBLA
2 Kings 21 in the LNT
2 Kings 21 in the LSV
2 Kings 21 in the MAAL
2 Kings 21 in the MBV
2 Kings 21 in the MBV2
2 Kings 21 in the MHNT
2 Kings 21 in the MKNFD
2 Kings 21 in the MNG
2 Kings 21 in the MNT
2 Kings 21 in the MNT2
2 Kings 21 in the MRS1T
2 Kings 21 in the NAA
2 Kings 21 in the NASB
2 Kings 21 in the NBLA
2 Kings 21 in the NBS
2 Kings 21 in the NBVTP
2 Kings 21 in the NET2
2 Kings 21 in the NIV11
2 Kings 21 in the NNT
2 Kings 21 in the NNT2
2 Kings 21 in the NNT3
2 Kings 21 in the PDDPT
2 Kings 21 in the PFNT
2 Kings 21 in the RMNT
2 Kings 21 in the SBIAS
2 Kings 21 in the SBIBS
2 Kings 21 in the SBIBS2
2 Kings 21 in the SBICS
2 Kings 21 in the SBIDS
2 Kings 21 in the SBIGS
2 Kings 21 in the SBIHS
2 Kings 21 in the SBIIS
2 Kings 21 in the SBIIS2
2 Kings 21 in the SBIIS3
2 Kings 21 in the SBIKS
2 Kings 21 in the SBIKS2
2 Kings 21 in the SBIMS
2 Kings 21 in the SBIOS
2 Kings 21 in the SBIPS
2 Kings 21 in the SBISS
2 Kings 21 in the SBITS
2 Kings 21 in the SBITS2
2 Kings 21 in the SBITS3
2 Kings 21 in the SBITS4
2 Kings 21 in the SBIUS
2 Kings 21 in the SBIVS
2 Kings 21 in the SBT
2 Kings 21 in the SBT1E
2 Kings 21 in the SCHL
2 Kings 21 in the SNT
2 Kings 21 in the SUSU
2 Kings 21 in the SUSU2
2 Kings 21 in the SYNO
2 Kings 21 in the TBIAOTANT
2 Kings 21 in the TBT1E
2 Kings 21 in the TBT1E2
2 Kings 21 in the TFTIP
2 Kings 21 in the TFTU
2 Kings 21 in the TGNTATF3T
2 Kings 21 in the THAI
2 Kings 21 in the TNFD
2 Kings 21 in the TNT
2 Kings 21 in the TNTIK
2 Kings 21 in the TNTIL
2 Kings 21 in the TNTIN
2 Kings 21 in the TNTIP
2 Kings 21 in the TNTIZ
2 Kings 21 in the TOMA
2 Kings 21 in the TTENT
2 Kings 21 in the UBG
2 Kings 21 in the UGV
2 Kings 21 in the UGV2
2 Kings 21 in the UGV3
2 Kings 21 in the VBL
2 Kings 21 in the VDCC
2 Kings 21 in the YALU
2 Kings 21 in the YAPE
2 Kings 21 in the YBVTP
2 Kings 21 in the ZBP