2 Kings 24 (BOYCB)
1 Nígbà ìjọba Jehoiakimu, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun sí ilẹ̀ náà, Jehoiakimu sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadnessari. 2 OLÚWA sì rán àwọn ará Babeli, àwọn ará Aramu, àwọn ará Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni. Ó rán wọn láti pa Juda run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì. 3 Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLÚWA, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe. 4 Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí OLÚWA kò sì fẹ́ láti dáríjì. 5 Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda? 6 Jehoiakimu sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 7 Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate. 8 Jehoiakini jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Nehuṣita ọmọbìnrin Elnatani; ó wá láti Jerusalẹmu. 9 Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe. 10 Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà, 11 Nebukadnessari ọba Babeli fúnra rẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í. 12 Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n. 13 Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé OLÚWA àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún OLÚWA. 14 Ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn gbogbo Jerusalẹmu: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù. 15 Nebukadnessari mú Jehoiakini ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ilé náà. 16 Àti gbogbo àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) alágbára ọkùnrin, àti àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000), gbogbo àwọn alágbára tí ó yẹ fún ogun ni ọba Babeli kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. 17 Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah. 18 Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó sì wá láti Libina. 19 Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe. 20 Nítorí tí ìbínú OLÚWA, ni gbogbo èyí ṣe ṣẹ sí Jerusalẹmu, àti Juda, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.Nísinsin yìí Sedekiah sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.
In Other Versions
2 Kings 24 in the ANGEFD
2 Kings 24 in the ANTPNG2D
2 Kings 24 in the AS21
2 Kings 24 in the BAGH
2 Kings 24 in the BBPNG
2 Kings 24 in the BBT1E
2 Kings 24 in the BDS
2 Kings 24 in the BEV
2 Kings 24 in the BHAD
2 Kings 24 in the BIB
2 Kings 24 in the BLPT
2 Kings 24 in the BNT
2 Kings 24 in the BNTABOOT
2 Kings 24 in the BNTLV
2 Kings 24 in the BOATCB
2 Kings 24 in the BOATCB2
2 Kings 24 in the BOBCV
2 Kings 24 in the BOCNT
2 Kings 24 in the BOECS
2 Kings 24 in the BOGWICC
2 Kings 24 in the BOHCB
2 Kings 24 in the BOHCV
2 Kings 24 in the BOHLNT
2 Kings 24 in the BOHNTLTAL
2 Kings 24 in the BOICB
2 Kings 24 in the BOILNTAP
2 Kings 24 in the BOITCV
2 Kings 24 in the BOKCV
2 Kings 24 in the BOKCV2
2 Kings 24 in the BOKHWOG
2 Kings 24 in the BOKSSV
2 Kings 24 in the BOLCB
2 Kings 24 in the BOLCB2
2 Kings 24 in the BOMCV
2 Kings 24 in the BONAV
2 Kings 24 in the BONCB
2 Kings 24 in the BONLT
2 Kings 24 in the BONUT2
2 Kings 24 in the BOPLNT
2 Kings 24 in the BOSCB
2 Kings 24 in the BOSNC
2 Kings 24 in the BOTLNT
2 Kings 24 in the BOVCB
2 Kings 24 in the BPBB
2 Kings 24 in the BPH
2 Kings 24 in the BSB
2 Kings 24 in the CCB
2 Kings 24 in the CUV
2 Kings 24 in the CUVS
2 Kings 24 in the DBT
2 Kings 24 in the DGDNT
2 Kings 24 in the DHNT
2 Kings 24 in the DNT
2 Kings 24 in the ELBE
2 Kings 24 in the EMTV
2 Kings 24 in the ESV
2 Kings 24 in the FBV
2 Kings 24 in the FEB
2 Kings 24 in the GGMNT
2 Kings 24 in the GNT
2 Kings 24 in the HARY
2 Kings 24 in the HNT
2 Kings 24 in the IRVA
2 Kings 24 in the IRVB
2 Kings 24 in the IRVG
2 Kings 24 in the IRVH
2 Kings 24 in the IRVK
2 Kings 24 in the IRVM
2 Kings 24 in the IRVM2
2 Kings 24 in the IRVO
2 Kings 24 in the IRVP
2 Kings 24 in the IRVT
2 Kings 24 in the IRVT2
2 Kings 24 in the IRVU
2 Kings 24 in the ISVN
2 Kings 24 in the JSNT
2 Kings 24 in the KAPI
2 Kings 24 in the KBT1ETNIK
2 Kings 24 in the KBV
2 Kings 24 in the KJV
2 Kings 24 in the KNFD
2 Kings 24 in the LBA
2 Kings 24 in the LBLA
2 Kings 24 in the LNT
2 Kings 24 in the LSV
2 Kings 24 in the MAAL
2 Kings 24 in the MBV
2 Kings 24 in the MBV2
2 Kings 24 in the MHNT
2 Kings 24 in the MKNFD
2 Kings 24 in the MNG
2 Kings 24 in the MNT
2 Kings 24 in the MNT2
2 Kings 24 in the MRS1T
2 Kings 24 in the NAA
2 Kings 24 in the NASB
2 Kings 24 in the NBLA
2 Kings 24 in the NBS
2 Kings 24 in the NBVTP
2 Kings 24 in the NET2
2 Kings 24 in the NIV11
2 Kings 24 in the NNT
2 Kings 24 in the NNT2
2 Kings 24 in the NNT3
2 Kings 24 in the PDDPT
2 Kings 24 in the PFNT
2 Kings 24 in the RMNT
2 Kings 24 in the SBIAS
2 Kings 24 in the SBIBS
2 Kings 24 in the SBIBS2
2 Kings 24 in the SBICS
2 Kings 24 in the SBIDS
2 Kings 24 in the SBIGS
2 Kings 24 in the SBIHS
2 Kings 24 in the SBIIS
2 Kings 24 in the SBIIS2
2 Kings 24 in the SBIIS3
2 Kings 24 in the SBIKS
2 Kings 24 in the SBIKS2
2 Kings 24 in the SBIMS
2 Kings 24 in the SBIOS
2 Kings 24 in the SBIPS
2 Kings 24 in the SBISS
2 Kings 24 in the SBITS
2 Kings 24 in the SBITS2
2 Kings 24 in the SBITS3
2 Kings 24 in the SBITS4
2 Kings 24 in the SBIUS
2 Kings 24 in the SBIVS
2 Kings 24 in the SBT
2 Kings 24 in the SBT1E
2 Kings 24 in the SCHL
2 Kings 24 in the SNT
2 Kings 24 in the SUSU
2 Kings 24 in the SUSU2
2 Kings 24 in the SYNO
2 Kings 24 in the TBIAOTANT
2 Kings 24 in the TBT1E
2 Kings 24 in the TBT1E2
2 Kings 24 in the TFTIP
2 Kings 24 in the TFTU
2 Kings 24 in the TGNTATF3T
2 Kings 24 in the THAI
2 Kings 24 in the TNFD
2 Kings 24 in the TNT
2 Kings 24 in the TNTIK
2 Kings 24 in the TNTIL
2 Kings 24 in the TNTIN
2 Kings 24 in the TNTIP
2 Kings 24 in the TNTIZ
2 Kings 24 in the TOMA
2 Kings 24 in the TTENT
2 Kings 24 in the UBG
2 Kings 24 in the UGV
2 Kings 24 in the UGV2
2 Kings 24 in the UGV3
2 Kings 24 in the VBL
2 Kings 24 in the VDCC
2 Kings 24 in the YALU
2 Kings 24 in the YAPE
2 Kings 24 in the YBVTP
2 Kings 24 in the ZBP