2 Peter 1 (BOYCB)
1 Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà: 2 Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa. 3 Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. 4 Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. 5 Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; 6 àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. 7 Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. 8 Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 9 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. 10 Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú, nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. 11 Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. 12 Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí. 13 Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́ ara yìí. 14 Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́ ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní, bí Olúwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. 15 Èmi ó sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi. 16 Nítorí kì í ṣe bí ẹni tí ó ń tọ ìtàn asán lẹ́yìn tí a fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n là sílẹ̀, nígbà tí àwa sọ fún yín ní ti agbára àti wíwá Jesu Kristi Olúwa, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí ọláńlá rẹ̀ ni àwa jẹ́. 17 Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” 18 Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà. 19 Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín. 20 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀. 21 Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.
In Other Versions
2 Peter 1 in the ANGEFD
2 Peter 1 in the ANTPNG2D
2 Peter 1 in the AS21
2 Peter 1 in the BAGH
2 Peter 1 in the BBPNG
2 Peter 1 in the BBT1E
2 Peter 1 in the BDS
2 Peter 1 in the BEV
2 Peter 1 in the BHAD
2 Peter 1 in the BIB
2 Peter 1 in the BLPT
2 Peter 1 in the BNT
2 Peter 1 in the BNTABOOT
2 Peter 1 in the BNTLV
2 Peter 1 in the BOATCB
2 Peter 1 in the BOATCB2
2 Peter 1 in the BOBCV
2 Peter 1 in the BOCNT
2 Peter 1 in the BOECS
2 Peter 1 in the BOGWICC
2 Peter 1 in the BOHCB
2 Peter 1 in the BOHCV
2 Peter 1 in the BOHLNT
2 Peter 1 in the BOHNTLTAL
2 Peter 1 in the BOICB
2 Peter 1 in the BOILNTAP
2 Peter 1 in the BOITCV
2 Peter 1 in the BOKCV
2 Peter 1 in the BOKCV2
2 Peter 1 in the BOKHWOG
2 Peter 1 in the BOKSSV
2 Peter 1 in the BOLCB
2 Peter 1 in the BOLCB2
2 Peter 1 in the BOMCV
2 Peter 1 in the BONAV
2 Peter 1 in the BONCB
2 Peter 1 in the BONLT
2 Peter 1 in the BONUT2
2 Peter 1 in the BOPLNT
2 Peter 1 in the BOSCB
2 Peter 1 in the BOSNC
2 Peter 1 in the BOTLNT
2 Peter 1 in the BOVCB
2 Peter 1 in the BPBB
2 Peter 1 in the BPH
2 Peter 1 in the BSB
2 Peter 1 in the CCB
2 Peter 1 in the CUV
2 Peter 1 in the CUVS
2 Peter 1 in the DBT
2 Peter 1 in the DGDNT
2 Peter 1 in the DHNT
2 Peter 1 in the DNT
2 Peter 1 in the ELBE
2 Peter 1 in the EMTV
2 Peter 1 in the ESV
2 Peter 1 in the FBV
2 Peter 1 in the FEB
2 Peter 1 in the GGMNT
2 Peter 1 in the GNT
2 Peter 1 in the HARY
2 Peter 1 in the HNT
2 Peter 1 in the IRVA
2 Peter 1 in the IRVB
2 Peter 1 in the IRVG
2 Peter 1 in the IRVH
2 Peter 1 in the IRVK
2 Peter 1 in the IRVM
2 Peter 1 in the IRVM2
2 Peter 1 in the IRVO
2 Peter 1 in the IRVP
2 Peter 1 in the IRVT
2 Peter 1 in the IRVT2
2 Peter 1 in the IRVU
2 Peter 1 in the ISVN
2 Peter 1 in the JSNT
2 Peter 1 in the KAPI
2 Peter 1 in the KBT1ETNIK
2 Peter 1 in the KBV
2 Peter 1 in the KJV
2 Peter 1 in the KNFD
2 Peter 1 in the LBA
2 Peter 1 in the LBLA
2 Peter 1 in the LNT
2 Peter 1 in the LSV
2 Peter 1 in the MAAL
2 Peter 1 in the MBV
2 Peter 1 in the MBV2
2 Peter 1 in the MHNT
2 Peter 1 in the MKNFD
2 Peter 1 in the MNG
2 Peter 1 in the MNT
2 Peter 1 in the MNT2
2 Peter 1 in the MRS1T
2 Peter 1 in the NAA
2 Peter 1 in the NASB
2 Peter 1 in the NBLA
2 Peter 1 in the NBS
2 Peter 1 in the NBVTP
2 Peter 1 in the NET2
2 Peter 1 in the NIV11
2 Peter 1 in the NNT
2 Peter 1 in the NNT2
2 Peter 1 in the NNT3
2 Peter 1 in the PDDPT
2 Peter 1 in the PFNT
2 Peter 1 in the RMNT
2 Peter 1 in the SBIAS
2 Peter 1 in the SBIBS
2 Peter 1 in the SBIBS2
2 Peter 1 in the SBICS
2 Peter 1 in the SBIDS
2 Peter 1 in the SBIGS
2 Peter 1 in the SBIHS
2 Peter 1 in the SBIIS
2 Peter 1 in the SBIIS2
2 Peter 1 in the SBIIS3
2 Peter 1 in the SBIKS
2 Peter 1 in the SBIKS2
2 Peter 1 in the SBIMS
2 Peter 1 in the SBIOS
2 Peter 1 in the SBIPS
2 Peter 1 in the SBISS
2 Peter 1 in the SBITS
2 Peter 1 in the SBITS2
2 Peter 1 in the SBITS3
2 Peter 1 in the SBITS4
2 Peter 1 in the SBIUS
2 Peter 1 in the SBIVS
2 Peter 1 in the SBT
2 Peter 1 in the SBT1E
2 Peter 1 in the SCHL
2 Peter 1 in the SNT
2 Peter 1 in the SUSU
2 Peter 1 in the SUSU2
2 Peter 1 in the SYNO
2 Peter 1 in the TBIAOTANT
2 Peter 1 in the TBT1E
2 Peter 1 in the TBT1E2
2 Peter 1 in the TFTIP
2 Peter 1 in the TFTU
2 Peter 1 in the TGNTATF3T
2 Peter 1 in the THAI
2 Peter 1 in the TNFD
2 Peter 1 in the TNT
2 Peter 1 in the TNTIK
2 Peter 1 in the TNTIL
2 Peter 1 in the TNTIN
2 Peter 1 in the TNTIP
2 Peter 1 in the TNTIZ
2 Peter 1 in the TOMA
2 Peter 1 in the TTENT
2 Peter 1 in the UBG
2 Peter 1 in the UGV
2 Peter 1 in the UGV2
2 Peter 1 in the UGV3
2 Peter 1 in the VBL
2 Peter 1 in the VDCC
2 Peter 1 in the YALU
2 Peter 1 in the YAPE
2 Peter 1 in the YBVTP
2 Peter 1 in the ZBP