Acts 21 (BOYCB)

1 Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ kejì a sì lọ sí Rodu, à si gba ibẹ̀ lọ sí Patara, 2 A rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rékọjá lọ sí Fonisia, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì ṣíkọ̀. 3 Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀. 4 Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọjọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Paulu pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerusalẹmu. 5 Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà. 6 Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn. 7 Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tire, àwa dé Pitolemai; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ọjọ́ kan. 8 Ní ọjọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesarea; nígbà tí á sì wọ ilé Filipi efangelisti tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. 9 Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀. 10 Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Agabu. 11 Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí, ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ” 12 Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 13 Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” 14 Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!” 15 Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 16 Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kesarea bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Munasoni ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Saipurọsi, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa yóò dé sí. 17 Nígbà tí a sì dé Jerusalẹmu, àwọn arákùnrin sì fi ayọ̀ gbà wá. 18 Ní ọjọ́ kejì, a bá Paulu lọ sọ́dọ̀ Jakọbu; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀. 19 Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrín àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. 20 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin. 21 Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrín àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mose sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. 22 Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé. 23 Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe, àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́. 24 Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́. 25 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti àgbèrè.” 26 Nígbà náà ni Paulu mú àwọn ọkùnrin náà; ní ọjọ́ kejì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹmpili lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olúkúlùkù wọn. 27 Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un. 28 Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbà wá. Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn ènìyàn, àti sí òfin, àti sí ibí yìí, àti pẹ̀lú ó sì mú àwọn ará Giriki wá sínú tẹmpili, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.” 29 Nítorí wọ́n tí rí Tirofimu ará Efesu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Paulu mú wá sínú tẹmpili. 30 Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdò, àwọn ènìyàn sì súré jọ wọ́n sì mú Paulu, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹmpili: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. 31 Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. 32 Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu. 33 Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. 34 Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. 35 Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. 36 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!” 37 Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Paulu wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí ogun pé, “Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí?”Ó sì dáhùn wí pé, “Ìwọ mọ èdè Giriki bí? 38 Ìwọ ha kọ ní ara Ejibiti náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì (4,000) ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ sí ijù?” 39 Ṣùgbọ́n Paulu sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tarsu ìlú Kilikia, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi síbẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!” 40 Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́ rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wí pé,

In Other Versions

Acts 21 in the ANGEFD

Acts 21 in the ANTPNG2D

Acts 21 in the AS21

Acts 21 in the BAGH

Acts 21 in the BBPNG

Acts 21 in the BBT1E

Acts 21 in the BDS

Acts 21 in the BEV

Acts 21 in the BHAD

Acts 21 in the BIB

Acts 21 in the BLPT

Acts 21 in the BNT

Acts 21 in the BNTABOOT

Acts 21 in the BNTLV

Acts 21 in the BOATCB

Acts 21 in the BOATCB2

Acts 21 in the BOBCV

Acts 21 in the BOCNT

Acts 21 in the BOECS

Acts 21 in the BOGWICC

Acts 21 in the BOHCB

Acts 21 in the BOHCV

Acts 21 in the BOHLNT

Acts 21 in the BOHNTLTAL

Acts 21 in the BOICB

Acts 21 in the BOILNTAP

Acts 21 in the BOITCV

Acts 21 in the BOKCV

Acts 21 in the BOKCV2

Acts 21 in the BOKHWOG

Acts 21 in the BOKSSV

Acts 21 in the BOLCB

Acts 21 in the BOLCB2

Acts 21 in the BOMCV

Acts 21 in the BONAV

Acts 21 in the BONCB

Acts 21 in the BONLT

Acts 21 in the BONUT2

Acts 21 in the BOPLNT

Acts 21 in the BOSCB

Acts 21 in the BOSNC

Acts 21 in the BOTLNT

Acts 21 in the BOVCB

Acts 21 in the BPBB

Acts 21 in the BPH

Acts 21 in the BSB

Acts 21 in the CCB

Acts 21 in the CUV

Acts 21 in the CUVS

Acts 21 in the DBT

Acts 21 in the DGDNT

Acts 21 in the DHNT

Acts 21 in the DNT

Acts 21 in the ELBE

Acts 21 in the EMTV

Acts 21 in the ESV

Acts 21 in the FBV

Acts 21 in the FEB

Acts 21 in the GGMNT

Acts 21 in the GNT

Acts 21 in the HARY

Acts 21 in the HNT

Acts 21 in the IRVA

Acts 21 in the IRVB

Acts 21 in the IRVG

Acts 21 in the IRVH

Acts 21 in the IRVK

Acts 21 in the IRVM

Acts 21 in the IRVM2

Acts 21 in the IRVO

Acts 21 in the IRVP

Acts 21 in the IRVT

Acts 21 in the IRVT2

Acts 21 in the IRVU

Acts 21 in the ISVN

Acts 21 in the JSNT

Acts 21 in the KAPI

Acts 21 in the KBT1ETNIK

Acts 21 in the KBV

Acts 21 in the KJV

Acts 21 in the KNFD

Acts 21 in the LBA

Acts 21 in the LBLA

Acts 21 in the LNT

Acts 21 in the LSV

Acts 21 in the MAAL

Acts 21 in the MBV

Acts 21 in the MBV2

Acts 21 in the MHNT

Acts 21 in the MKNFD

Acts 21 in the MNG

Acts 21 in the MNT

Acts 21 in the MNT2

Acts 21 in the MRS1T

Acts 21 in the NAA

Acts 21 in the NASB

Acts 21 in the NBLA

Acts 21 in the NBS

Acts 21 in the NBVTP

Acts 21 in the NET2

Acts 21 in the NIV11

Acts 21 in the NNT

Acts 21 in the NNT2

Acts 21 in the NNT3

Acts 21 in the PDDPT

Acts 21 in the PFNT

Acts 21 in the RMNT

Acts 21 in the SBIAS

Acts 21 in the SBIBS

Acts 21 in the SBIBS2

Acts 21 in the SBICS

Acts 21 in the SBIDS

Acts 21 in the SBIGS

Acts 21 in the SBIHS

Acts 21 in the SBIIS

Acts 21 in the SBIIS2

Acts 21 in the SBIIS3

Acts 21 in the SBIKS

Acts 21 in the SBIKS2

Acts 21 in the SBIMS

Acts 21 in the SBIOS

Acts 21 in the SBIPS

Acts 21 in the SBISS

Acts 21 in the SBITS

Acts 21 in the SBITS2

Acts 21 in the SBITS3

Acts 21 in the SBITS4

Acts 21 in the SBIUS

Acts 21 in the SBIVS

Acts 21 in the SBT

Acts 21 in the SBT1E

Acts 21 in the SCHL

Acts 21 in the SNT

Acts 21 in the SUSU

Acts 21 in the SUSU2

Acts 21 in the SYNO

Acts 21 in the TBIAOTANT

Acts 21 in the TBT1E

Acts 21 in the TBT1E2

Acts 21 in the TFTIP

Acts 21 in the TFTU

Acts 21 in the TGNTATF3T

Acts 21 in the THAI

Acts 21 in the TNFD

Acts 21 in the TNT

Acts 21 in the TNTIK

Acts 21 in the TNTIL

Acts 21 in the TNTIN

Acts 21 in the TNTIP

Acts 21 in the TNTIZ

Acts 21 in the TOMA

Acts 21 in the TTENT

Acts 21 in the UBG

Acts 21 in the UGV

Acts 21 in the UGV2

Acts 21 in the UGV3

Acts 21 in the VBL

Acts 21 in the VDCC

Acts 21 in the YALU

Acts 21 in the YAPE

Acts 21 in the YBVTP

Acts 21 in the ZBP